Ọwọ́ tẹ afurasí tó fi èrú jí owó ‘Bitcoin’ tó lé ní ₦200M látorí ìtàkùn àgbáyé

Aworan awọn ọdaran

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Police Force

Ajọ ọlọpaa orilẹ-ede Naijiria lo ti fi panpẹ ọba mu ọkunrin ti wọn pe ni Wilfred Bonse to nii ṣe pẹlu oniruuru jibiti leyi ti ileeṣẹ ‘Patricia Technologies Limited’ fi to wọn leti lẹyin ọpọlọpọ iwadii.

Ọrọ ọhun, gẹgẹ bi wọn ṣe to ọga agba ajọ ọlọpaa ni Naijiria leti, lo da lori iwa jibiti to nii ṣe pẹlu iditẹpọ lati hu iwa ọdaran, yiyi akọọlẹ ori ẹrọ kọmputa lai gba aṣẹ, ati didari owo to le ni igba miliọnu naira kuro ninu asunwọn to wa si omiran lọna ti ko bofin mu.

Agbẹnusọ ajọ ọlọpaa ni Naijiria, Olumuyiwa Adejọbi to fi ọrọ naa lede loju opo facebook rẹ wi pe ọpọ ifimufinlẹ ati iwadii to jinlẹ ni ajọ naa ṣe ki ọwọ too tẹ Bonse.

Ninu iwe ti Patricia Technologies kọ si ajọ ọlọpaa ni wọn ti ṣalaye pe ọkunrin naa ati awọn kan ti wọn ko tii ri, lo lo ọgbọn alumọkọrọyi lati yọ owo ori ẹrọ ayelujara taa mọ si ‘crypto’ ninu awọn asunwọn to wa, to fi mọ eyi to wa pẹlu Flutterwave.

Bonse, ni iwadi fihan pe, o dari aadọta miliọnu naira lọna aitọ sinu asunwọn ile ifowopamọ rẹ latinu ẹgbẹta miliọnu o le meje naira ti wọn ji ko, ninu asunwọn Patricia Technologies.

Ni bi iwadii ṣe n tẹsiwaju, ajọ ọlọpaa fi da awọn araalu loju pe gbogbo ẹni to lọwọ ninu iwa jibiti ni yoo foju wina ofin ọba.

Bakan naa ni wọn mu awọn mẹta miran fun lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara

Adejobi tẹsiwaju ninu atẹjade naa pe lẹyin ti ikọ to n gbogun ti lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara lajọ naa gunle iwadii ijinlẹ lati ṣiṣọ loju awọn kan ti wọn n fi orukọ olorukọ lu jibiti ni wọn wọ Wumba District ni Apo, nilu Abuja ni ogunjọ oṣu kẹsan ọdun 2023 ti wọn si mu awọn mẹta kan.

Njoku Kinglsey ati Jideofor Sejus ti wọn jẹ ọmọ ọdun marundinlogoji ati Chigozie Okorie to jẹ ọmọ ọdun mẹrinlelọgbọn ni wọn mu lọjọ naa fun ẹsun igbimọpọ lati huwa ibi, lilo orukọ ati aworan ẹlomiran bii tiwọn ati fifi ifẹ lu jibiti.

Adejobi wi pe iwadi fihan pe awọn mẹtẹẹta ni wọn jumọ n jẹ orukọ Anthony James ti wọn n lo aworan rẹ lati fi parọ fun awọn kan pe wọn nifẹ wọn ti wọn si n fi eyi gba ohun ini awọn bẹẹ.

Adejobi wi pe awọn mẹtẹẹta ni wọn ti jẹwọ ipa ti wọn ko ninu iṣẹlẹ naa ti igbiyanju si n lọ lọwọ lati rii pe awọn to ti bọ si panpẹ awọn onijibiti yii gba itura ati atilẹyin to yẹ.

Adejobi to wi pe awọn afurasi yoo foju ba ile-ẹjọ laipẹ waa rọ gbogbo awọn to n ṣe ọrọ ifẹ lori ẹrọ ayelujara lati yago fun fifi ohun inii wọn dọrẹ.

aworan Komputa

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Police Force

Iwadi miran mu ki wọn gba owo to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọgọjọ dollar pada

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agbẹnusọ ajọ ọlọpaa naa tẹsiwaju ninu atẹjade rẹ pe NPF-NCCC ni wọ ba oniṣowo crypto kan gba owo to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọgọjọ dollar pada lọwọ onijibi kan.

Gẹgẹ bii Adejobi ṣe wi “Ummulkulthum Basha ni o dowopọ pẹlu Sean Andres Delacruz lẹyin tawọn mejeeji pade lori ikanni atẹjiṣẹ telegram

“Basha ni o rọ Delacruz lati ba oun ere ti yoo di ẹgbẹrun lọna ogun dollar ti oun padanu ninu idokowo crypto lẹyin ti awọn mejeeji di ọrẹ, ti Delacruz si fi ṣe ọkan lara awọn adari loju opo @kochikenbsc ni telegram.

“Delacruz fi daa loju pe ti oun ba baa fi ẹgbẹrun lọna ọgọjọ to wa lọwọ rẹ ṣowo, yoo jere ti yoo di ofo rẹ ni kia.

“Ẹwẹ, yiyọ owo ninu asunwọn crypto Basha lẹẹmeji lera wọn sinu asunwọn crypto Delacruz lo mu ifunra dani.

“Lara owo yii ni Delacruz ti fi awọn kan pamọ si oju-opo idokowo crypto miran ti wọn n pe ni KuCoin.

“Ajọṣepọ laarin ajọ ọlọpaa ati KuCoin n la fi mọ pe Delacruz lo ni asunwọn ti owo naa wa.

“Lẹyin ọpọ iwadii la rii pe niṣe ni Delacruz fẹẹ fi ọgbọn alumọkọrọyi gba gbogbo ẹgbẹrun lọna ọgọjọ dollar naa ninu asunwọn Basha lai jẹ ki KuCoin mọ jibiti to fẹẹ lu.

“Bo tilẹ jẹ pe ajọṣepọ laarin awọn ileeṣẹ ilẹ okeere yii pẹlu ajọ ọlọpaa ti mu ki wọn da owo naa pada, iwadii ṣi n tẹsiwaju lati le mu Delacruz ko lee fimu danrin.”

Adejobi fi kun pe ajọ ọlọpaa ilẹ Naijiria rọ awọn araalu lati ṣọra fun awọn onijibi ti n polowo owo sọgundogoji ki owo wọn maa baa wọgbo.