"Boko Haram tó wà lẹ́wọ̀n jẹ́wọ́ pé àwọn ń lo àpò owó Wọ́dà láti gba owó táwọn yóò pìn-ín"

Oríṣun àwòrán, Nigeria Correctional Service
Minista to n ri si ọrọ abẹle lorilẹ-ede yii, Olubunmi Tunji Ojo, ti paṣẹ pe ki ọga agba to n ri si ọgba ẹwọn, Haliru Nababa, bẹrẹ iwadii lori awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn kan tẹnu n kun pe wọn n gbabọde fawọn agbesunmọmi, ki wọn le fọwọ ofin mu wọn.
Eyi waye latari ẹsun ti ọga ologun agba, Chris Musa, fi kan awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn kan, paapaa julọ, awọn wọda, pe wọn n ṣajọpin owo pẹlu awọn agbebọn, agbesunmọmi, wọn si n ran wọn lọwọ lati ṣiṣẹ ibi wọn.
Ọgagun Musa ṣalaye nile igbimọ Aṣoju lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii, pe awọn Boko Haram tọwọ ba lagbegbe Ariwa-Ila-Oorun, jẹwọ pe awọn maa n lo akanti awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn kan lati gbowo lọwọ awọn eeyan.
''ọmọ ẹgbẹ Boko Haram jẹwọ pe awọn maa n lo akanti awọn wọda lati gba owo tawọn yoo jọ pin"
‘’ Wọn maa n lo awọn wọda to n dari ọgba ẹwọn, ki i ṣe gbogbo wọn, ṣugbọn awọn kan wa ti wọn n ṣagbodegba fawọn agbesunmọmi.
‘’Awọn Boko Haram yẹn sọ fun wa pe awọn maa n ṣeto ikọlu pẹlu iranlọwọ tawọn n ri gba lati ọgba ẹwọn, wọn lawọn maa n pin owo fawọn to n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn nibẹ’’
Bẹẹ ni Ọgagun Chris Musa ṣalaye.
Nigba to n fesi si ẹsun yii ninu atẹjade to fi sita l’ Ọjọbọ, Minista fun ọrọ abẹle, Olubunmi Tunji-Ojo, sọ pe iwadii gbọdọ bẹrẹ lati mọ awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn to n gbabọde, o ni ẹnikẹni tọwọ ba tẹ yoo jiya to tọ labẹ ofin.
O ni asiko ileri lai mu un ṣẹ ti kọja, ireti ọtun ti iṣakoso Aarẹ Tinubu gbe dani yii yoo so eso rere pẹlu ohun to n ṣe.
Bẹẹ lo ni kawọn araalu fọkan balẹ lori atunṣe ọgba ẹwọn, nitori ijọba yoo tun un ṣe laipẹ ti yoo si wa ni ibamu pẹlu tawọn ilẹ okeere, nibi ti wọn ti n tun wọn rọ si rere.

Oríṣun àwòrán, DefenceHQ
Olori awọn osisẹ alaabo lorileede Naijiria ti figbe ta pe ori awọn nikan kọ lo yẹ ki araalu di ẹbi aabo to mẹhẹ le.
Ọgagun Chris Musa ti wa sọ pe ẹka idajọ, ileeṣẹ ọgba ẹwọn ati orileede ilẹ okere kan lo lẹbi bi awọn agbofinro ko ṣe ribi koju awọn ipenija aabo to n koju Naijiria.
O fidi ọrọ yi mulẹ lasiko ti o lewaju awọn ọga ileeṣẹ ologun Naijiria ati ọga ileeṣẹ ọlọpaa, Kayode Egbetokun, lati lọ jabọ bi eto aabo ṣe ri niwaju ile aṣoju ṣofin Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Defence Headquarters Nigeria
"Apẹrẹ isejọba rere wa lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria ni ipese aabo se peye nibẹ"
Yiyọju ọga ileeṣẹ aabo ati awọn agbofinro mii yi n waye lẹyin ti ile aṣofin ti da awọn ọmọ iṣẹ wọn ti wọn kọkọ ran wa lỌjọbọ pada wi pe awọn to jẹ ọga lawọn fẹ foju kan.
Ọgagun Musa to tọrọ aforijin idi ti wọn ko fi ribi yọju ṣaaju tẹlẹ sọ pe awọn ko mọọmọ kọ lati yọju sile.
O ni awọn to wa nidi aabo ti ri pe ko si na abayọ onikiakia kankan to le wa ojutu si aabbo to mẹhẹ bi kii ṣe pe ki iṣejoba to munadoko wa nilẹ.
O ni ''gbogbo ibi ti iṣejọba ba ti gunrege, o di dandan ki eeto aabo naa gbamuṣe.''
O ni idi ti awọn ologun fi ribi pese aabo to peye ni iwọ oorun ariwa Naijiria ni pe apẹrẹ iṣejọba daada wa nibẹ.
O wa fikun pe ipese aabo to peye kii ṣe ojuṣe awọn agbofinro nikan, bi ko ṣe ti gbogbo araalu.
"Ẹ̀mi awa agbofinro wa ninu ewu bi wọn se n gba beeli ọmọ ẹgbẹ Booko Haram ta ba mu"
Ninu atotonu rẹ niwaju ile o sọ pe aabo ẹmi nikan kọ lo yẹ ki orileede mojuto.
O ni aabo ilera, ounjẹ ẹkọ ati tawujọ naa ṣe pataki.
O di ẹbi ailese pese aabo to peye lori ẹka idajọ.
Musa sọ pe ''Mo ti pẹ ni ila oorun ariwa mo si ti ri bi wọn ṣe mu awọn ọmọ ikọ Boko Haram nibẹ.''
O ni awọn ti fi wọn sahamọ fun bi ọdun marun un si mẹfa ṣugbọn ẹka idajọ ko gbe igbesẹ ki wọn baa le kawọ pẹyin rojọ.
''Ologun la wa. A kan le mu wọn ni ṣugbọn a ko le dajọ le wọn lori''
O tẹsiwaju pe nigba mii tawọn ba ṣe wahala lati mu awọn ọmọ ikọ agbesunmọmi yi tan tawọn si fawọn le awọn to kan lọwọ, ko ni pẹ ti wọn yoo fi gba beeli wọn, ti wọn yoo si tu wọn silẹ pada.
''Bayii o ti fi ẹmi ara rẹ sinu ewu tori awọn wọn yi yoo pada lọ sọ fun awọn iyoku rẹ pe iwọ lo mu oun.
Ni bayii ẹmi iwọ ati mọlẹbi rẹ ti wa ni inu ewu''

Oríṣun àwòrán, NTA
"Awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn n lẹdi apo pọ pẹlu Boko Haram lati pete ikọlu latinu ọgba ẹwọn"
Musa ṣalaye pe iru nkan bayii naa n waye lagbegbe Guusu Naijiria.
''Ọpọ awọn ọkọ oju omi fayawọ ta baa mu, wọn yoo pada lọ yi orukọ tabi ki wọn si yi ọda ara rẹ pada.
Kete to ba ri ọkọ naa mu, to si fa le awọn alaṣẹ lọwọ, nibẹ naa ni wọn yoo ti tu wọn silẹ pe ki wọn maa lọ.
A gbọdọ ni ile ẹjọ ọtọ ti yoo ma mojuto iru nkan bayii''
Nipa bi awọn ọlọgba ẹwọn ṣe lẹbi, o ni ''Bi a ba ti mu awọn ikọ Boko Haram, ta a si n gba ọrọ kalẹ lẹnu wọn, wọn a maa tu aṣiri bi awọn ṣe maa n pete ikọlu mii lati inu ọgba ẹwọn.''
O fẹsun kan awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn pe wọn a lẹdi apo pọ pẹlu awọn Boko Haram.
''A ko sọ pe gbogbo wọn lo ti gbabọde ṣugbọn wọn a maa fi akoto owo wọn gba owo ti wọn yoo fi ṣeto ikọlu mii. Ẹnikẹni ti wọn ba fi akanti rẹ gba owo, wọn o jijọ pin owo naa deede ni.Awọn ipenija taa n koju ree''
"Finland n gba alaburu laaye lorileede wọn"
Lakotan ọgagun ileeṣẹ aabo Naijiria yi sọ pe ni Guusu iwọ oorun Naijiria, Simon Ekpa ọkan lara awọn olori ikọ agbesunmọmi IPOB n sa sabẹ aabo orileede Finland.
O ni lati ibẹ lo ti n foro ẹmi awọn eeyan to wa lagbegbe yi ni Naijiria.
''Orileede Finland n gba ni iyanju lati maa se gbogbo nkan to n ṣe.Ọrọ ati iṣesi rẹ n dakun nkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria.Ko yẹ ka faaye gba iru nkan bayii''
Gẹgẹ bi ọna abayọ, o ni ki awọn ẹka ileeṣẹ to n mojuto ọrọ ilẹ okere da si yla nipa ki wọn pe aṣojuorileede naa ni Naijiria lati wa ṣalaye idi ti wọn fi n da aabo bo Ekpa.
''Akoba nla lo n ṣe fun wa tori nipa ọrọ ẹnu rẹ, ọpọ eeyan lo ti padanu ẹmi wọn''














