Níbi ìgbìyànjú láti dóòlà ẹ̀mí ọmọ dókítà tí wọ́n jí gbé ní Kwara, fijilanté kàgbákò ikú lọ́wọ́ àwọn agbébọn

Jimọh Suberu, ọkan lara awọn Fijilante Kwara to fẹẹ doola ẹmi ọmọbinrin kan, Christiana Adejọkẹ Alabi, ẹni ọdun mẹtalelogun, ọmọ Dokita oniṣegun oyinbo Adefikayọ Alabi, tawọn agbebọn jigbe lo ti dero ọrun bayii.
Ti ẹ o ba gbagbe, ni Ọjọbọ ọsẹ to kọja ni awọn agbebon ya bo ile Dokita Adefikayọ Alabi, ti wọn yinbọn paa, ti wọn si tun gbe ọmọbinrin rẹ sa lọ.
BBC gbọ pe lọjọ Ẹti, ọjọ kejilelogun, oṣu Kejila yii, tawọn ẹgbẹ fijilante wọnu igbo kan to wa lagbegbe Òkúta, n'ilu Òké-Òyì, nijọba ibilẹ lla-oorun Ilọrin, lati doola ẹmi Adejọkẹ ni awọn Fijilante ati agbebọn koju ija sira wọn.
Lakoko ti wọn si n rọjo ibọn, ti ibọn n ro lakọlakọ ni awọn agbebọn naa yinbọn pa Jimoh Suberu, to jẹ ọmọ ẹgbẹ fijilante nijọba ibilẹ Ìlà-Oòrùn Ilọrin, ni wọọdu Agbéyangí, nipinlẹ Kwara.
Laarọ ọjọ Aiku, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kejila yii, lawọn ẹgbẹ fijilante ipinlẹ Kwara labẹ alaga wọn, Alaaji Ibrahim Seriki-n-Daji, n fi ibanujẹ ọkan wọn han lori bi awọn ṣe padanu akọni kan ninu ẹgbẹ wọn, iyẹn Jimoh Suberu, bi o tilẹ jẹ pe awọn ri ọkan mu lara awọn agbebọn naa lasiko ti ibọn ba a ti ko ribi sa lọ to si n gba itọju nileewosan bayii.
Seriki-n-Daji wi pe pẹlu gbogbo ilakaka ẹgbẹ fijilante ni Kwara lati maa daabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu, ijọba ko ri tawọn ro, tawọn agbebọn si n pa awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun nipakupa.
O wi pe awọn ti n pariwo tipẹ pe ki ijọba ran ẹgbẹ awọn lọwọ nipa fifun awọn ni ibọn ati awọn irinṣẹ miran lati le maa koju awọn ọdaran ṣugbọn pabo lo ja si, ijọba ko ran awọn lọwọ.
'A nilo iranlọwọ ijọba ipinlẹ Kwara'
“Awa la maa n wọ inu igbo lọ koju awọn ọdaran yii, ṣugbọn ṣe ni awọn agbofinro ijọba maa n gboriyin iṣẹ ti a ṣe, to si jẹ pe wọn ko ba wa wọnu igbo lọ.
“Gbogbo awọn fijilante ti wọn ti n padanu ẹmi wọn sọwọ awọn agbebọn yii ni wọn niyawo ti wọn si bimọ, ṣugbọn ijọba ki i ṣe nkankan fun mọlẹbi wọn lẹyin ti wọn ba ti ku.”
Alaga naa wi pe eyi to ṣẹlẹ lọjọ Ẹti ọṣẹ yii ba awọn lọkan jẹ pupọ nitori pe awọn ọlọpaa ti ko tẹle fijilante wọ inu igbo n ṣọ pe awọn ni awọn doola Adejọkẹ, bakan naa ni wọn ko sọ fawọn oniroyin pe awọn agbebọn naa pa fijilante kan.
Seriki-n-Daji waa rọ Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRasaq, ko waa ran ẹgbẹ fijilante lọwọ nipa ipese gbogbo ohun ti wọn nilo lati koju awọn agbebọn to n da omi alaafia ipinlẹ naa ru nitori pe ibọn sakabula lasan ni awọn n lo.
Àwọn agbébọn pa dókítà sínú ilé rẹ̀ ní Kwara, wọ́n tún gbé ọmọbìnrin rẹ̀ lọ

Oríṣun àwòrán, Kirstine Rosas/Pixabay
Awọn olugbe ilu Kambi, ni ijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara ti wọ inu ibanujẹ ati ẹru latari bi awọn agbebọn ṣe ya wọ ile Dokita kan, David Adefikayọ.
Wọn gbẹmi dokita naa, wọn si tun ji ọmọ binrin rẹ to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun gbe lọ.
Iroyin to tẹ BBC Yoruba lọwọ, sọ pe nnkan bii aago mẹjọ abọ, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila, ọdun 2023 yii ni iṣẹlẹ buruku waye waye.
A gbọ pe awọn afurasi ọhun ya bo ilu Kanbi, ti wọn si gba ile Dokita Adefikayọ James Alabi, to jẹ oludari ile iwosan Dafikayo Clinic lọ taara, ti wọn bẹrẹ si ni rọjo ibọn nibi ti wọn ti yinbọn pa Dokita naa.
Idi iṣẹlẹ laabi yii si ṣokunkun si awọn eniyan titi di igba ti a n ko iroyin yii jọ.
Ọkan lara awọn ẹbi oloogbe naa ti a fi orukọ bo lasiri ṣalaye pe dokita naa bẹ awọn agbenipa yii, koda, o fi owo ati ohun gbogbo ti wọn ba n fẹ bẹ wọn, ṣugbon wo ko gba, wọn yinbon paa niwaju iyawo ati awọn ọmọ rẹ.
O ni ohun to tun ba ni ninu jẹ julọ ni ti abi gbẹyin rẹ, ọmọbinrin ọdun mẹrindinlogun ti wọn tun gbe lọ.
Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.
O ni lootọ ni awọn gba ipe pajawiri pe awọn agbebọn ya bo ilu Kanbi, nijọba ibilẹ Moro, ti wọn si ṣekupa Dokita Adefikayọ, ti wọn si ji ọmọ binrin oloogbe gbe naa salọ.
O ni ikọ ẹsọ alaabo ti ya bo inu igbo to wa lagbegbe naa, ti wọn si ti n lakaka lati doola ẹmi ọmọ binrin ti wọn ji gbe tawọn yoo si mu awọn afurasi ajinigbe, ti ileeṣẹ ọlọpaa yoo si fi wọn jofin.
Sugbọn ni dede ago mẹjọ alẹ ọjọ Ẹti, Adetoun fidi rẹ mulẹ pe, pẹlu atilẹyin awọn fijilante, ileesẹ ọlọpaa ti doola ọmọbinrin ọhun, o si ti dara pọ mo awọn molẹbi rẹ.
O ni lotitọ, awọn ko tii ri awọn agbenipa naa mu ṣugbon iwadii si n lọ lọwọ lori rẹ lati rii pe wọn fimu kata ofin.














