Ìkúnlẹ̀ Abiyamọ! Ọmọ ọdún mẹ́rin tó ń darí láti ṣọ́ọ̀ṣì kàgbákò ikú lẹ́yìn tó já sí 'canal'

Oríṣun àwòrán, Getty
Ibanujẹ ti dori ẹbi arakunrin Olabode Oyedokun kodo lẹyin ti ọmọ wọn ọkunrin ọdun mẹrin,Daniel, ri sinu omi 'canal' nigba to n dari bọ lati ile ijọsin lọjọ Aiku.
Opopona Awori ni Dopemu l'Eko ni iṣẹlẹ yi ti waye.
Ileeṣẹ iroyin Naijiria nii, Punch Metro, jabọ pe agbara omi to ba ọpọ ojo to rọ lọjọ naa wa lo gbe ọmọ yi lọ.
Baba ọmọ naa ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin naa sọ pe alabagbe wọn kan ni ọmọ naa tẹle lọ si ile ijọsin lọjọ iṣẹlẹ yi.
Olabode ti ọpọ mọ si Baba Ibeji sọ pe nigba toun pada dele loun baa ti ero pejọ ti wọn si n sunkun.
O ni nigba toun beere pe ki lo ṣẹlẹ ni wọn sọ pe ọmọ rẹ lo ja si 'canal'
Eti gọta ni Daniel duro si ko to ja si inu omi 'canal'
Baba ọmọ to ṣalaisi yi sọ pe ọdọ kan to jẹ ibatan alabagbe oun lo ko ọmọ yi ati awọn ọmọ mii lọ si ile ijọsin.
Olabode fi kun pe ''Daniel loun fẹ tẹle alabagbe mii lọ si ṣọọṣi mo si yọnda pe ki o tẹle wọn. Ara mi ko ya daada ni ko jẹ ki n mu lọ si ile ijọsin wa.''
''Aburo alabagbe wa lo ko wọn lọ si ṣọọṣi nigba ti wọn si pari nibẹ lo bẹrẹ si ni ko wọn pada wa sile tohun ti pe ojo n rọ lọwọ
O sọ pe nigba ti wọn yoo fi de eti gọta ọmọ obinrin yi bẹrẹ si ni gbe awọn ọmọ naa sọda lọkọọkan.
''O ni ki Daniel duro si eti Canal bo ṣe n gbe awọn iyoku sọda ṣugbọn ẹsẹ rẹ ṣeṣi yẹ to si ja sinu omi''
''Bi mo ṣe de ile ti mo ri ero niwaju ita mi ni mo sare lọ si agọ ọlọpaa lẹyin ti wọn sọ fun mi pe Daniel ko si omi.''
''Mi o mọ nkan ti maa ṣe.Wọn sọ pe inu gọta ni wọn ti ri oku rẹ tori naa ni mo fi lọ si agọ ọlọpaa lọgbe oku rẹ taa si sin.''
Ile ijọsin to jẹ ki awọn ọmọ tori bọ ojo ni mo da lẹbi
Ọmọ bibi ipinlẹ Ekiti yi sọ pe oun da ile ijọsin to faaye gba awọn ọmọde lati jade ninu ile ijọsin lasiko ojo lẹbi.
''Ile ijọsin ni mo ri bawi.Ko yẹ ki wọn jẹ ki awọn ọmọde yi jade lasiko tojo n rọ bayẹn.O yẹ ki wọn ti ilẹkun mọ wọn titi ti ojo naa yoo fi da ni.
O tẹsiwaju pe ''ọmọ obinrin to ko wọn lọ si ile ijọsin ko ju bi dun mẹẹdogun si mẹrindinlogun. O wa nile mi bayi to n sunkun.Kini mo fẹ ṣe? Ọmọ mi ti lọ. Ọmọ mi ti lọ''
Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ nipa iyawo rẹ, o ni ko le sọrọ tori ko dakẹ ẹkun lati igba ti iṣẹlẹ yi ti waye.
Baba Ibeji sọ pe awn dupẹ pe awn ṣi lawọn ibeji ọkunrin ati obinrin kan to ṣẹku ninu awọn ọmọ wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa gẹgẹ bi Punch Metro ti ṣe wi fidi iṣẹlẹ yi mulẹ.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ SP Benjamin Hundeyin kilọ pe ki awọn obi maa mojuto awọn ọmọ wn.
A ko gbọ nkankan nipa boya wn yoo fẹsun kan ile ijọsin naa tori pe ko mojuto awn ọmọ ti wọn ko wa jọsin lọdọ rẹ.














