N kò le gbàgbé ọ̀rọ̀ méjì tí Baba Suwe sọ sí mi láéláé, wọ́n sì ń dún lọ́kàn mi - Yomi Fabiyi

Aworan Yomi Fabiyi ati Oloogbe Baba Suwe

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi

Gbajugbaja oṣere tiata, Yomi Fabiyi ti ṣe daro iranti iku gbajugbaja oṣere tiata to di oloogbe, Babatunde Omidan ti ọpọ mọ si Baba Suwe, ẹni to jade laye lọdun meji sẹyin.

Ọjọ kejilelogun, oṣu kọkanla ọdun 2021 ni Baba Suwe, tii se gbajumọ oṣere ati adẹrinposonu dagbere faye lẹyin to se aisan ọlọjọ pipẹ.

Ọdun mẹtalelọgọta ni oloogbe agba osere naa lo loke eepe, ko to tẹri gbasọ.

Ninu ọrọ rẹ, Yomi Fabiyi ni ọrọ meji ti Baba Suwe sọ si oun si n dun sibẹ ninu ọpọlọ oun titi di asiko yii.

"Baba Suwe bọ mi, o gba mi sile, to si ṣe mi gẹgẹ bi ọmọ, to si ra iyi akọkọ fun mi laye"

Nigba to n salaye awn ọrọ meji naa, Yomi Fabiyi ni Baba Suwe sọ fun oun pe o wu oun ko jẹ pe oun ni Baba to bi Yomi Fabiyi lọmọ.

“Ọrọ ti Baba Suwe sọ fun mi gbẹyin si n dun lori mi.

O ni ’Yomi o ṣeun mi, o ṣeun mi. To ba jẹ pe mo le beere lọwọ Ọlọrun pe ko sọ mi di Baba rẹ, o wu mi pe emi ni mo bi ẹ’,

“O wu mi pe ki o ko ba mi laye nigba to ba pada de.

Sugbọn maa tẹsiwaju lati ma ja fun Baba Ijesha, wọn ko mọ pe o ko fẹran iyanjẹ.

Mo ri gbogbo nnkan to n lọ, fi Tampan silẹ, ma ba wọn ja .”

Yomi Fabiyi tẹsiwaju pe oun ko le gbagbe gbogbo iranlọwọ ti Baba Suwe ṣe fun oun ati bi o se mu oun wọ agbo ere tiata lati bẹrẹ isẹ.

“Baba Suwe bọ mi, o gba mi sile, to si ṣe mi gẹgẹ bi ọmọ ati awọn nnkan mii to dara.

“O ra ohun iyi akọkọ fun mi ni igbesi aye mi.

“Lai wo gbogbo itan nipa irinajo wa to waye laarin ọga ati ọmọ isẹ, titi ayeraye ni mo ma fi ma dupẹ, ti maa si bọwọ fun Baba Suwe.

“Agbaọjẹ ni Baba Suwe, to si jẹ ọkan ninu ohun alumọni orilẹede Naijiria.”

Ta ni Babatunde Omidina, Baba Suwe?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Adẹrinposonu tabi alawada nla ni Babatunde Omidina, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Suwe nigba aye rẹ.

Ọjọ kejilelogun osu kẹjọ ọdun 1958 lo dele aye, ti ko ba si pe ẹni ọdun mẹrinlelọgọta loke eepẹ ọdun 2023 yii.

Ọdun 1971 lo bẹrẹ si ni kopa ninu ere tiata amọ ọdun 1997 ni okiki rẹ wa to kan lati ipasẹ awọn sinima kan to kopa ninu wọn.

Lara awọn sinima to gbe Baba Suwa han faraye ni Baba Jayejaye, Oluweri Magboojo, Ba o ku, Oju Oloju, Baba Londoner, Ko tan si be, Aso Ibora, Obelomo, Elebolo, Larinloodu ati Omo Lasan.

Baba Suwe maa n kopa ninu ere tiata pẹlu ọkan lara awọn aya rẹ, to n jẹ Moladun lagbo tiata.

Amọ iji aye de ba lọdun 2001, nigba ti ajọ to n dena gbigbe oogun oloro ni Naijiria, NDLEA mu pe o gbe eroja Cocaine.

Ọrọ naa dele ẹjọ amọ ti adajọ da Baba Suwe lare pe ko jẹbi ẹsun naa nitori NDLEA ko ri ẹri kankan fi silẹ.

Sugbọn lati akoko naa ni Alawada naa ti bẹrẹ aisan nitori o ni wọn ki awọn irin kan bọ oun nidi ati ninu pẹlu ipa, pe ki oun le ya awọn idi oogun oloro jade.

Bi o tilẹ jẹ pe o du ẹmi rẹ amọ aisan lo se wo, a ko ri ti ọlọjọ se.

Babatunde Omidina dagbere faye nile iwosan kan nilu Ikorodu, nipinlẹ Eko to n gbe ni ọjọ kejilelogun osu Kọkanla ọdun 2021.