Wo ohun tó ṣokùnfà ọ̀wọ́ngógó tòmátò káàkiri Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Others
Minisita fun eto ọgbin lorilẹede Naijiria, Abubakar Kyari ti ni bi ọwọngogo ṣe gbode lori tomato ni awọn apa ibi kan lorilẹede Naijiria, ko sẹyin bi kokoro kan se ikọlu si awọn oko Tomato.
O sọ eyi loju opo ayelujara rẹ, to si ni pe orukọ kokoro naa Tomato Ebola tabi Tomato Leaf Miner.
Kyari ni gbogbo ọna ni ijọba apapọ n gbe lati fopin ijamba ti awọn kokoro n ṣe si awọn oko Tomato.
Pupọ ile lo ti sun si lilo Tomato ti wọn lọpọ di po eyi ti wọn gbe wa lati oko nitori bi ọwọn gogo ṣe gbode.
Kyari ni ”Ọpọlọpọ oko Tomato ni awọn kokoro Tomato Ebola tabi Tomato Leaf Miner yii ti ṣe ikọlu si.
Eyi lo jẹ ka a ma ri pupó Tomato ni ọja, to si jẹ ohun naa lo sokunfa bi ọwọn gogo rẹ se gbode.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
“Ẹka eto ọgbin lorilẹede Naijiria ti n gbe igbesẹ lati koju iṣẹlẹ yii. A ti ran awọn akọsẹmọṣẹ lọ si ninu awọn oko ti awọn kokoro yii ti ṣe ijamba.
“Lafikun, a yoo ṣe atilẹyin ati iranlọwọ fawọn agbẹ wa ni kiakia, ki ikolọ wọn le pada.
“A mọ pe eyi n ṣe akoba nla fun araalu wa sugbọn a sisẹ llori bi gbogbo eyi yoo se di ohun igbagbe, ti ọwọn gogo yoo si di ohun igbagbe
Ẹwẹ ni Minisita ni owo toto N309bn ni owo ti eto ọgbin fikun owo isuna Naijiria lori ere ọja ti wọn pa wọle lọdun kọja.

Oríṣun àwòrán, X/Abubakar Kyari















