Lẹ́yìn ó rẹyìn, ilé aṣòfin àgbà l'Abuja buwọ́lu àbá láti padà sí orin ìyìn ilẹ̀ Naijiria àtijọ́

Aworan aare ile asofin agba

Oríṣun àwòrán, President of the Senate/X

Ile igbimọ aṣofin agba lorilẹede Naijiria ti buwọlu aba Orin iyin orilẹede Naijiria 2024, to n pe fun rirọpo orin iyin si eyi ti wọn se akọsilẹ rẹ lasiko ti orilẹede Naijiria gba ominira.

Aba yii, ni o ti kọja ipele ikinni ati ikeji ni Ọjọbọ, to si n duro aṣẹ lati ọwọ Aarẹ Bola Tinubu.

Ile igbimọ aṣofin ni orin orilẹede ‘Ẹ Dide ẹyin ara, ẹ jẹ ka gbe Naijiria’ ni wọn yoo rọpo si ‘Najiria, a kan sara si ẹ’

Orin iyin tẹlẹ yii ni wọn ṣe akọsilẹ rẹ nigba ti orilẹede Naijiria gba ominira lọjọ kinni oṣu kẹwaa ọdun 1960, to jẹ oun ni wọn yoo fi rọpo eyi ti a n lo lọwó.

Lillian Jean Williams, ọmọ orilẹede Gẹẹsi lo ṣe akọsilẹ orin naa ti Frances Berda si kọ ọ sita.

Orin yii ni wọn ṣapejuwe gẹgẹ bii eyi ti o kopa nla ninu idagbasoke orilẹede Naijiria .

Olori ọmọ ile, Opeyemi Bamidele sọ lori ipa orin iyin naa.

O ni, “ orin yii mu ajọsepọ wa laarin awọn ọmọ Naijiria wa. Awọn to wa lasiko naa mọ ipa to ko ninu itan orilẹede Naijiria.”

Lọjọ Aje ọsẹ yii ni ile igbimọ bẹrẹ si ni gbọ ipinnu lori aba naa.

Aworan apero ile igbimọ aṣofin agbe lorilẹede Naijiria

Oríṣun àwòrán, @NGRSenate

Bamidele, ẹni to soju Aarẹ igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio ninu ipade apero naa, ni ẹsẹ keji orin iyin ti a n lo lọwọ yii ni yoo jẹ adura orilẹede.

Ninu ọrọ rẹ, Adajọ agba lorilẹede Naijiria, Lateef Fagbemi ni ile igbimọ aṣofin nikan ko lo sọrọ lori aba yii, to si pe fun pe ki gba ero awọn lori igbesẹ ti wọn fẹ gbe.

O ṣe koko ko jẹ ki wọn aba yii kiri lati mọ boya ohun ti awọn Naijiria fẹ niyẹn.