Ohun tí a mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe yin ìbọn pa akẹ́kọ̀ọ́ 15 ní ọgbà fásitì ní ìlú Prague

Aworan awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O kere tan awọn mẹẹdogun lo ti padanu ẹmi wọn, ti ọpọlọpọ si fara pa nigba ti agbebọn kan ṣina bo’lẹ ninu ọgba ileẹkọ fasiti kan laaringbungbun ilu Prague, gẹgẹ bi awọn ọlọpaa orilẹede Czech ṣe salaye.

Iṣẹlẹ ọhun to waye ninu ọgba fasiti Charles ni wọn wi pe akẹkọọ fasiti naa ni agbebọn ọun.

Awọn ọlọpaa wi pe ọkunrin agbebọn naa ni wọn ti yanju rẹ.

Awọn oṣiṣẹ pajawiri

Oríṣun àwòrán, EPA

Ni nkan bii aago mẹrin ku ogun iṣẹju nirọlẹ Ọjọbọ ni iroyin gbode pe ẹnikan ti yin ọpọ ero nibnọn laarin olu-ilu orilẹede naa.

Awọn ọlọpaa wi pe wọn ti n da si iṣẹlẹ naa to waye l’ẹka ikọṣẹ ọna nileẹkọ naa ni fasiti Charles, ati pe ọpọ eeyan lo ti gbẹmi mi tawọn kan naa sio fara pa.

Ninu atẹjade kan loju opo X, aarẹ orilẹede Czech, Petr Pavel, lo wi pe iṣelẹ naa ya oun lẹnu, to si ba awọn mọlẹbi ti iṣẹlẹ naa ṣẹ si kẹdun.

Bakan naa lo gboriyin fawọn olugbe agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ fun bi wọn ṣe tẹlẹ ọrọ awọn agbofinro.

'A gburo ibugbamu, a si ri agbebọn kan lori orule'

Awọn oṣiṣẹ pajawiri nilu Prague wi pe ọpọ ọkọ awọn alaarẹ n la wọn ti fi ranṣẹ si ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ ninu ọgbafasiti naa nitori pe oniruuru ifarapa lawọn eeyan ni nibẹ.

Ileeṣẹ amohunmaworan Nova lorilẹede Czech jabọ pe ibugbamu kan dun tawọn si ri agbebọn kan to wa lori orule ile naa.

Minisita fọrọ abẹlẹ, Vit Rakusan, to rọ awọn araalu lati tẹle aṣẹ awọn agbofinro, wi pe ẹnikẹni ko tii ri agbebọn miran yatọ si eyi ti wọn kọkọ ri.

Awọn ọlọpaa ti gbegi dina lagbegbe naa, wọn si ti rọ awọn to n gbe nitosi lati fidimọle.

Wọn ri oku agbebọn naa nilẹ ninu ọgba fasiti ọhun

Ọga awọn ọlọpaa lo ti wi pe awọn ba okun agbebọn naa nilẹ ninu ọgba fasiti ọhun.

Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe wi, agbebọn naa, to jẹ ọmọ ọdun mẹrinlelogun, lo wa lati abule kan ti ko ju ibusọ mọkanlelogun lọ silu Prague.

Awọn ọlọpaa wi pe agbebọn naa lo ri iwuri latara irufẹ iṣẹlẹ naa to waye loke okun.

Bakan naa ni wọn ni wọn ti ri ara baba rẹ nilẹ.

Iṣẹlẹ naa ni wọn ko lee so pọ mọ igbesunmọmi lagbegbe kọọkan jakejado agbaye, gẹgẹ bi Vit Rakusan ṣe wi.

'A fi ara pamọ nigba ti a gburo ibọn'

Joe Hyland, ọmọ ọdun mejidinlogun to wa fun isinmi nilu Prague pẹlu awọn ọrẹ rẹ ni ko jẹ sina agbegbe naa nigba ti o gburo ibọn.

Hyland wi pe: “baa ṣe gburo ibọn la wa ibi taa maa sa pamọ si lẹyi ti awọn ọlọpaa wi pe ki a maa sa lọ.o bani lẹru.

“Lojiji, awọn eyan bẹrẹ si nii sa. A o mọ ohun to ṣẹlẹ. A ṣaa ri ti awọn ọlọpaa n kọja ti wọn si n wi pe ka maa sa lọ.

“Nigba taa pada de yara wa ni a pe awọn obi wa, tori igba akọkọ ree ti awa nikan yoo wa fun isinmi.”

Aworan ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Reuters

Akọlu agbebọn to buru ju ninu akaatan ile Czech ree

Akọlu to waye losan Ọjọbọ lẹka ẹkọṣẹ ọna ninu ọgba fasiti Charles ni akọlu agbebọn to buru ju ninu itan orilẹede Czech lati ọgbọn ọdun sẹyin ti wọn ti gba ominira.

Akọlu agbebọn to tun ṣẹlẹ laipẹ lo waye lọgba ileewosan kan nilu Ostrava ninu oṣu kejila, ọdun 2019, ti agbebọn kan yinbọn pa ọkunrin mẹrin ati obinrin meji ko too doju ibọn naa kọ ara rẹ.

Ninu oṣu keji, ọdun 2015, ọkunrin kan ṣina ibọn bolẹ ninu ile ounjẹ kan ni ila-oorun Uhersky Brod, to si mu ẹmi awọn mẹjọ lọ.

Bo tilẹ jẹ pe akọlu awọn agbebọn ko wọpọ lorilẹede Czech, ṣiṣe ọdẹ pẹlu ibọn lo gbajumọ.