Kí ló dé táwọn aṣòfin ń gbèrò láti yí orin orílẹ̀èdè Nàìjíríà kúrò ní 'Arise O compatriot'?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹ́yìn ogójì ọdún, ilé aṣòfin àpapọ̀ Nàìjíríà ti gbé òfin tuntun kan kalẹ̀ tí yóò mú kí Nàìjíríà padà sí lílo orin orílẹ̀ èdè ayé àtijọ́.
Òfin tuntun yìí túmọ̀ sí pé orin orílẹ̀ èdè tí à ń lò lásìkò yìí ìyẹn “Arise o compatriot” kò ní jẹ́ lílò mọ́ níbi àwọn ayẹyẹ tó jẹ́ ti orílẹ̀ èdè, tí a ò sì padà sí “Nigeria we hail thee”.
Lẹ́yìn tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gba òmìnira lọ́dún 1960 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní lo “Nigeria we hail thee” àmọ́ nígbà tí wọ́n ṣe àyípadà rẹ̀ sí “Arise o compatriot” lẹ́yìn Olusegun Obasanjo gba ìjọba lọ́dún 1978.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ilé aṣòfin ń ti àbá yìí lẹ́yìn, ìwé òfin Nàìjíríà fàyè gba àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè láti sọ àríwísí wọn lórí àbá náà nígbà tí wọ́n bá ti kà á fún ìgbà kejì nílé aṣòfin.
Èyí ló mú kí agbẹjọ́rò àgbà Nàìjíríà, tó tún jẹ́ Mínísítà fétò ìdájọ́, Lateef Fagbemi ṣe ní àbá náà kò gbọdọ̀ bẹ̀rẹ̀ kó sì parí sí ilé aṣòfin.
Ó ní kí àwọn aṣòfin pe àwọn ará ìlú jọ láti gbọ́ èrò wọn lórí ìgbésẹ̀ náà, kí wọ́n sì mọ ohun tí àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè yìí ń fẹ́.
Ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Karùn-ún 2024 ni ilé aṣòfin àgbà kọ́kọ́ ka àbá náà fún ìgbà àkọ́kọ́.
Bí àbá náà ṣe jẹ́ kíkà láàárín ọ̀sẹ̀ fún ìgbà kìíní àti èkejì ń mú kí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kọminú lórí pàtàkì kíkọ orin orílẹ̀ èdè àtijọ́ náà tó fi mú kí àwọn aṣòfin járamọ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́.
Onírúurú ìpèníjà ló ń bá Nàìjíríà fínra lásìkò yìí lórí ètò ọrọ̀ ajé, ààbò, ìṣẹ́ àti òṣì, ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọ̀rọ̀ orin orílẹ̀ èdè kọ́ ni ó wà lọ́kàn àwọn ọmọ Nàìjíríà báyìí àmọ́ ó jọ wí pé ohun tó ń ṣe àwọn aṣòfin kò jọ mọ́ ohun tó bá àwọn ọmọ Nàìjírià fínra.
Kí ló dé tí àwọn aṣòfin fẹ́ yí orin orílẹ̀ èdè padà
Oríṣiríṣi àwíjàre ni àwọn aṣòfin àgbà ti sọ pé ó mú àwọn gbèrò láti yí orin orílẹ̀ èdè padà sí ti ayé àtijọ́.
Aṣòfin Okechukwu Eze tó ń ṣojú ẹkùn àríwa Enugu ní àwọn ọmọ Nàìjíríà kìí ní ìmọ̀lára tí wọ́n bá ń kọrin orílẹ̀ èdè tí à ń lò báyìí.
Eze wòye pé orin orílẹ̀ èdè “Arise O compatriot” tí à ń lò báyìí kò já mọ́ nǹkankan lọ́kàn àwọn èèyàn àti pé tí àwọn ọ̀dọ́ bá ń kọ kìí dàbí wí pé wọ́n mọ ìtumọ̀ rẹ̀ rárá.
Aṣòfin Mohammed Tahir Mongono láti àríwá Borno ní ìpínlẹ̀ Sokoto ní ó dára láti ju orin orílẹ̀ èdè náà sílẹ̀ nítorí àwọn ológun ló pa á ní dandan fún àwọn ènìyàn láti máa lò ó.
Sẹ́nétọ̀ Yohanna Amos ní tirẹ̀ ní ìdí tí òun fi dìbò pé kí wọ́n ka àbá náà fún ìgbà kejì kò ṣẹ̀yìn pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà yóò yan orin orílẹ̀ èdè tí wọ́n fẹ́ fúnra wọn.
Olórin aṣòfin tó kéré jùlọ, Michael Bamidele tó gbé àbá náà kalẹ̀ ní orin orílẹ̀ èdè ṣe pàtàkì fún orílẹ̀ èdè àti pé pípadà sí orin ayé àtijọ́ náà yóò dá àwọn ìrántí ayé àtijọ́ padà sọ́kàn àwọn èèyàn.
Bamidele gbàgbọ́ pé pẹ̀lú gbogbo ìyapa tó ń wáyé káàkiri Nàìjíríà báyìí, orin orílẹ̀ èdè ayé àtijọ́ náà yóò dàbí okùn tí yóò so àwọn èèyàn pọ̀.
Kí ló wà nínú orin ayé àtijọ́ náà?
Àwọn aṣòfin tó ń ṣe àtìlẹyìn fún àbá náà ní ìdí tí àwọn fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé orin ayé àtijọ́ náà dára ju èyí tí à ń lò lọ.
Wọ́n ní àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú orin àtijọ́ náà jinlẹ̀ tó sì ní àwọn ìtumọ̀ tó múnilọ́kàn.
Wọ́n ní ó ṣe àfihàn ìtàn, ẹ̀yà Nàìjíríà àti pé ó ń kọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti gbé nínú ìṣọ̀kan àti òótọ́ àti pé ó parí pẹ̀lú àdúrà pé kí Ọlọ́run bùnkún wa.
Àmọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí ayélujára ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ náà.















