'A ò rí oúnjẹ jẹ bíi ti àtijọ́ mọ́,' aráàlú kọminú lẹ́yìn ọdún kan tí ìjọba yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ Bola Tinubu sí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lẹ́yìn tí wọ́n búra fún-un tán gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ló ti kéde pé kò ní ìrànwọ́ tí ìjọba lórí owó bẹntiróòlù mọ́.
Ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù “subsidy” ní èdè gẹ́ẹ̀sì ni owó tí ìjọba máa ń san fún àwọn la’gbàtà tó ń gbé epo wọ Nàìjíríà láti òkè òkun láti lè jẹ́ kí wọ́n máa ta epo ní àdínkù sí iye tí wọ́n ń rà á.
Ọ̀bítíbitì owó ni ìjọba máa ń ná láti fi ṣe ìrànwọ́ yìí ní ọdọọdún tí àwọn onímọ̀ kan láti ọjọ́ pípẹ́ sì ti ní kí ìjọba da dúró.
Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn mìíràn wòye pé kò yẹ kí ìjọba yọ ìrànwọ́ yìí nítorí òhun ní àǹfàní ìjọba tí àwọn ará ìlú ń jẹ jùlọ àti pé yóò mú ìpalára bá àwọn ènìyàn tí ìjọba kò bá ṣe é mọ́.
Lẹ́yìn-ò-rẹyìn, Tinubu kéde pé kò ní sí ìrànwọ́ náà mọ́ lọ́jọ́ tí wọ́n búra wọlé fun.
Èyí mú kí owó epo bẹntiróòlù lọ sókè láti N185 jálá kan di iye tó lé ní N300 jálá kan.
Ní báyìí, iye tí wọ́n ń ta jálá epo bẹntiróòlù wà láàárín N568 sí N1,000 káàkiri Nàìjíríà.
Àmọ́ àwọn onímọ̀ kan kò gbà pé ìjọba kò san ìrànwọ́ ori epo bẹntiróòlù mọ́ nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé iye í wọ́n ṣì ń ta epo kéré sí iye tí wọ́n fi ń gbe wọlé lọ.
Jù gbogbo rẹ̀ lọ, ọdún kan lẹ́yìn tí Tinubu kéde pé kò ní sí ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù mọ́, ipa wo ní èyí ti ní lórí àwọn ọmọ Nàìjíríà?
A ò rí oúnjẹ jẹ bíi ti àtijọ́ mọ́ – ará ìlú kọminú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìdí tí ìjọba fi ní àwọn yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù ni pé owó tí ìjọba ń ná sí pọ̀ púpọ̀ tó sì jẹ́ wí pé àwọn èèyàn péréte ló ń jẹ àǹfàní rẹ̀.
Wọ́n ní owó tó yẹ kí àwọn máa fi san owó subsidy ọ̀hún ni àwọn yóò máa lò láti fi ṣe àwọn ohun amáyédẹrùn tí gbogbo èèyàn yóò jẹ́ àǹfàní rẹ̀.
Lọ́pọ̀ ìgbà ni Tinubu ti sọ pé yíyọ subsidy ti mú kí àwọn fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó pamọ́ tí àwọn ń lò sí àwọn ẹ̀ka mìíràn àti pé yíyọ subsidy ti mú kí òun yọ inubu lóko ìparun.
Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Nàìjíríà ní láti ìgbà tí ìjọba ti yọ ìrànwọ́ orí epo ni ìgbéayé kò ti rọrùn fún àwọn mọ́.
Lára àwọn ará ìlú tó bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ ní láti ìgbà tí ìjọba Tinubu ti bẹ̀rẹ̀ ní ọdún tó kọjá ni nǹkan kò ti rọrùn fún àwọn mọ́ nítorí gbogbo oúnjẹ ló ti gbówó lórí.
Wọ́n ní iye tí àwọn fi ń ra oúnjẹ ti lékún ní ìlọ́po ọ̀nà látàrí owó epo tó gbówó lórí àti ìjáwálẹ̀ tó ti bá owó náírà sí dọ́là.
Ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ kéréje ló ti kógbá sílé lẹ́yìn yíyọ ìrànwọ́ orí epo – onímọ̀
Onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé, Bisi Iyaniwura ní iṣu kò ṣè é rà lọ́jà mọ́ nítorí iye tí wọ́n ń ta iṣu ti di nǹkan tí mẹ̀kúnù kò lè rà mọ́.
“Iṣu kò ṣè é rà lọ́jà, àwọn ọlọ́jà ní àwọn èèyàn kò ra iṣu mọ́, iṣu ẹyọ̀kan ni wọ́n ń tà ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta náírà báyìí.
“Gaàrí ní kí ló ṣubú tẹ òhun ike ọ̀dà gaàrí ti di N4,500, ba ṣe ń lọ nísìn-ín Ọlọ́run má jẹ kó wọ N6,000.”
Iyaniwura ní ìjọba kò rí owó kankan fi pamọ́ láti ìgbà tí wọ́n ti yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù nítorí wọ́n ń lo owó tó pọ̀ ju iye ti tẹ́lẹ̀ lọ láti fi ṣe ìrànwọ́ fún epo.
Ó wòye pé ìṣòro tó lágbára ni yíyọ ìrànwọ́ orí epo ń mú bá àwọn ará ìlú àti pé nílò láti sán ṣòkòtò wọn kó le kí ìdẹ̀kùn le bá ará ìlú.
Ó fi kun pé tí owó epo àti afẹ́fẹ́ ìdána kò bá gbówó lórí bí ó ṣe wà báyìí, àwọn ènìyàn máa ní àǹfàní láti ṣe iṣẹ́ àmọ́ ipò tí ọrọ̀ ajé Nàìjíríà wà kò ran àwọn ilé iṣẹ́ kéréje lọ́wọ́.
Ó ní ó jọ́ wí pé ìjọba kò mọ nǹkan tó yẹ kí wọ́n ṣe àmọ́ tí wan kò láti ṣe nítorí subsidy ní nǹkan ṣe pẹ̀lú owó náírà sí dọ́là.
Iyaniwura rọ ìjọba láti pèsè iṣẹ́ fún àwọn èèyàn, kí ètò ọrọ̀ ajé lè gbèrú, tí gbogbo nǹkan yóò sì rọrùn fún àwọn èèyàn.















