Ọ̀rẹ́ méjì dèrò àhámọ́ ni Kirikiri l'Eko lórí ẹ̀sùn ìṣekúpa ọ̀rẹ́ wọn torí ráìsì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile ẹjọ majisreeti to wa ni Yaba niluu Eko ti pàṣẹ pe ki wọn ju ọrẹ meji, Noah Tovohome ati Rajay Zannu si ahamọ lori ẹsun igbimọpọ lati pa ọrẹ wọn, Segun Zusu lori baagi raisi mẹrindinlogoji.
Ọjọ Isẹgun ana ni awọn mejeeji kawọ sẹyin rojọ niwaju adajọ majisreeti Linda Balogun lori ẹsun iṣekupani onikoko meji.
Ile ẹjọ fidi rẹ mulẹ pe Tovohome ati Zannu gbimọ pọ pẹlu awakọ oju-omi to n ko ẹru Zusu bọ lati Seme wí pe ko pa a, ki o sí ji raisi rẹ gbe lọ.
Amọ, loru bii ago meji ni wọn lọ da ọkọ oju-omi naa l'ọna ninu odo Novo ni Seme.
Níbẹ ni a gbọ pe wọn ti fi pako lu Zusu pa ti wọn si ju u sinu odo.
Lẹyin naa ni wọn ko awọn baagi raisi ọhún lọ si Babagry nibi ti wọn ti ta a ni ₦1.4m fun obinrin oniṣowo kan ti wọn si pin owo naa.
Olupẹjọ ọlọpaa, Chekwube Okeh sọ fun ile ẹjọ pe ọjọ kejila oṣu Kọkanla to kọja lọ yii l'awọn ọrẹ mejeeji ṣiṣẹ laabi ọhun.
Olupẹjọ Okeh ni ẹsun yii tako ẹka 222 ninu iwe ofin, o si ni ijiya ni ẹka 223 ninu ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko ọdun 2015.
Bayii ni wọn ṣe ka ẹsun ti wọn fi kan awọn afurasí mejeeji naa nile ẹjọ majisreeti ni Yaba: "ẹsun ti ile ẹjọ fi kan iwọ, Noah Tovohome, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ati iwọ, Rajay Zannu, ọmọ ọdun mejidinlogoji at'awọn mii to ti salọ ni pe ẹ ṣekupa Segun Zusu, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn nì ago meji oru ninu odo Novo ni Seme, ipinlẹ Eko eyi tii ṣe ẹsun to ni ijiya ninu iwe ofin ọdaran ipinlẹ Eko ọdun 2015."
Ile ẹjọ ko gba awijare awọn olujẹjọ naa.
Okeh rọ ile ẹjọ pe ki wọn ju awọn mejeeji sí ahamọ na titi ti ọfiisi adari olupẹjọ nipinlẹ Eko yoo fi sọ imọran rẹ lori ẹjọ naa.
Adajọ majisreeti Balogun gba ẹbẹ naa, o sí pàṣẹ pe ki wọn ju awọn olujẹjọ mejeeji sí ahamọ ni Kirikiri.
Adajọ majisreeti Balogun wa sun igbẹjo si ọjọ kejilelogun oṣu kinni ọdun 2024.















