Èèmọ̀! Ọkọ ìyàwó ṣíná ìbọn bolẹ̀ lọ́jọ́ ìgbeyàwó rẹ̀, ìyàwó àti èèyàn mẹ́ta jáde láyé

Aworan ibọn

Oríṣun àwòrán, Getty

Ọkọ iyawo kan ti ṣekupa eeyan mẹrin lọjọ igbeyawo rẹ lorileede Thailand.

Iyawo rẹ ati awọn eeyan mẹta mii lo kagbako iku lọwọ ọkọ iyawo naa to ti fi igbakan ri jẹ ọmọ ogun ati akanda elere idaraya.

Ni agbegbe ila oorun ariwa Thailand lọjọ Abamẹta ni wọn ṣeto igbeyawo Chaturong Suksuk, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ati Kanchana Pachunthuek ẹni ọdun mẹrinlelogoji.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹwa lọwọ, ṣadede lo kuro nibi eto igbeyawo naa to si pada de pẹlu ibọn to fi pa iyawo rẹ, mama iyawo rẹ ati ẹgbọn iyawo.

Ẹni ọdun mejilelọgọta ni iya iyawo rẹ ṣe ti ẹgbọn iyawo rẹ si jẹ ẹni ọdun mejidinlogoji.

Ọta ibọn ba awọn alejo meji kan ti wọn sare gbe lọ si ile iwosan.

Ọkan ninu wọn pada dagbere faye.

Awọn ọlọpaa sọ fun BBC Chaturong pe ''o ti mọti yo nigba naa'' ṣugbọn awọn ko mọ idi to fi hu iru iwa yi.

Wọn fi kun pe lọdun to kọja lo ra ibọn ati ọta naa lọna ẹtọ.

Awọn ileeṣẹ iroyin Thailand jabọ pe aigboraẹni ye kan waye laarin tọkọ-taya lasiko apejẹ igbeyawo wọn.

Bẹẹ niwọn tun sọ pe iyatọ to wa laarin ọjọ ori wọn naa tun jẹ nkan to n kan ọkọ iyawo naa lominu.

Iyawo gba ọdun marun un lọwọ ọkọ.

Amọ ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ahesọ ṣi ni gbogbo eyi jẹ ti wọn si lawọn ṣi n ṣe iwadii lati le wa ojutu si ọrọ naa ni ''kiakia''

Chaturong ati Kanchana ti jijọ gbe papọ fun ọdun mẹta ṣaaju ki wọn to ṣe igbeyawo gẹgẹ bi awọn ileeṣẹ iroyin ṣe wi.

Lọdun to kọja ni Chaturong gbami ẹyẹ fadaka nibi idije omuwẹAesean Para Games ni Indonesia.

A tun gbọ pe orukọ rẹ wa ninu awọn ẹlere idaraya to n kopa nibi idije agbaye awọn akanda ti yoo waye ni Thailand loṣu to n bọ.

Lasiko to wa lẹnu iṣẹ ibode ṣiṣọ pẹlu awọn ọmọ ileeṣẹ ologun Thailand lo padanu ẹsẹ ọtun rẹ

Bo tilẹ jẹ wipe fifi ibọn pa ọpọ eeyan ko wọpọ ni Thailand, ko jẹ nkan tuntun pe ka ri awọn eeyan to da ibọn ni laaye ara wọn.

Loṣu to kọja eeyan mẹta kan padanu ẹmi wọn nile itaja olowo nla kan ni Bangkok.

Loṣu Kẹwaa to kọja bakan naa,ọlọpaa tẹlẹ ri kan fi ibọn ati ọbẹ ṣeku pa awọn ọmọde mẹtadinlogoji ni ile ẹkọ jẹleosinmi kan ni ila oorun ariwa Thailand.