Olúdíje ipò Ààrẹ mẹ́rin pè fún wíwọ́gilé ìbò Ààrẹ DR Congo

Oríṣun àwòrán, REUTERS
Eto idibo lorilẹede Democratic Republic of Congo ni ko lọ daada nitori bi mago mago se waye ati bi o se n gba akoko awọn oludibo.
Awọn ibudo eto idibo kọọkan ni ko wa ni sisi fun awọn eeyan lati dibo, eyi to bi ọpọ ninu pupọ.
Wọn ti sun eto idibo siwaju ni awọn agbegbe kan.
Oludije sipo aarẹ mẹrin ninu eto idibo Democratic of Congo ti fi atẹjade sita, ti wọn si n pe fun wiwọgile eto idibo to waye lọjọru.
Ọkan lara wọn sapejuwe eto idibo ọhun gẹgẹ gbagede ija nitori bi rogbodiyan se bẹ silẹ lasiko iponlogo.
Awọn oludije yii ni, Olori ẹgbẹ oṣelu alatako, Martin Fayulu, Ẹni to gba ami ẹyẹ Nobel Peace Denis Mukwege, Olori awọn ọdọ, Flonbert Anzuluni ati Pasitọ Theodore Ngoy.
Ni awọn apa ibi kan lorilẹede naa, awọn araalu se iwọde lati fẹhonu han lori bi ijọba sese eto idibo, ti wọn si ba ọpọlọpọ irinsẹ awọpn eleto idibo jẹ.
Gẹgẹ awọn to n woye eto idibo se sọ, O to ida ọgọta ibudo eto idibo ti wọn pẹ lati bẹrẹ idibo, ti ida ọgbọn si ni irinsẹ wọn kọ lati sisẹ.
Ẹwẹ, ijọba orilẹede Congo ti ki awọn araalu to ni anfani lati dibo ku orire
Ninu atẹjade ti ijọba fi lede, agbẹnusọ ijọba bu ẹnu atẹlu bi rogbodiyan se bẹ silẹ ni awọn agbegbe kan.
O wa rọ awọn agbofinro lati sawari awọn eeyan to wa ni di rogbodiyan naa.















