Ṣé lóòtọ́ làwọn ẹgbẹ́ alátakò ń wá ọ̀nà àjọṣepọ̀ Obi àti Atiku láti kojú Tinubu lọ́dún 2027?

Oríṣun àwòrán, Peter Obi/Atiku Abubakar@ Facebook
Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ bayii laarin awọn ẹgbẹ oṣelu alatako meji, PDP ati ẹgbẹ Labour, òye foju han pe gbogbo ipa ni wọn n sa lati wa ondije ti yoo gbe Aarẹ Bọla Tinubu lulẹ ninu ibo 2027.
Eyi ri bẹẹ pẹlu bi ajọṣepọ ati ọrọ ajọsọ ṣe n waye leralera laarin Atiku Abubakar ati Peter Obi, ti awọn mejeeji jẹ alatako ninu ẹgbẹ PDP ati Labour.
Gbogbo ajọsọ ọrọ naa ko ju bi wọn yoo ṣe sọwọpọ di ẹgbẹ kan ṣoṣo ti yoo gbe Tinubu lulẹ ni 2027 lọ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti Peter Obi ṣe laipẹ yii lo ti gboriyin fun Atiku.
Obi sọ pe inu oun dun si awọn ọrọ ti Atiku n sọ lẹnu ọjọ mẹta yii, to n fi igboya han lati koju Tinubu ni 2027, to si tun n sọrọ iṣọkan Naijiria.
A ò tí ì sọ̀rọ̀ nípa olùdíje tí a fẹ́ẹ́ lò, ṣùgbọ́n ẹni tó kájú ẹ̀ la máa mú
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu Labour, Ọmọwe Tanko Yunusa, ṣalaye fun BBC pe ireti awọn ni lati ṣiṣẹ pọ fun aṣeyọri.
O ni loootọ lawọn ko ti i sọrọ nipa ẹni ti yoo dije lorukọ ẹgbẹ tawọn ba fa kalẹ, ṣugbọn o daju pe ẹni to kaju ẹ lawọn yoo fa kalẹ lati fi agba han Aarẹ Tinubu.
‘’Ọrọ ẹni to maa jẹ olori fun wa ko ti i ṣẹlẹ rara, awọn olori ẹgbẹ oṣelu mejeeji ti n sọrọ pọ lati mọ ẹni to yẹ.
‘’Ṣugbọn awa ti mọ laarin wa pe a gbọdọ wa ẹni to kaju ẹ, to ni gbogbo amuyẹ to si le ṣiṣe yii daadaa’’
Bẹẹ ni Agbẹnusọ labour wi.
Bakan naa ni Agbẹnusọ fun Atiku Abubakar, Abdulrashid Shehu Uba Sharada, sọ pe ọpọlọpọ iṣoro ni iṣakoso awọn APC ti da silẹ fawọn eeyan Naijiria.
O ni adehun ti wọn ki i muṣẹ ni wọn n ṣe fun araalu. Irọ gbuu si ni ti ọrọ iṣọkan ti wọn sọ.
Tẹ o ba gbagbe, eyi kọ ni igba akọkọ ti ẹgbẹ oṣelu alatako yoo gbiyanju lati di ọkan ṣoṣo ni Naijiria. Ṣugbọn ọpọ igba ni wọn maa n lulẹ ninu igbiyanju naa.
Ẹgbẹ Labor, ti Peter Obi ati NNPP, ti Rabiu Musa Kwankwaso, ti gbiyanju lati ṣiṣẹ pọ ri, ṣugbọn o pada dofo nigba ti ẹnu wọn o ko lori ẹni ti yoo ṣoju wọn.














