Ṣé òfin Nàíjírìà dá ìgbéyàwó rẹ mọ̀? Bí o ṣe lè mọ àrídájú rẹ̀ nìyí

Oríṣun àwòrán, Getty image
Isopọ laarin ololufẹ meji ti wọn ti gba lati fẹ ara wọn, ti wọn si tẹle ilana to yẹ lati di ọkan ṣoṣo la n pe ni igbeyawo.
Lorilẹ-ede Naijiria yii, ko si Satide kan ti igbeyawo ki i waye, awọn mi-in naa a si maa mu ọjọ to wu wọn laarin ọsẹ.
Ṣugbọn ọpọ ọmọ Naijiria lo n ṣegbeyawo to jẹ pe igbeyawo naa ko lẹsẹ nilẹ, nitori ọna ti wọn n gba ṣe e ti ko ba ofin ilẹ yii mu.
Ni Naijiria, awọn ẹlomi-in n ṣegbeyawo oriṣi mẹta: Ti ibilẹ, ti ilana ẹsin Kristẹni abi ti Islam ati ti kootu ijọba.
Ṣugbọn ṣiṣe gbogbo eyi kọ lo ṣe pataki, bi ko ṣe keeyan le fọwọ sọya pe ilana to ba ofin Naijiria mu loun fi gbe iyawo silẹ, tabi ti oun fi lọkọ.
Awọn pasitọ kan tiẹ maa n fọwọ sọya pe awọn le so tọkọ-taya nikan pọ bi wọn ko ba fẹ ki awọn ẹlomi-in wa nibi eto naa.
Ṣe eyi tọna bi?
Ohun to buru ni pe keeyan ti pari gbogbo eto, ko si ti ro pe oun ti ṣegbeyawo, ko waa pada ri i pe ofege ni igbeyawo naa labẹ ofin.
Eyi lo fi yẹ ki o mọ awọn nnkan wọnyi ti ko ye awọn eeyan nipa igbeyawo lorilẹ-ede Naijiria.
Irú ìgbeyàwó wó ni òfin fọwọ́ sí?

Oríṣun àwòrán, Getty image
Meji ni igbeyawo ti ofin fọwọ si ni Naijiria, awọn naa ni:
Igbeyawo nilana ibilẹ ati nilana kootu:
Igbeyawo nilana ibilẹ ni oloyinbo n pe ni Customary marriage.
Ilana ibilẹ ilu ti ọkọ ati iyawo ti wa ni wọn maa n tẹle lati ṣe iru igbeyawo yii.
Bakan naa ni wọn tun maa n tẹle ilana idile ti ẹbi ọkọ ati iyawo ti wa.
Labẹ iru igbeyawo yii ni wọn ti maa n gba owo ori iyawo lọwọ ọkọ, ti awọn ẹbi ọkọ yoo si tun ko ọpọlọpọ nnkan idana wa bi ẹbi iyawo ba ṣe beere si.
Owo ori iyawo sisan ko ri bakan naa kaakiri ilẹ yii, o maa n pọ ju ara wọn lọ.
Bẹẹ ni awọn idile mi-in si wa ti wọn ki i gba owo yii rara.
Wọn aa ni awọn o ta ọmọ awọn.
Kí ni yóò jẹ́ kí ìgbeyàwó rẹ nílànà ìbílẹ̀ bá òfin Nàíjírìà mu?
Ki iyawo gba lati fẹ ọkọ, ki ọkọ naa gba lati fẹ iyawo lai si ipá nibẹ (Consent), ni nnkan akọkọ ti yoo mu igbeyawo nilana ibilẹ ba ofin mu.
Awọn obi tabi alagbatọ iyawo gbọdọ yọnda tọkan-tọkan pe ki ọmọ awọn fẹ ọkunrin naa ki igbeyawo too waye.
Bi o ba jẹ pe awọn obi tabi alagbatọ iyawo to wa nile rẹ ko fọwọ si ajọṣepọ yin, ohun ti ko ba ofin mu lo ṣe, igbeyawo kọ.
Bi o ba ṣegbeyawo lai si pe iyawo gba lati fẹ ọkọ, tabi ọkọ gba lati fẹ iyawo. Ti awọn obi ati abi alagbatọ naa ko si fọwọ si i, kootu ibilẹ laṣẹ lati tu igbeyawo bẹẹ ka.
Owó orí ìyàwó: Gẹgẹ bii ọkunrin, ko sọgbọn ki o ma san owo ori iyawo ki igbeyawo too waye. Afi to ba wu ẹbi iyawo lati fi ṣaanu rẹ lo ku.
Dandan lowo ori ti Yoruba maa n wi wa ni ibamu pẹlu igbeyawo naa, gẹgẹ bo ṣe jẹ dandan lati sanwo ori fun ijọba pẹlu.
Bi igbeyawo rẹ nilana ibilẹ yoo ba tẹle ofin Naijiria, dandan ni ki o san owo ori fun ẹbi iyawo.
Bakan naa lo si gbọdọ tẹle iwe ti wọn ba fi beere ohun ti wọn fẹẹ gba gẹgẹ bii nnkan iyawo, ki o too gbe ọmọ wọn kuro lọọdẹ wọn.
Ẹ si tun gbọdọ jẹ ọmọ orilẹ-ede Naijiria.
Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹbí kan náà:
Iwa ọdaran gbaa ni labẹ ofin lati fẹ ẹni ti ẹ jọ jẹ ẹbi kan naa, ẹni ti ẹ jọ jẹ ẹjẹ kan naa.
Koda, eewọ gidi ni lati ni ajọṣepọ takọ-tabo pẹlu ẹni ti ẹ jọ jẹ ẹbi. A ko si gbọdọ dabaa pe a fẹẹ fẹ wọn.
Bi iru igbeyawo bẹẹ ba waye, ko ba ofin mu labẹ igbeyawo ilana ibilẹ lorilẹ-ede Naijiria.
O ko le fẹ aburo rẹ obinrin, ọkunrin, ọmọ ẹgbọn, ọmọ aburo rẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ to ba ba ọ tan.
2) Ìgbeyàwó nílànà kóòtù

Oríṣun àwòrán, Getty image
Oriṣi igbeyawo keji ti ofin Naijiria fọwọ si ni igbeyawo nilana kootu (Registry marriage).
Iru igbeyawo yii naa ni wọn tun n pe ni Marriage under the Act. Iyẹn ni pe igbeyawo ofin ta a ṣe labala igbeyawo to wa ninu kootu ijọba.
Abi ni ibudo ti ofin fọwọ si pe iru rẹ le waye.
Awọn mi-in n ṣegbeyawo iru eyi ni ṣọọṣi, wọn yoo si pe e nigbeyawo labẹ ofin.
Ṣugbọn ohun to rọ mọ iru igbeyawo yii pọ, ka too le gba pe labẹ ofin ni ẹnikan ti ṣeyawo.
O le maa ya ọ lẹnu, pe ki lo wa de tawọn eeyan maa n sare lọ si Rẹjisiiri Ikoyi, Abuja ati awọn mi-in ti wọn gbajumọ, ṣebi fun asopọ lọna ofin naa ni.
O ju bẹẹ lọ.
Awọn nnkan kan wa to o gbọdọ ṣe ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ abẹle lorilẹ-ede yii (Federal Ministry of Interior) yoo fi gba igbeyawo rẹ wọle bii eyi ti wọn ṣe labẹ ofin.
Bí ìgbeyàwó rẹ yóò ṣe bá òfin mu
Igbesẹ akọkọ labẹ ilana yii ni lati kọkọ fi igbeyawo naa to alakooso eto igbeyawo nijọba ibilẹ ti eto naa yoo ti waye leti.
Si jẹ ko ye ọ, pe ijọba ibilẹ kan ko ga ju ọkan lọ. Fun idi eyi, ma ṣe jẹ ki ẹnikéni ko ọ si wahala pe rẹjisiiri kan nijọba fówọ si.
Aparo kan ko ga jukan lọ to ba jẹ ti ijọba ibilẹ.
Bi ofin ilana igbeyawo yii ṣe wi, ọkan ninu ọkọ tabi iyawo yoo buwọ luwe, yoo si fun alakooso agbegbe ti igbeyawo naa yoo ti waye.
Wọn yoo waa kede igbeyawo naa si oju patako nibẹ fun ọjọ mọkanlelogun, ki gbogbo oju ri i.
Ki ẹnikẹni to ba si ni idi kan ti igbeyawo naa ko fi gbọdọ waye le jade waa sọ tẹnu rẹ kọjọ too pe.
Bi ẹnikẹni ko ba tako igbeyawo naa, alakooso yoo waa fun tọkọ-taya ti wọn fẹẹ ṣegbeyawo ọhun ni iwe-ẹri.
Ó yẹ kí ọ mọ àwọn nǹkan wọ̀nyí náà fún ìgbeyàwó kóòtù
Ọkan ninu ọkọ ati iyawo, gbọdọ maa gbe lagbegbe ti igbeyawo naa ti fẹẹ waye. O kere tan, fun ọjọ mẹẹẹdogun ki igbeyawo too waye.
Awọn ti wọn fẹẹ fẹra wọn yii gbọdọ ti pe ẹni ọdun mọkanlelogun (21 years).
Bi ọkan ninu wọn ko ba ti i to ọjọ ori yii, yoo ni lati gba iyọnda, wọn ko si gbọdọ jẹ opobinrin, abi ọkunrin ti iyawo rẹ ti ku.
Awọn ti wọn fẹẹ fẹra yii ko gbọdọ ti ṣe igbeyawo pẹlu ẹnikan ri labẹ ilana igbeyawo ibilẹ. Afi ẹni to fẹẹ fẹ nilana ofin yii nikan.
Bi wọn ba ti kogo awọn nnkan oke yii ja tan, awọn ololufẹ meji naa yoo bura niwaju alakooso eto igbeyawo, oṣiṣẹ kootu naa tabi olori ẹsin tawọn eeyan mọ fun eto yii lati so wọn pọ.
Eyi le waye nibudo ijọsin ti wọn ba fun laṣẹ iru ẹ labẹ ilana igbeyawo kootu. Iyẹn ibudo ijọsin to lorukọ lọdọ ijọba.
Akiyesi: Ranti pe ki i ṣe gbogbo ṣọọṣi tabi mọṣalaaṣi ni wọn forukọ silẹ lọdọ ijọba o.
Awọn ti wọn ba forukọsilẹ nikan ni wọn ni aṣẹ yii.
Kí ni yóò jẹ́ kí ìgbeyàwó tí o ṣe ní ṣọ́ọ́ṣì lẹ́sẹ̀ nilẹ̀ lábẹ́ òfin ?
Gẹgẹ bi ofin igbeyawo (22-25) ṣe sọ, o le ṣe igbeyawo nile ijọsin to ba lorukọ lọdọ ijọba. Alufaa ileejọsin naa tawọn eeyan mọ daadaa ni yoo si ṣakooso rẹ.
O ṣe pataki lati mọ pe wọn yoo ṣeto igbeyawo naa nilana igbeyawo ti wọn ba n lo nile ijọsin ọhun, yoo si jẹ ile ijọsin ti wọn ti fun laṣẹ igbeyawo nilana ofin.
Yoo waye laarin aago mẹjọ aarọ si mẹfa irọlẹ, yoo si ṣoju ẹlẹrii meji tabi ju bẹẹ lọ, yatọ si adari ẹsin ti yoo dari igbeyawo naa.
Ẹni to fẹẹ so wọn pọ ko ni i le ṣe bẹẹ bi wahala kan ba wa, tabi bi tọkọ-taya ko ba ri iwe-ẹri mu kalẹ.
Alakooso ati ẹni to fẹẹ so wọn pọ yoo ni ẹda iwe-ẹri igbeyawo naa lọwọ pẹlu, wọn yoo si tọju rẹ.
Iyẹn lẹyin ti tọkọ-taya ba ti buwọ luwe naa tan.
Lẹyin ayẹyẹ, ẹni to so wọn pọ yoo ṣe ẹda iwe-ẹri igbeyawo naa pẹlu alaye nipa tọkọ-taya yii.
Orukọ wọn, ọjọ ti wọn ṣegbeyawo, orukọ awọn ẹlẹrii, yoo si fi i ranṣẹ si ẹka to yẹ.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ to n ri si ọrọ abẹnu ni Naijiria ṣe wi, labẹ ofin, ileejọsin to ba fẹẹ ṣegbeyawo nilana ofin gbọdọ gba iwe aṣẹ rẹ.
Ọdun marun-un ni wọn yoo fi lo iwe aṣẹ akọkọ, wọn yoo si maa ṣe isọdọtun rẹ (renewal) lẹyin ọdun mẹta-mẹta.
Bi iwọ ba tẹle gbogbo ilana yii ki o too ṣegbeyawo, igbeyawo rẹ tọna labẹ ofin Naijiria. O fẹsẹ mulẹ.
Ṣe o da ọ loju pe ileejọsin rẹ lorukọ lọdọ ijọba ṣaa?
Ṣe olori ẹsin to so yin pọ jẹ ẹni itẹwọgba?
To ba ri bakan naa. Ire o.













