Sheikh Dahiru Bauchi kọ lẹ́tà sí adájọ àgbà Nàìjíríà lórí ìdájọ ìdìbò Kano lariwo bá sọ

Oríṣun àwòrán, BBC
Awuyewuye ti n waye ni ilu Kano lẹyin ti iwe kan lati ọwọ Sheikh Dahiru Bauchi si awọn adajọ agba ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lu sita.
Bawọn kan ṣe n sọ pe kii ṣe Sheikh Dahiru lo kọ iwe yi l'awọn mii n sọ pe lati ọwọ rẹ ni lẹta yi ti wa.
Ọrọ idajọ lori esi idibo Gomina to waye ni Kano jẹ eleyi tàwọn eeyan n ran lẹnu ni ẹnu ọjọ mẹta yii.
Lọjọ Ẹtì yi ni iwe naa ti a ri pe ibuwọlu Sheikh naa wa lori rẹ lu sita ti wọn sì kọ sibẹ pe lọjọ Kini oṣu Kejila ni Sheikh kọ iwe naa.
Adajọ agba Naijiria Adajọ Olukayode Ariwoola ni wọn lo fi iwe yi ranṣẹ si.
Ibeere nla to si gbode bayii ni pe ṣe Sheikh Dahiru lo kọ lootọ ati pe ki lo mu kọ iwe yi lori idajọ idibo Gomina to waye ni Kano.
Ta ni Sheikh Dahiru ati pe ki lo wa ninu lẹta to kọ si adajọ agba Naijiria
Olori ẹgbẹ esin Islaamu Tijjaniya ni ilẹ ariwa Naijiria ni Sheikh Dahiru Bauchi jẹ.
Ipo yi jẹ ipo ọwọ laarin awọn alatilẹyin rẹ to si mu ki ọpọ awọn oloṣelu ati alaṣẹ maa foju apọnle wo o.
Ninu iwe taa n sọ yii, ọkan ninu awọn ọmọ Sheikh Bauchi Naziru Dahiru fidi ọrọ mulẹ pe lootọ ni Sheikh Dahiru kọ iwe yi.
Lọjọ Abamẹta lo fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC Hausa.
Ko pẹ si igba naa ti awọn ileeṣẹ iroyin kan gbe iroyin yi jade ni ọmọ Sheikh yi miran Bashiru Dahiru sọ fun BBC pe kii ṣe baba oun lo buwọlu iwe naa.
O ni " bi ẹ ṣe ri iwe yi naa lawa naa ṣe ri.Sheikh sọ pe awọn kọ láwọn kọ ati pe wọn ko mọ nípa rẹ"
Alaye yi lo ṣe nigba to kopa lori eto BBC kan l'owurọ ọjọ Aiku.
O fikun pe ọrọ atẹjiṣẹ ohun Sheikh naa kan gbode nibi to ti sọpẹ oun ko kọ lẹta kankan ati pe lọdọ oun kọ ni iwe yi ti jade.
Ko tan sibẹ ọmọ Sheikh Dahiru taa mẹnu ba lakọkọ Naziru Dahiru ti bọ sí oju opo Facebook lọjọ Aiku to si tẹnumọ pe oun loun gbe iwe yi lọ jisẹ fun adajọ agba ti baba rẹ si mọ nipa iwe yi.
O sọ pe "Emi gangan ni mo gbe iwe to n rain loju opo ayelujara yi jisẹ nigba ti mo ṣì gbe fun wọn ni ọfisi adajọ agba wọn da iwe ijẹrisi pada fun mi"
Koda o ni oun loun lọ ba baba rẹ Sheikh Dahiru Bauchi pe ko dasi ọrọ awuyewuye idajọ lori esi idibo Gomina ipinlẹ Kano ki o si beere fun idajọ ododo lori ọrọ yi.
Ninu fọnran yi lori Facebook Dahiru n sọ fún baba rẹ ninu ipe lori ago pe : "awọn olori Naijiria n reti kẹ beere idajọ ododo tori a o fẹ ki nkankan ṣẹlẹ ni Kano.Ti nkan ba de Kano gbogbo Naijiria ni yoo kan an."
A ko gbọ esi Sheikh Bauchi ninu ipe yi ko to ja.
A mọ ṣa ọrọ to wa ninu lẹta yi fara pẹ ọrọ ti ọmọ rẹ loun tori rẹ kesi Sheikh ko dasi awuyewuye lori idibo Kano yi.

Oríṣun àwòrán, Naziru Dahiru












