'Mo fowó mi polongo ìbò fún Tinubu nírètí pé yóò pèsè iṣẹ́ yanturu, ṣùgbọ́n èmi gan ti pàdánù iṣẹ́ mi báyìí'

Àkọlé fídíò, Mo fowó mi polongo ìbò fún Tinubu pé yóò pèsè iṣẹ́ ṣùgbọ́n èmi gan ti padánù iṣẹ́ mi
'Mo fowó mi polongo ìbò fún Tinubu nírètí pé yóò pèsè iṣẹ́ yanturu, ṣùgbọ́n èmi gan ti pàdánù iṣẹ́ mi báyìí'
    • Author, Busayo James-Olufade
    • Role, Senior Journalist, BBC News Yoruba

Bi orilẹede Naijiria ṣe n ṣe ayajọ ọdun karundinlọgbọn ti wọn pada si iṣejọba tiwantiwa, ti aarẹ orilẹede naa bayii, Bọla Tinubu pẹlu si n ṣe ayajọ ọdun to de ori oye oniruuru ni ohun ti ọpọ n sọ nipa rẹ.

Lara awọn dọ to fi gbogbo ọkan wọn tẹle Bọla Tinubu lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin ni Sulaiman Yusuf jẹ.

Amọṣa o lẹyin ọdun kan ti oludije to gbe ka ori lasiko ipolongo idibo de ipo tan, bawo lọrọ ṣe ri fun un? |se Sulaiman ṣi le fọwọ sọya pe loju ọna Tinubu loun wa mọ?

Ninu ọrọ to ba BBC sọ, Sulaiman ni oun o fi gbogbo ara gba ti ọdun kan akọkọ Aarẹ Tinubu nitori pe, gẹgẹ bi o ṣe, pupọ awọn nnkan ti oun dimu gẹgẹ bi ireti ni ko tii wa si imuṣẹ.

“Mo woye pe diẹ lara awọn lo n wa si imuṣẹ lẹnu lọwọlọwọ yii

‘Mo padanu iṣẹ mi lọdun yii’

Yusuf ṣalaye pe ṣaaju wiwọle Bọla Tinubu si ori alefa aarẹ, oun ni iṣẹ lọwọ ti oun nṣe, amọṣa ọr ko ri bẹẹ mọ nitori pe oun ti padanu iṣẹ oun bayii.

“Mo padanu iṣẹ mi lọdun yii, awọn ọpọ eeyan miran naa lo padanu iṣẹ wọn laarin ọdun to kọja si ọdun yii.”

O ni idakeji ipese iṣẹ lọpọ yanturu ti Tinubu ṣe ileri fun Naijiria lawọn n ri.

Iya Yusuf Sulaiman

Oríṣun àwòrán, Adama Sulaimon

“O ṣeleri lati mu adinku ba iye dọla kan si naira, amọṣa, iye naira si dọla bayii ti n pin gbogbo eeyan lẹmi, titi kan iya mi gan pẹlu ninu okoowo rẹ.”

Iya Sulaimanpẹlu, Adama Sulaiman, salaye pe ariwo Tinubu lo le ṣe ni ọmọ oun n pa nigba ti asiko idibo to lọdun 2023, ṣugbọn ‘nigba to ya, a ko ri nnkankan to ṣe.

Iya Sulaiman ni eto ọrọ aje ti da gbogbo oniṣowo wolẹ ti gbogbo ọja si ti wọn lawọn onibara si ti sa lọ tan nigba ti awọn naa ko ri owo ti wọn le fi ra awọn ọja to ti di ọwọ gogo bayii.