Mohammed, ọmọ Lebanon tó di alásè Àmàlà, Gbẹ̀gìrì àti Ewédú ní Nàìjíríà

Ọpọ igba ni awọn ọmọ Naijiria to kundun ounjẹ Yoruba maa n ke irora pe awọn kii saba ri awọn ounjẹ adayeba ilẹ Yoruba jẹ lawọn ile igbafẹ ti awọn ba lọ paapaajulọ ni ilẹ okeere.
Nitori naa iyalẹnu lo jẹ lati ri oyinbo alawọfunfun kan ti o jẹ wi pe lara awọn ohun to gbajumọ gẹgẹbi alase ni ounjẹ adayeba ilẹ Yoruba.
Mohammed Baydoun jẹ gbajugbaja alase ni orilẹede Naijiria, ti ọpọ si mọọ si inagijẹ rẹ - Amazing Chef.

Iṣẹ aṣela pọ pupọ ni Naijiria ni mo ṣe fi Lebanon silẹ wa si Naijiria - Chef Mohammed Baydoun
Ni ọdun 2018 ni Mohammed wa si orilẹede Naijiria, lati igba naa lo si ti ni ifẹ si awọn ounjẹ ibilẹ.
Ọmọ bibi orilẹede Lebanon ni, amọṣa o ni oun rii pe anfani iṣẹ aṣela pọ pupọ lorilẹede Naijiria loun ṣe tẹ ọkọ leti lati wa si Naijiria.
O ni nigba ti oun de, oun gbiyanju lati kaakiri orilẹede Naijiria, paapaajulọ awọn ọja rẹ gbogbo ati awọn eroja ounjẹ to sodo si orilẹede naa.
- Wo òyìnbó tó ń fi èdè Yorùbá kọrin ju ọmọ Yorùbá míì lọ
- Tiago Isola, akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Ibadan: Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ọ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà
- Mike Ifabunmi: Ifá fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé kò sí ohun ti Ọlọrun kò lè ṣe
- Oluwatoyin Olanipekun: Wo àwọn òyìnbó tó ń kẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá ní Michigan, America
Orileẹde NAijiria ni ewebẹ, ounjẹ sodo si julọ lagbaye

Lọkọọkan ejeeji ni oun si di ẹni to n ni ifẹ si awọn eroja isebẹ ati idana lorilẹede Naijiria.
O ni ounjẹ Naijiria ti oun kọkọ jẹ naa ni, Amala pẹlu Gbẹgiri ati Ewedu.
O ni eyi lo si mu ki ọrọ pari.
O ni awọn eroja isebẹ to sodo si orilẹede Naijiria jẹ eyi ti ko si ni ibomiran lagbaye nitori adun atiẹwa wọn.

“Mo le ro amala, Semo, Wheat; bẹẹ ni mo si tun le gun iyan.
“Mo le ro Ẹfọ, Ewedu ati Gbẹgiri.”
Mohammed Baydoun ni ọbẹ Ẹgusi ni oun fẹran julọ.
















