Àwọn olólùfẹ́ ANPP wọ́de ní Kano, ìgbìmọ̀ ètò ìdájọ́ ní Nàìjíríà pinnu láti wádìí awuyewuye ìwe ìdájọ́ ìdìbò gómìnà níbẹ̀

Aworan awọn olufẹhonu han

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ to n moju to eto idajọ lorilẹede Naijiria, NJC, ni oun yoo ṣe iwadii oun to fa edeaiyede nipa iwe idajọ ileẹjọ kotẹmilọrun lori igbẹjọ esi ibo gomina nipinlẹ Kano.

Ileeṣẹ iroyin abẹle kan lorilẹede Naijiria, Daily Trust gbe iroyin sita lọjọru pe awọn ọmọ ajọ naa kan sọ eyi nigba ti wọn ṣe abẹwo si oluileeṣẹ wọn nilu Abuja lọjọ Iṣẹgun.

Oriṣiriṣi ariyanjiyan lo ti waye lori idajọ naa ti ọpọ si ti bu ẹnu atẹ lu iwe idajọ ọhun lẹyin ti wọn rii pe ohun ti wọn kọ sinu iwe idajọ naa tako ara wọn.

Idajọ ileẹjọ kotẹmilọrun naa ni pe Yusuf Gawuna ti ẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori, ti wọn si ni ki Gomina Abba Kabir Yusuf o kuro lori aleefa nitori kii ṣe ọmọ ẹgbẹ ANPP to gbee wọle.

Ẹwẹ, ninu iwe idajọ ọhun tileẹjọ fi lede, apa kan iwe ọun wi pe Abba Kabir Yusuf lo yege, ti abala miran ninu iwe ọun si ni Yusuf Gawuna lo bori.

Bo tilẹ jẹ pe akọwe agba ileẹjọ kotẹmilọrun naa, Umar Mohammed Bangari, ti jade lati wi pe oun gba ẹbi aṣitẹ iwe ọhun, o ni idajọ ileẹjọ naa ṣi duro sibẹ.

Igbimọ naa wi pe gbogbo iwe ẹsun ti awọn araalu kọ ranṣẹ si awọn ni awọn ti ri, ti wọn yoo si ṣiṣẹ le lori bo ṣe yẹ.

Awọn alatilẹyin NNPP ko sinmi ifẹhonu han

Awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu NNPP nipinlẹ Kano lo n tẹsiwaju pẹlu iwọde ifẹhonu han alalaafia ti wọn ṣe tako ohun ti wọn juwe bii “igbiyanju lati yi esi ibo gomina ipinlẹ naa”.

Eyi lo n waye lẹyin ti ileẹjọ kotẹmilọrun wọgi le ibo to gbe Gomina Abba Kabir Yusuf wọle.

Ẹwe, kọmiṣọna ajọ ọlọpaa nipinlẹ Kano, Mohammed Usaini Gumel, lo ti paṣẹ ki wọn ọlọpaa kan ti wọn funra si pe o yinbọn mọ awọn ọdọ kan leyi to ṣekupa ọkan ninu wọn to waa mu ki wọn maa ṣe ifẹhonu han.