Kò sí ohun jíjẹ fún wa lásìkò àti lẹ́yìn ọdún Kérésìmesì; àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì àti opó ké gbàjarè ní Osun

Aworan kan ninu awọn opo to ba BBC sọrọ

Lasiko ọdun tawọn kan jẹ ti wọn si n mu ninu ayọ ati alaafia lawọn mii wa ninui inira aisi nkan ti wọn yoo fi gbọ bukata jijẹ ati mimu.

Ika ko dọgba lootọ bẹẹ si ni kii ṣe gbogbo eeyan naa lo le ri taje ṣe amọ pẹlu bi ọpọ araalu ṣe n ke irora yi, asiko yi tubọ jẹ ko ṣoro fawọn ti nkan le fun.

Ni ipinlẹ Osun, awọn oṣiṣẹfẹyinti ati awọn opo kan n ke gbajare pe ki awọn ẹlẹyinju aanu ṣiju aanu wo wọn lasiko ati lẹyin ọdun Kẹresimesi yi.

Laipẹ yii ni Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke fọwọ si iwe idokowo owo ifẹyinti ti o le diẹ ni biliọnu kan ati arundinlọgbọnlelẹgbẹta miliọnu naira fun awọn oṣiṣẹ to fẹyinti pẹlu kikopa ninu idawo ifẹyinti lẹnu iṣẹ pamọ.

BBC News Yoruba ni anfaani lati kan si awọn agbegbe kan ni ipinlẹ Osun nibi ti awọn arugbo ti n rawọ ẹbẹ si awọn ẹlẹyinju anu fun ounjẹ, owo ati ohun nkan miran fun ọdun keresimesi ati ọdun tuntun.

Aworan awọn opo ati oṣiṣẹfẹyinti ni Osun

Ẹnikan ninu awọn ta ṣalabapade ni arabinrin Bolanle Oyewumi to n gbe n'ilu Ikire ni ipinle Osun.

O jẹ osisẹ fẹyinti ati opo gẹgẹ bo ṣe ṣalaye fun BBC News Yoruba.

Ninu ọrọ rẹ,ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin yi sọ pe oun ko ni ireti oun jijẹ lasiko ọdun Keresimesi ati ọdun tuntun to n bọ lọna.

Aworan awọn opo ati oṣiṣẹfẹyinti ni Osun

Arabinrin Bolanle salaye wi pe, oju ọmọ pọn oun lọpọlọpọ ati ninu wahala naa ni ọkọ oun ti fi oun silẹ saye ti ko si si oluranlọwọ kan lati igba naa.

Arabinrin Bolanle nikan kọ ni o wa ninu inira yi.

A ṣalabapade arabinrin Afusat Alimi tohun naa jẹ opo ati arugbo to nilu Apomu-ikire ni ipinle Osun yi kanna.

Aworan awọn opo ati oṣiṣẹfẹyinti ni Osun
Aworan awọn opo ati oṣiṣẹfẹyinti ni Osun

Pẹlu omije loju ni arabinrin Afusat Alimi fi n ṣalaye bi ati jẹ ati mu ṣe ṣoro fun akọroyin wa.

O ni ko si iranlọwọ lati ọdọ ijọba fun awọn opo ati arugbo.

O tun tesiwaju pe, iya naa pọ fun ohun ti ko si si ireti kankan lati le se ajọdun Keresimesi ati ọdun tuntun ninu ayọ ati idunnu.

Nibi taa ti ṣalabapade awọn opo yi ari pe wọn tu jade wa sibi ti ẹlẹyinju aanu kan ti n fun wọn ni nkan ti wọn yoo fi ṣe ọdun.

Aworan awọn opo ati oṣiṣẹfẹyinti ni Osun

Lara awọn taa tun ri ni baba arugbo ẹni ọdun mẹtadinlaadọrun kan.

Saka Sanusi bu sẹkun latari bi ko ṣe ni ireti irẹsi ti yoo fi se ọdun.

Ẹkun naa ti baba yii bu si ni ko jẹ ko le tesiwaju lati ba ikọ Bbc Yoruba sọrọ pupọ lori ilakoja rẹ mọ.

Adeleke buwọ́ lu ₦1.6B fún àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì l’Osun

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, ti fọwọ si iwe idokowo owo ifẹyinti ti o le diẹ ni biliọnu kan ati arundinlọgbọnlelẹgbẹta miliọnu naira fun awọn oṣiṣẹ to fẹyinti pẹlu kikopa ninu idawo ifẹyinti lẹnu iṣẹ pamọ.

Atẹjade kan ti akọwe agba fun ọfiisi to n moju to ifẹyinti awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ nipinlẹ Osun, Ibrahim Akibu, fi lede nilu Osogbo lo sọ eleyi.

Akibu wi pe awọn ti yoo jẹ anfani owo naa ni wọn mu lara awọn oṣiṣẹfẹyinti ileẹkọ alakọbẹrẹ ati ijọba ibilẹ.

Atẹjade naa ka pe “gbogbo awọn ti yoo jẹ anfaani yi jẹ ẹrindinlaadọtalelọọdurun: ti ejilelọgọsan ninu wọn olukọ ileẹkọ alakọbẹrẹ, ti ẹrinlelọgọjọ si jẹ oṣiṣẹ ijọba ibilẹ.

“Fifun awọn oṣiṣẹfẹyinti niwe yii lo jẹ itẹsiwaju ipinnu ijọba ipinlẹ yii lati moju to igbayegbadun awọn oṣiṣe, yala nigba ti wọn ṣi wa lẹnu iṣẹ abi lakoko ifẹyinti.”

Atẹjade naa fi kun pe Gomina Adeleke lo ti bẹrẹ si nii san awọn ajẹsilẹ idaji owo oṣu ti ijọba rẹ jogun atawọn ẹtọ miran tijọba to rekọja n jẹ awọn oṣiṣẹ.