Wo oríṣìí àrùn tó lágbára tí ìbínú lè dá sínú àgọ́ ara èèyàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn oluwadii nipa eto ilera ti sọ pe ibinu ni gbogbo igba le ṣokunfa arun ọkan ati rọparọsẹ.
Awọn oluwadii naa fidi rẹ múlẹ pe ti eeyan ba n binu, yatọ si pe inu ẹni naa bajẹ tabi ọkan ẹni bẹẹ poruuru, o le sakoba fun ẹjẹ ninu ara eyi to le fa arun ọkan ati rọparọsẹ.
Abọ iwadii naa ti wọn gbe jade ninu iwe iroyin ajọ ilẹ Amẹrika to n ri ọrọ ilera ọkan, AHA, sọ pe ibaṣepọ wa laarin ibinu ati arun ọkan ojiji.
Esi iwadii naa sọ pe koda ibinu diẹ gan an le ṣakoba fun ara de bi wi pe o le fa arun rọparọsẹ.
Awọn onimọ naa ṣalaye pe arun rọpárọsẹ̀ ati arun ọkan ojiji maa n ṣẹlẹ nigba ti ẹjẹ ko ba raye lọ si ọpọlọ lati inu ọkan eeyan.
Awọn ile ẹkọ to ṣe iwadii yii l'Amẹrika ni Fasiti Columbia, Ile ẹkọ iṣegun Yale, Fasiti St. John's ni ilu New York at'awọn ile ẹkọ mii.
Agbalagba ọrinlelugba ni wọn ko jọ ti wọn fi ṣe iwadii yii, wọn pin gbogbo wọn si isọri mẹrin.
Lẹyin ti wọn pin wọn si isọri yii tan ni wọn bi wọn leere pe ki wọn ranti awọn nkan to ti mi wọn binu sẹyin.
Adari iṣẹ iwadii naa, Ọjọgbọn Daichi Shimbo salaye pe iwadii ọhun fihàn pe ibinu maa n jẹ ki ẹjẹ ṣiṣẹ ṣegeṣege.
"Eleyii tumọ si pe ẹni to ba n binu ni gbogbo igba papaa jùlọ ẹni to ba ti larun lara tẹlẹ le ni arun ọkan lojiji, tabi arun to le maa gboogun mọ," Ọjọgbọn Shimbo lo sọ bẹẹ.
Awọn oluwadii yii sọ pe ti eeyan ba n binu, gbogbo homunu ara ko ni gbadun.
Awọn homunu ara yii lo maa pada ṣokunfa ẹjẹ ruru eyi to le jẹ ki eeyan maa mi gule gule.
Eyi ṣi le fa arun rọparọsẹ tabi arun ọkan ojiji.
Awọn onimọ yii sọ pe ikiyesara le ṣe iranwọ lati dẹkun ibinu ki o to fa arun buruku si eeyan lara.
Wọn tun fidi rẹ múlẹ pe oogun wa to le ran iru awọn eeyan to maa n binu bẹẹ lọwọ.













