Afcon 2023: Mo rọ̀ yín láti ṣe àtìlẹyìn fún aṣọ́lé mi Uzoho -Jose Paseiro bẹ àwọn ọmọ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Oluwashina Okeleji
- Role, Football Writer
Akọnimọgba fun ikọ Super Eagles ti orilẹede Naijiria, Jose Paseiro ti ni oun ṣe atilẹyin fun asole ikọ naa ti ẹnu n kun lọwọlọwọ, Francis Uzoho nitori pe ko si agbabọọlu ti ko le se asise.
Bi Uzoho ṣe n mule lasiko ti Super Eagles koju ikọ orilẹede Saudi Arabia ati Mozambique ni bi ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ ni ọpọ ti bu ẹnu atẹlu. ti inu wọn ko si dun si aṣọle naa ṣe mule.
Aṣọle ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Omonia Nicosia, to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun ni ọpọ asise rẹ ti fa ijakinlẹ si ikọ rẹ. Asisẹ to fa ariwo yii ni eyi to waye lasiko ti ikọ Super Eagles n koju ikọ Saudi Arabia, to si fi ọwọ rẹ gba bọọlu si ile ara rẹ.
"Ni Naijiria, ni gbogbo igba ni wọn kọlu Aṣọle," Paseiro sọ fun BBC Sport Africa.
"Kilode ti a ko ki n bu ẹnu atẹlu awọn agba ọwọ iwaju ti wọn kọ lati mi awọn? Nkankan naa ni."
Uzoho ko ti kopa fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu rẹ ni saa yii.
Sugbọn Peseiro ni oun n ṣe atilẹyin fun aṣọle akọkọ rẹ, ẹni to bẹrẹ si ni soju ikọ Super Eagles ni ẹni ọdun mọkandinlogun.
"Ti mo ba ni ki ma fiya jẹ wọn tabi parọ wọn lẹyin ti wọn ba se asise, n ko ni ni agbabọọlu mọ ti yoo ni oun fẹ gba bọọlu nitori pe gbogbo agbabọọlu lo ma ṣe asise.,
"A gba pe awọn ololufẹ wa gbọdọ sọrọ, ko ki n ṣe nnkan to buru..
"Emi, Uzoho ati awọn agbabọọlu yooku mọ eyi. Ẹ tọ mi ni lati ma jẹ ki irẹwẹsi ọkan ba awọn agbabọọlu mi.
Akọnimọgba ọmọ orilẹede Portugal lo ni amule mẹta ọtọtọ ni ikọ awọn agbabọọlu sugbọn o kọ lati ti fun amule miiran ni anfani lẹyin asise Uzoho ni ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Saudi Arabia, to si gba ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Mozambique.
"Isoro kan ti mo ni pélu Uzoho ni ti ko ba tẹti gbọ ohun ti mo n sọ.
"Bi wọn ṣe n bu ẹnu atẹlu wa jẹ nnkan to dara, to si tun la oju wa si bi o ṣe yẹ ki nnkan lọ. Sugbọn mo mọ pe, lorilẹede Naijiria, amule ni awọn eeyan maa n bu ẹnu atẹlu.
"Fun emi, Asise kan ni Uzoho ti ṣe bayii."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Erongba ife ẹyẹ agbaye
Ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ to waye ninu oṣu kẹwaa ni lati gbaradi fun ipele lati le koja ninu idije ife ẹyẹ agbaye ti ọdun 2026 ni yoo bẹrẹ ninu oṣu kọkanla.
Ikọ Nigeria yoo bẹrẹ igbaradi naa pẹlu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu ikọ orilẹede Lesotho ni ile ati Zimbabawe.
Paseiro, ẹni to sisẹ pẹlu awọn ikọ agbabọọlu bi Saudi Arabia ati Venezuela, ni ireti lati lati lewaju ikọ Super Eagles lọ idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye ni Ariwa Amẹrika.
To si ni inu oun dun pupọ si ilọsiwaju ti oun ti ṣe.
"Afojusun meji ni a ni fun ikọ yii, ọkan ni lati pese ayika to dara. Ikeji ni lati gbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Lesotho ati Zimbabwe.
"A gba ayo to dara pẹlu Saudi Arabia , ti a si fi han wọn pe a koju oṣuwọn.
"Pẹlu Zimbabwe, mo fẹran ipele akọkọ. Ipele keji ni n ko fẹran. Awọn agbabọọlu ti simi sinu, ti wọn ko si jafafa, eyi to fun awọn alatako ni anfani lati wọle si wọn lara.
"Mo nifẹ lati ṣe igbaradi si, ka tun gba ifẹsẹwọnsẹ bi kan tabi meji si sugbọn ko ṣeeṣe.
"Nigba ti mo tọwọ bọ iwe, ohun ti mo ni lọkan ni lati gbe Super Eagles lọ si idije ife ẹyẹ agbaye , ka si tun gba idijẹ ti ilẹ adulawọ.
"A gbọdọ fiya jẹ Lesotho ati Zimbabwe sugbọn ko le ba irọnu de.
"Tẹlẹ ni alafo wa laarin awọn ikọ agbabọọlu yii sugbọn bayi ọrọ ko ri bẹ mọ."
Ireti wa pe ikọ Nigeria yoo gba ami to yẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ mejeeji naa lai ro boya amule kan lo wa loju ile.
Amule to n gba bọọlu rẹ ni Israel, Adebayo Adeleye lo mu ile fun Ikọ Super Eagles to bori ikọ Sierra Leone ninu oṣu kẹfa.
O wa lara ikọ fun Saudi Arabia ati Mozambique sugbọn ko ti ni anfani lati kopa ni ọna to fẹ.
Maduka Okoye, amule akọkọ ọdun 2021 ninu idije ilẹ adulawọ to waye ni Cameroon ni wọn sọrọ buruku si, ti wọn si ti ni anfani lati ri ogo rẹ gba pada lati bi oṣu mejidinlogun ṣeyin.
Amule Chippa, Stanley Nwabali ni ọpọ ti n na wọ si pe ki wọn fun ni anfani.
Bakan naa ni irẹwẹsi ọkan ba Paseiro lori ilera Victor Osimhen ati Samuel Chukwueze.
Awọn mejeeji farapa nioni ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Saudi Arabia, to si ṣeeṣe ki wọn ma ni anfani lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ gbaradi fun idije ife ẹyẹ agbaye losu to n bọ.
"A fẹ ki ajinde ara ba gbogbo awọn agbabọọlu wa.
"Sugbọn mo ni lati sọ pe atunṣe ti wa ninu ikọ yii. Mo mọ awọn agbabọọlu mi daada, ti a si ni eeyan to le gba aye meji si mẹta,"

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alatako to lewu ni AFCON
Anfani to le jẹ ki Paseiro lewaju ikọ Super Eagles lọ idije ife ẹyẹ agbaye lo da lori bo ba ṣeeṣe ninu idije ilẹ Adulawọ ti yoo waye lọdun to n bọ.
Ẹni ọdun mẹtalọgọta lo ni adehun pẹlu Naijiria ti wọ ipari idije AFCON.
Ohun ti ọpọ gbagbọ ni pe aṣeyọri ninu idije AFCON nikan lo le fun Paseiro ni anfani lati wa pẹlu ikọ naa titi wọ inu oṣu kẹji ọdun to n bọ.
Isọri kini pẹlu orilẹede to n gba alejo idije naa ni Ikó Sper Eagles, Equatoria Guinea ati Guinea Bissau to fiya jẹ ikọ Paseiro ni ami ayo sodo niluu Abuja wa.
"To ba fẹ ṣe aṣeyọri ninu idije yii, o ni lati tẹwọ gba ibi ti wọn pin ẹ si. Awọn alatako dara pupọ, ti wọn si tun buru.
"A koju oṣuwọn ju Guinea-Bissau sugbọn mo ranti pe wọn fiya jẹ ni ile wa, fun idi eyi, a ni lati gbaradi fun awọn alatako yii."












