Ǹ jẹ́ Peseiro àti Super Eagles lè fakọyọ nínú ìdíje Afcon tó ń bọ̀?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ ololufẹ ere bọọlu lorilẹede Naijiria ni ko ni igboya mọ ninu ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles lẹyin ti wọn ta ọmi pẹlu orilẹede Lesotho ati Zimbabwe ninu ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye 2026 World Cup.
O tun di oṣu Kẹfa ọdun 2024 ki Super Eagles tun to koju orilẹede mii ninu ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun ife ẹyẹ agbaye 2026 World Cup.
Amọ, ni bayii, idije Afcon 2023 ti yoo bẹrẹ ninu oṣu Kinni ọdun 2024 lorilẹede Ivory Coast lo wa niwaju Super Eagles.
Isọri ‘’A’’ ni Naijiria wa ninu idije naa pẹlu orilẹede Ivory Coast to yoo gbalejo idije naa ati Guinea-Bissau to fi mọ Equatorial Guinea.
Amọ, ṣe Super Eagles le jẹwọ orukọ ara wọn ki wọn si fakọyọ ni Ivory Coast?
Moses Simon to jẹ ọkan lara awọn agbabọọlu iwaju fun Super Eagles sọ loju opo X rẹ pe ọpọ ipenija lawọn ti bori sẹyin.
Simon ni akoko tito fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles lati ji giri.
Ọpọ lo gbagbọ pe Super Eagles yoo tun gbinaya nigba ti ẹlẹsẹ ayo Victor Osimhen ba gbadun ẹsẹ to fi ṣeṣe.
Agbabọọlu Naijiria tẹlẹ ri, Duke Udi sọ pe o ṣeeṣe ki Naijiria gba ife ẹyẹ Afcon fun igba kẹrin.
Udi ni akọnimọọgba Jose Peseiro naa lo ṣi le ṣiṣẹ Super Eagles lasiko yii.
Udi ṣalaye pe ko bojumu ki wọn jawe gbele ẹ fun Peseiro nitori Naijiria ta ọmi pẹlu Lesotho ati Zimbabwe.
O gbagbọ pe Naijiria ṣi le pegede lati kopa ninu ife ẹyẹ agbaye 2026 World Cup.
Udi ni Super Eagles Naijiria ṣi le fakọyọ ninu Afcon 2023 ni Ivory Coast.















