"Lẹ́yìn oṣù díẹ̀ tí mo ṣe ìgbeyàwó ni mo bẹ̀rẹ̀ sí tọ̀ sílé pada"

Aworan ẹni to tọ si ṣokoto

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Isidore Kouwonou
    • Role, BBC Afrique
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Bo jẹ laarin awọn ọmọde, eeyan le maa sọrọ nipa titọọle.

Amọ bawo ni ka ti gbọ pe agbalagba, ẹni ọgbọn ọdun n yami lu ibusun rẹ lalẹ to ba sun tan?

Bi o ba waye bẹẹ, eyi ti di aisan tawọn onimọ iṣegun oyinbo n pe ni Enuresis.

Pupọ awọn ti aisan yi n ba finra lo maa n tiju lati sọrọ nipa rẹ.

Koda, wọn kii fẹ sọ fun akọsẹmọsẹ ti yoo bẹrẹ si ni wa ọna abayọ fun wọn, bẹẹ ni wọn ko si ni fẹ lati bun ẹni kankan gbọ.

Amọ ṣa Enuresis kii ṣe aisan ti eeyan le daṣọ bo tawọn eeyan ko ni mọ.

Linus, onimọ ẹrọ kọmputa ẹni ọdun mẹrinlelogoji ni Cotonou, ta a ba sọrọ sọ pe, ''Oju maa n ti mi lati maa wo iyawo mi to ba ti n fọ aṣọ ti mo tọ si mọjumọ.

O maa n ba mi lọkan jẹ“

Àwọn ìròyìn míràn tí ẹ tún lè kà:

Ki lo n jẹ Enuresis?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Enuresis ni iwa aile pa itọ mọdi to maa n waye lasiko ti eeyan ba n sun lọwọ.

Eleyi jẹ aiṣedeede ti ko ni jẹ ki eeyan le dari aboonu.

Linus sọ pe ''ohun to buru nibẹ ni pe lọsan gangan nigba mii, mi o ni ikapa lori bi itọ ṣe n jade lara mi''

O ni eyi ti ṣe akoba fun iṣẹ toun n ṣe nitori aile fi ọkan maa ba iṣẹ lọ tori pe oun yoo maa bẹru kawọn akẹgbẹ rẹ ma mọ nkan to n ṣẹlẹ si.

Tori eyi, o ni ile loun maa n joko si lati ṣe iṣẹ.

Lori foonu taa ti jijọ sọrọ, arakunrin yi n fi tipa ribi ṣalaye fun BBC bi aisan yi ko ṣe jẹ ko lọ ibiṣẹ bo ẹ yẹ lati le fi ṣiṣẹ rẹ.

''O ku diẹ ko ba ṣe akoba fun ajọsepọ laarin emi ati iyawo mi ṣugbọn o jẹ eeyan to gba mi bi mo ṣe ri.''

O ni oore nla leyi jẹ fun awọn tori aimọye tọkọtayalo ti pinya tori iru nkan bayii.

O ni ohun ko tiẹ ro pe iru aisan bayii yoo ba oun finra.

O loun ko ti tọọ le mọ lati igba toun wa lọmọ ọdun mẹta.

“Mo bẹrẹ si ni tọọle pada paapa lalẹ lẹyin oṣu diẹ ti mo ṣe igbeyawo.

Mi o le ṣalaye ohun to wa nidi rẹ''

Amọ dokita rẹ sọ fun pe idamu lẹnu iṣẹ lo fa a.Tori pe aboonu rẹ ko ni idiwọ kankan.

Ki eeyan maa tọọle loogun

Oríṣun àwòrán, JEEP5D VIA GETTY IMAGES

Awọn nkan to le ṣokunfa Enuresis

Awọn nkan taa le fojuri ati eleyi to n ba ọkan finra le ṣkunfa rẹ lara awọn agbalagba.

Aisan itọ ṣuga tabi kokoro to n koju ile itọ naa le ṣokunfa rẹ gẹgẹ bi dokita Anne Marie Gaoussou ti ṣe sọ fun wa ni Cotonou.

Awọn onimọ si tun s pe o o maa n ṣeṣi waye ki eeyan tọ sara.

Bi eeyan ba mọti yo,ko maa ṣe iranran tabi ko maa fa siga le fa aisan yi.

Amọ gẹgẹ bi onimọ yi ṣe sọ, ailemu itọ duro lara yi le waye latari wahala pupọ lori ẹmi,iporuru ọkan ibẹru tabi awọn iṣesi miran an.

''Ni ti temi, igba kigba ti mo ba koju awọn ero lati ba wọn sọrọ lo maa n ṣẹlẹ si mi.''

Alaye ree ti arakunrin yi ti ko ni akọsilẹ aisan naa mu wa lati le sọ ohun to n fa titọ sara fun un.

Awọn onimọ si tun s pe aisan Nocturnal polyuria le ṣe okunfa ki eeyan maa tọọle nitori pe onitọhun le maa tọ lọpọ igba laarin oru.

"Ko jẹ ki n le maa ṣe faaji kankan"

Awọn ti Enuresis n da laamu kii le ba ẹnikankan sọrọ nipa ohun to n ṣe wọn.

Iru oju tawọn eeyan ma fi n wo wọn jẹ ki ọpọ yago fun awọn eeyan lawujọ ni paapa awọn to sunmọ wọn.

Onimọ nipa aisan yi sọ pe ''a ti gbiyanju lọpọ igba lati pari ọrọ fawọn lọkọlaya ti ọkan ninu wọn ba n koju aisan yi.Lọpọ igabigbeyawo wn maa n pada tuka ni.''

O ni itọju to peye wa ti yoo wo aisan yi san lara eeyan.

Linus ni ẹru ko ba oun nipa igbeyawo rẹ tori pe iyawo oun jẹ ẹni ti ọrọ ye daada to si ni ifarada.

O loun ko tiẹ mọ ohun ti o yẹ koun s pẹlu iru ṣuuru ti arabinrin naa ni pẹlu gbogbo ipenija tawọn n koju.''Ohun lo n gbami ni iyanju lati bọwọ fun itọju tawọn dokita ni ki n maa tẹle''

Yatọ si ko gba ere bọọlu ori ọdan taa mọ si Tennis pẹlu ibatan rẹ to fọkan tan, Linus kii lọ ju ile ati ibiṣẹ rẹ lọ.

O ni boun ba fẹ rin irinajo, pampers agbalagba loun maa n de mọ idi ki o ma ba doju ti oun.

Ati pe o loun kii saba rinrinajo.

Lara ọna abayo lo sọ pe oun a maa ji tọ loru loore koore ṣugbọn eyi ko jẹ ko gbadun orun daada.

Linus ko gba ka ba iyawo rẹ sọrọ.

O ni''ko ni gba lati ba yin sọrọ''

Amọ o loun nigbagbọ pe gbogbo nkan naa ni yoo pada wa di itan.''Mo lero pe maa lanfaani lati gbadun aye mi daada lẹyin ta ba pari itọju taa n ṣe''

Aworan afihan ẹni to n tọ sara

Oríṣun àwòrán, GETTY IMAGES

N jẹ Enuresis se tọju lara agbalagba?

Awọn onimọ sọ pe ko si itọju iyanu lori aisan yi.

Bi kii ṣe pe ki eeyan mojuto itọju ara.

Wọn ni eeyan gbọdọ mu omi to bojumu ko si ṣọra fun amuju nkan olomi.

Bẹẹ lo ni ki a yago fun coffee mimu ati awọn ọti ẹlẹrindodo.

O ni awọn nkan wọnyi a maa ṣokunfa inira fun aboonu to le mu ki eeyan maa tọọle.

Linus sọ pe ''ko rọrun lati ko ara ẹni ni ijanu nipa awọn nkan to mọ ọ lara''

Ninu itọju aisan yii, o tun yẹ ka fi ọkan si ji dide lati tọ ti awọn dokita a maa gba alaisan lamọran rẹ.

O leyi ṣe pataki ni paapa asiko ti wn ba kẹfin pe itọ ti n bọ si awn lara.

Bẹẹ naa ni dokita le kọ oogun desmopressin ti awọn igbiyanju ara to daba ṣaaju yi ko ba fẹ ṣiṣẹ.

Oogun yi a maa da itọ duro lalẹ ṣugbọn o le ma ṣiṣẹ daada bi ki eeyan maa ji tọfun ara rẹ nitori ti apọju lilo oogun yi ko ba mu ko ṣiṣẹ mọ.

Ẹwẹ awọn onimọ mii parọwa lilo ọna mejeeji yi lati le fi koju aisan titọọle.