PrimeBoy, ọ̀rẹ́ Mohbad ni mo fura sí pé ó pa ẹ̀gbọ́n mi - Àbúrò olóògbé sọ fúnlé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Mohbad Imole
Ẹjọ nipa iku agbajugbaja olorin takasufe to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad tun ti gba ọna miiran yọ nigba ti aburo rẹ, Adura Aloba farahan ni ileẹjọ lati sọ ohun to mọ nipa iku ẹgbọn rẹ.
Ọjọru, ọjọ kẹtalelogun ọdun 2023 ni Adura Aloba to jẹ aburo Mohbad yọju si ileẹjọ, to si salaye bi irinajo iku ẹgbọn rẹ ṣe waye.
O ni ti wọn ba ni ki oun tọka si ẹnikan to mọ nipa iku ẹgbọn oun, oun yoo tọka si ọrẹ rẹ, Ibrahim Owodunni, ti ọpọ mọ si PrimeBoy.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ karun un oṣu kẹwaa ni PrimeBoy juwọ ara rẹ lẹ fun Ileeṣẹ Ọlọpaa lẹyin ti wọn kede pe awọn yoo fun ẹnikẹni to ba ri ni milọnu kan naira.
Primeboy ti wa ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa lati oṣu to kọja.
"N ko si nibẹ lasiko ti Mohbad ati PrimeBoy ja, Wummi lo sọ ohun to waye fun mi"
Ninu alaye rẹ, Adura Aloba, ẹni ogun ọdun ni, oun ko si nibẹ nigba ti Mohbad ati Primeboy ja.
Sugbọn o ni pẹlu nnkan ti Wunmi, to jẹ iyawo ẹgbọn rẹ sọ fun oun nipa isẹlẹ naa, o jẹ ki oun gbagbọ pe PrimeBoy mọ nipa iku ẹgbọn oun.
“N ko si nibẹ lasiko ti Mohbad ati PrimeBoy wọ iya ija. Wummi lo pada sọ ohun to waye fun mi pe wọn ja.
“Ti n ba ni ki tọka si ẹnikan to mọ nipa iku ẹgbọn mi, maa ni PrimeBoy ni.
Pẹlu bi n ko ṣe si nibẹ lasiko ti wọn ja, Wummi salaye gbogbo ohun to waye fun mi, mo si gbagbọ.”
"Otitọ ni pe Mohbad ati Wummi ma n ja sugbọn..."
Adura Aloba ninu alaye fun ileẹjọ ni Mohbad ati Wummi ma n ja ninu ile wọn sugbọn wọn ma n pari rẹ.
O ni oun gbe papọ pẹlu ẹgbọn oun ninu ile kana, to si tun fidi rẹ mulẹ pe tọkọtaya naa ja saaju ki wọn to lọ si Ikorodu nibi ti ija ti waye laarin Mohbad ati Primeboy.
“Nigba ti a de lati ikorodu, mo wa si isalẹ, ti awọn yooku si gba oke lọ. Nigba to ya mo gbera lati lọ fun Mohbad ni foonu rẹ, mo gbọ iro ija laarin Wummi ati ẹgbọn mi nipa irinajo wọn lọ si orilẹede Canada.
“Saaju ki nọọsi to de si ile, alaafia ni ẹgbọn mi wa sugbọn mo ri ẹjẹ ni bi apa rẹ.
“Emi ni mo ṣe ounjẹ ‘Noodles’ ti gbogbo wa jẹ pẹlu Mohbad lọjọ naa. Nigba ti nọọsi de, emi ati Wummi wa ni ile idana, ti a n ṣe irẹsi, ti nọọsi si wa pẹlu Mohbad loke.
"Irọ ni pe ẹgbọn mi ni arun ọpọlọ"
Adura Aloba tun fidi rẹ mulẹ pe ko si nnkan to jọ mọ pe Mohbad ni aarun ọpọlọ lẹyin ohun to waye pẹlu ajọ NDLEA.
“Nipa iroyin kan to ni ẹgbọn mi ni aarun ọpọlọ lẹyin ohun to waye pẹlu ajọ NDLEA, irọ lasan ni.
“Ko fi igba kankan ni aarun ọpọlọ. Primeboy lo pa ẹgbọn mi".
Ìwádìí ohun tó ṣokùnfà ikú Mohbad ṣì ń lọ lọ́wọ́ l’Amẹrika - ilé-ẹjọ́
Ile ẹjọ to wa ni Ikorodu nipinlẹ Eko to n ṣe iwadii ohun to ṣe okunfa iku olorin takasufee, Ilerioluwa Aloba, ti ọpọ mọ si Mohbad ti sọ pe ayẹwo si n lọ lọwọ lori oku akọrin naa lorilẹede Amẹrika.
Agbẹjọro to n ṣoju ipinlẹ Eko, O. Akinde lo fidi ọrọ yii mulẹ nibi ijokoo ile ẹjọ ọhun ni Ọjọru.
Akinde sọ fun adajọ majisireeti Adetayo Shotobi pe ayẹwo ara oku Mohbad ti pari.
Amọ, ayẹwo inu rẹ tawọn oloyinbo n pe ni ‘’ toxicology test’’ lo n lọ lọwọ bayii lorilẹede Amẹrika.
Akinde sọrọ yii lẹyin ti agbẹjọro baba oloogbe naa, David Fadimu beere ohun to n da esi ayẹwo oku Mohbad duro gan an.
Ẹwẹ, majisireeti Shotobi beere idi ti ti wọn ko fi ṣe ayẹwo yii lorilẹede Naijiria to fi jẹ pe oke okun ni wọn ti lọ ṣe e.
Ni ọjọ Iṣẹgun ni arabinrin Olumiyi ti i ṣe iya Mohabdti ọpọ mọ si Mohbad ke gbajare pe wọn ti jọwọ oku Mohbad fun sinsin ṣugbọn baba rẹ, Ọgbẹni Joseph Aloba ni ko jẹ ki wọn tii sin Mohbad di akoko yii.
Arabinrin Olumiyi fọrọ yii lede ninu fidio kan to ṣe eleyii to wa kaakiri ori ayelujara lọjọ Iṣẹgun.
Arabinrin naa kepe awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn bẹ baba Mohbad lati lọ gba oku ọdọmọde akọrin naa lati ọdọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko ki wọn le sin in.
Iya Mohbad sọ ninu fidio naa pe lati igba ti wọn ti pari ayẹwo oku Mohbad ni ẹbi rẹ ti lanfaani lati gbe oku rẹ fun sinsin.
‘’Ọmọ Naijiria, ẹ jọwọ ẹ bami gba oku ọmọ mi, mo gbadura pe ẹ ko ni ri iku ọmọ.
Baba Mohbad ni ko tii jẹ ki a sin in, bi tilẹ jẹ pe mo ti bẹ ẹ ni aimọye igba.
Koda mo ti lọ ba kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Eko lọsẹ to kọja, o sọ fun mi pe awọn ti jọwọ oku Mohbad.
Ọga ọlọpaa beere lọwọ mi pe kilode ti n ṣe n fi oku Mohbad rare,’’ iya Mohbad ṣalaye.
Bakan naa ni Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko ti ní àwọn kò ì tíì rí èsì àyẹ̀wò òkú Mohbad gbà láti oṣù méjì tí wọ́n ti ṣàyẹ̀wò náà.















