Ó wùmí láti padà sí Nàìjíríà, àmọ́ mi ò kábámọ̀ pé mo jà fún Yorùbá - Sunday Igboho

Aworan Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, SUNDAY ADEYEMO IGBOHO FOUNDATION/FACEBOOK

Ajijagbara n ni, Oloye Sunday Adeniyi Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti sọ pe o wu oun lati pada si orilẹede Naijiria lati oke okun ki oun si maa ṣiṣẹ oun lọ ti ijọba ba gba oun laaye.

Sunday Igboho sọrọ yii ninu ifọrọwerọ kan to ṣe lori itakun agbaye Facebook.

Igboho sọ pe ''mi o ṣe nkankan bayii ni Germany, mo kan jokoo ti awọn ẹbi mi ni titi ti Ọlọrun yoo fi ṣina fun mi.

Mi o ṣe nkankan bayii ni Germany, mo kan jokoo ti awọn ẹbi mi ni titi ti Ọlọrun yoo fi ṣina fun mi.

Ilẹ Yoruba naa ni karakata mi wa, mọto ni mo n ta lati bi ọdun 1996.

Mo ni igbagbọ pe bi Ọlọrun ba ṣetan to fẹ mu mi wọle, yoo mu mi wọle, yoo si daabo bo mi.

Mo fi gbogbo nkan si ọwọ Ọlọrun.

Amọ, mi o kabamọ pe mo dide fun iran Yoruba

Oloye Igboho ni ohun to wa niwaju oun bayii ni eto isinku iya oun.

Mo maa sinku iya mi laipẹ yii, mo si maa wa nilẹ Yoruba.

Ti mo ba sinku iya mi tan, ti ijọba ba faye gba mi ki n maa ṣowo mi lọ daadaa ni.

Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ẹlẹyẹ iya mi ko siwaju rẹ, mo fẹ ki gbogbo ọmọ Yoruba rọgba yi mi ka ki n le sin iya mi.

Oku iya mi si wa ni mọṣuari di akoko yii, ti mo ba ti le bo iya mi mọlẹ abuṣe ti buṣe.

Ti wọn ba dẹ tun fẹ le, ma a tun pada wa ba awọn ẹbi ni Germany.

Mo rọ Yoruba lati fọwọ sowọ pọ ki gbogbo wa ni iṣọkan ki a le bọ loko ẹru.

A ni lati wa nkan ṣe si eto abo to mẹhẹ nilẹ Yoruba, awọn baba wa o le lọ si oko mọ.

Mo fẹ ki onikalulu ranti wi pe ọjọ ọla awọn ọmọ wa ṣe pataki.''

''Dukia mi ti wọn bajẹ ko ẹmi awọn eeyan to ku''

Lori awọn dukia rẹ ti wọn bajẹ nile rẹ to wa lagbegbe Soka niluu Ibadan, Sunday Igboho ni oun ti fi gbogbo rẹ fun Ọlọrun.

‘’Ṣe ẹ ri gbogbo dukia yẹn, mi o mu un wa sile aye, ẹ fi gbogbo rẹ fun Ọlọrun.

Gbogbo ohun ti mo ni ko ẹmi awọn ti wọn pa nile mi, ko to ẹmi buọda mi ati ọrẹ mi ti wọn pa.

Ija ti a n ja pe ki Yoruba bọ loko ẹru lawọn eeyan ku le lori, ori rẹ naa ni mama ku le.

Ọlọrun ọba to ni mi ni ko gbija mi,'' Igboho ṣalaye.

''Tinubu n gbiyanju fun Yoruba lọwọ yii''

Sunday Igboho ni ''ki Ọlọrun jẹ ki ẹmi Aarẹ Bola Tinubu gun, ọpọ igbesẹ ti o n gbe lo dara fun iran Yoruba.

Ni bayii, ọmọ Yoruba ni ọga agba ọlọpaa Naijiria, bakan naa, ọga agba ajọ to n ri si ijade ati wiwọle si Naijiria, ọmọ Yoruba naa ni.

Ọpọ ipo pataki mii naa lawọn ọmọ Yoruba ti di mu bayii, ipo kan toku ti Yoruba ko tii di mu ni ipo olori ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS.

Mo si ni igbagbọ wi pe, mo si ni igbagbọ wi pe Tinubu yoo ṣee de ibẹ, ki Ọlọrun jẹ ki ẹmi wọn gun.

Amọ, mo si fẹ ki aarẹ Tinubu fi ọrọ Yoruba si ọkan.''