Wo àwọn ètò márùn ún tí Ààrẹ Tinubu ṣe láàrín ọdún kan lórí ipò àti bí ó ṣe kàn ọ́

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Tinubu/FACEBOOK
- Author, Faoziyah Saanu-Olomoda
- Role, Broadcast Journalist
Ní Ọjọ́rú, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Karùn-ún ọdún 2024 ló máa pé ọdún kan géérégé tí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu gorí ipò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ tuntun Nàìjíríà.
Ọdún 2027 ni ìrètí wà pé sáà Bola Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bí ààrẹ yóò wá sópin gẹ́gẹ́ bí òfin Nàìjíríà ṣe là á kalẹ̀ pé ọdún mẹ́rin ni sáà kan fún ààrẹ.
Ṣáájú ètò ìdìbò ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù Kejì ọdún 2023 tó gbé Tinubu wọlé, ìrétí àwọn ọmọ Nàìjíríà ga púpọ̀ lórí ẹni tí yóò gba lọ́wọ́ ààrẹ Muhammadu Buhari tó tukọ̀ Nàìjíríà fún ọdún mẹ́jọ láti ọdún 2015 sí 2023.
Lára ohun tó jẹ àwọn ọmọ Nàìjíríà lógún jùlọ nígbà náà, tí wọ́n ń fẹ́ kí ìjọba tuntun mójútó ni bí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà yóò ṣe bọ̀ sípò tí ohun gbogbo yóò sì wà ní gbẹdẹmukẹ fún tolórí tẹlẹ́mù.
Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ààrẹ Tinubu ti ní ìjọba òun, gẹ́gẹ́ bí àkọmọ̀nà ìpolongo ètò ìdìbò òun, ní èròńgbà láti mú ìrétí àwọn èèyàn wá sí ìmúṣẹ nípa sísọ Nàìjíríà di orílẹ̀ èdè tí ọrọ̀ ajé rẹ̀ dára jùlọ nílẹ̀ Adúláwọ̀.
Ọdún kan lẹ́yìn ìbúrawọlé fún Tinubu láti gba àkóso Nàìjíríà, àwọn ètò wo ni ààrẹ ti ṣe láti mú ìrọ̀rùn bá àwọn ọmọ Nàìjíríà?
Yíyọ ìránwọ́ orí epo bẹntiróòlù

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ Tinubu sí àwọn ọmọ Nàìjíríà lẹ́yìn tí wọ́n búra fún-un tán ni Tinubu kéde pé ìjọba kò ní máa san owó ìránwọ́ orí epo mọ́.
Yíyọ ìrànwọ́ orí epo yìí mú kí owó epo bẹntiróòlù gbowó lórí ní ìlọ́po mẹ́ta àti jù bẹ́ẹ̀ lọ ní àwọn ìpínlẹ̀ mìíràn. Láti N185 ni epo bentiróòlù ti wọ
Ìgbésẹ̀ yìí bákan náà ṣokùnfà kí àwọn ọjà gbówó lórí púpọ̀ gan, tó sì pọn kún ọ̀wọ́n gógó tó ń bá Nàìjíríà fínra tẹ́lẹ̀.
Ọ̀pọ̀ àwọn lámèyítọ́ ló bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba Tinubu lórí yíyọ ìrànwọ́ ori epo bẹntiróòlù pé ìjọba kò ronú jínlẹ̀ nípa rẹ̀ kí wọ́n tó yọ ọ́, tí àwọn kan sì ní àǹfàní ìjọba tí àwọn mẹ̀kúnù ń jẹ jùlọ ni wọ́n ti yọ ọ̀hún.
Wọ́n ní ó yẹ kí ìjọba ti ṣe àwọn ètò tí yóò mú ìdẹ̀kùn bá àwọn aráàlú kalẹ̀ ṣáájú kí wọ́n tó yọ ìránwọ́ náà.
Àmọ́ Tinubu lọ́pọ̀ ìgbà sọ wí pé yíyọ ìrànwọ́ ori epo ní àǹfàní tó pọ̀ ju àléébù rẹ̀ lọ àti pé ìgbésẹ̀ náà ti kò jẹ́ kí Nàìjíríà wọ oko ìparun báyìí.
Ààrẹ ní lára owó ìránwọ́ orí epo tí àwọn ti fi pamọ́ ni àwọn ti ń lò láti fi ìdàgbàsókè mìíràn fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.
Ní ayé 1970s ni ètò ìrànwọ́ orí epo bẹ̀rẹ̀ ní Nàìjíríà àmọ́ nígbà ayé ológun Olusegun Obasanjo ni wọ́n fi òfin lélẹ̀ pé wọ́n ò gbọdọ̀ máa ta àwọn ọjà kan kọjá iye tí ìjọba bá gbe kà lọ. Epo bẹntiróòlù wà lára àwọn ọjà náà.
Ìgbésẹ̀ ìjọba nígbà náà ni láti mú ìdẹ̀kùn bá àwọn èèyàn Nàìjíríà látàrí ọ̀wọ́n gógó tó ń bá àwọn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, àwọn onímọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí rọ ìjọba láti yọ ìrànwọ́ náà nítorí pé àwọn èèyàn péréte láwùjọ ni ìgbésẹ̀ náà ń ṣe àǹfàní fún àti pé ọ̀bítíbitì owó tí wọ́n ń ná si lè wúlò láti fi ṣe àǹfàní fún àwọn ìdágbàsókè ẹ̀ka mìíràn.
Ṣáájú Tinubu ni àwọn ìjọba ti gbèrò láti yọ ìrànwọ́ ori epo bẹntiróòlù àmọ́ tí kìí wá sí ìmúṣẹ nítorí ihà tí àwọn èèyàn kọ si.
Owó Náírà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹfà, ọdún 2023, ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn tí Tinubu gba àkóso ìjọba Nàìjíríà ni ilé ìfowópama àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN kéde pé àwọn kò ní fi gbèdéke sí iye tí owó náírà yóò máa jẹ́ fún dọ́là mọ́.
Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé iye ọjà ni yóò máa sọ iye tí dọ́là sí náírà yóò máa jẹ́.
Ìgbésẹ̀ yìí wáyé láti mú ìgbòòrò bá ètò ọrọ̀ ajé, mú kí owó náírà dúró ire sí dọ́là.
Àmọ́ àwọn onimọ́ nípa ètò ọrọ̀ ajé sọ pé ìgbésẹ̀ náà kò dára tó nítorí Nàìjíríà kò ní okoòwò mìíràn tó ń kó lọ sí ilẹ̀ òkèrè ju epo rọ̀bì lọ.
Wọ́n ní iye tí Nàìjíríà ń ná lórí dọ́là láti fi ra ọjà ní ilẹ̀ òkèrè kó wá sí Nàìjíríà ju iye tí àwọn ọjà fi ń jáde lórílẹ̀ èdè yìí lọ àti pé epo rọ̀bì tí Nàìjíríà gbójúlé kò fi bẹ́ẹ̀ tà mọ́ lọ́jà àgbáyé.
Èyí ni wọ́n ní ó máa fa kí ọ̀wọ́ngógó tún peléke si.
Ọkọ̀ tí kò lo epo bẹntiróòlù

Oríṣun àwòrán, IVM
Látàrí bí owó epo bẹntiróòlù ṣe ti gbẹ́nu sókè, tí owó tí àwọn èèyàn fi ń wọ ọkọ̀ sì ti gbówó lórí gegege ni ààrẹ Tinubu kéde pé òun máa kó àwọn ọkọ̀ tí kò lo epo bẹntiróòlù wọ Nàìjíríà.
Tinubu, nígbà tó ń bá ìgbìmọ̀ aláṣẹ sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Kẹtàlá oṣù Karùn-ún ọdun 2024, ní kí gbogbo àwọn iléeṣẹ́ àti lájọlájọ ìjọba ra àwọn ọkọ̀ tí kìí lo epo bẹntiróòlù wọ Naìjíríà.
Ó ní ìgbésẹ̀ yìí yóò mú àdínkù bá ìnàwó ríra epo sí ọkọ̀ àti pé àwọn ọkọ̀ tí kò lo epo bẹntiróòlù ló dára jùlọ fún àyíká pàápàá lórí àyípadà ojú ọjọ́ tó ń da gbogbo orílẹ̀ èdè àgbáyé láàmú.
Tinubu ní ọkọ̀ 11,500 ni àwọn ń gbèrò láti kó wọ Nàìjíríà láìpẹ́ ọjọ́, tí èròńgbà àwọn sì ni pé tó bá máa fi di ọdún 2027, àwọn á ti kó tó mílíọ̀nù kan wọ́ Nàìjíríà.
Ètò ọrọ̀ ajé

Oríṣun àwòrán, Instagram/officialasiwajubat
Láàárín oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023 sí oṣù Karùn-ún ọdún 2024 ni àlékún ti gun owó orí tí ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ ń fún àwọn ilé ìfowópamọ́ kéékèèkèé fún ètò ìdókoòwò wọn ní Nàìjíríà.
Ṣaájú kí Tinubu tó yan Olayemi Cardoso gẹ́gẹ́ bí gómìnà ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN ,ní oṣù Kẹsàn-án 2023, ìdá méjìdínlógún (18.75%) ni ètò ìdókoòwò wà àmọ́ tó ti di ìdá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26.25%) báyìí.
Ètò ìdókoòwò máa ń ní ipa tó lágbára lórí ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè tó fi mọ́ Nàìjíríà nítorí ohun ló máa ń ṣokùnfà iye àlékún owó tí àwọn ilé ìfowópamọ́ máa ń gbà lọ́wọ́ àwọn tó bá yáwó láti fi ṣòwò.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́jà àti àwọn olùdókoòwò ní Nàìjíríà ní àlékún owó náà ti ṣe àkóbá fún àwọn nítorí àwọn máa lo owó tó pọ̀ loáti fi san owó tí àwọn bá yá.
Wọ́n ní orí ọjà àwọn ni àwọn máa fi àlékún náà lé tó sì lè ṣokùnfà kí owó ọjá gbówó lórí si.
Ẹ̀yáwó fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́

Oríṣun àwòrán, Instagram/officialasiwajubat
Ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Kẹfà, ọdún 2023 ni ààrẹ Tinubu kéde pé àwọn máa bẹ̀rẹ̀ sí ní fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga ní ẹ̀yàwó láti fi ràn wọ́n lọ́wọ́ láti prí ẹ̀kọ́ wọn ní ìrọ̀rùn.
Níbi ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti fi ṣàmì àyájọ́ ìjọba àwaarawa tí Tinubu kọ́kọ́ ṣe nígbà tó dé orí oyè ló ṣe ìkéde náà.
Ní oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023 ni wọ́n ní ètò náà yóò bẹ̀rẹ̀ àmọ́ ní oṣù Karùn-ún 2024 ni ètò náà kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ di àsìkò yìí.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí kò ní owó láti fi tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ wọn ni ètò ẹ̀yàwó yìí wà fún, tí akẹ́kọ̀ọ́ yóò sì dá owó náà padà lẹ́yìn ọdún méjì tó bá sin orílẹ̀ èdè tán.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìjọba àpapọ̀ 126 ló ní àǹfàní láti yá owó náà.















