Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Eyi ni akojọpọ awọn ohun to n ṣẹlẹ to tayo kaakiri agbaye.
Lọtẹ yii, Naijiria gba orin tuntun pẹlu bi Aarẹ Bọla Tinubu ṣe buwọlu lilo orin ti Naijiria n kọ tẹlẹ, iyẹn “Nigeria we hail thee” gẹgẹ bi orin akọmọna orilẹede Naijiria dipo “Arise O Compatriots” ti o nlo titi di Ọjọru ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun ọdun 2024.
Ero awọn ọmọ Naijiria ṣe ọtọọt lori igbesẹ yii. Bi awọn kan ṣe n sọ pe ṣe ohun to kan niyi pẹlu ebi ọpapanla to n pa araalu, lawọn miran n wi pe o ti pẹ to ti yẹ ki igbesẹ naa ti waye.
Ẹ tẹti gbọ awọn iroyin yii atawọn iroyin mi to tayọ lori “Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́” toni.


