Wo orin Nàìjíríà tuntun ní èdè Yorùbá, àti ìgbésẹ̀ ṣísẹ̀ n tẹ̀lé tí o lè gbà fi mọ̀ọ́ ní kíákía
Ni Ọjọru ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2024 ni aarẹ orilẹede Naijiria buwọlu abadofin fun idapada orin apapọ Naijiria tuntun.
Ofin naa buwọlu orin atijọ ti orilẹede Naijiria n kọ nigba ijọba amunisin gẹgẹ bi orin tuntun ti yoo di kikọ bayii gẹgẹ bi orin apapọ tuntun fun orilẹede Naijiria.
Laarin ọdun 1960 ti Naijiria gba ominira si ọdun 1978 ni Naijiria fi kọ orin “Nigeria we hail thee” ki o to di pe ijọba ologun labẹ Ọgagun Oluṣẹgun Ọbasanjọ yii pada si “Arise O Compatriots”.
Wo awọn igbesẹ kọkọkan ti o le gba fi kọ orin apapọ Naijiria tuntun naa ni irọrun.
- Wo kókó àṣeyọrí ìjọba Ààrẹ Bola Tinubu láàrin ọdún kan tó dé ipò ààrẹ
- 'Èmi ò ní báwọn kọ orin ìyìn Nàìjíríà àtijọ́ tí Tinubu fòntẹ̀ lù,' mínísítà tẹ́lẹ̀ rí yarí
- Ààrẹ Tinubu kéde wíwọ reluwé lọ̀fẹ̀ẹ́ fún oṣù mẹ́fà l'Abuja
- 'A ò rí oúnjẹ jẹ bíi ti àtijọ́ mọ́,' aráàlú kọminú lẹ́yìn ọdún kan tí ìjọba yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù
Igbesẹ akọkọ: Ka ọrọ inu orin naa ki o si mọ wọn dọkan.
O le ṣe eyi nipa ṣiṣe akọsilẹ ọrọ inu orin naa yala lede oyinbo tabi ni ede Yoruba.
A kí ọ 'lẹ̀ Nàìjíríà Nigeria we hail thee
1. A kí ọ 'lẹ̀ Nàìjíríà Nigeria we hail thee,
Ilẹ̀ ibí wa ọ̀wọ́n Our own dear native land,
Ẹ̀yà àti èdè le yàtọ̀ Though tribe and tongue may differ,
Ní'ṣọ̀kan la dúróIn brotherhood, we stand,
Gbogbo wa fi ìgboyà kí ọNigerians all, and proud to serve,
Ilẹ̀ ìbí wa ọ̀wọ́nOur sovereign Motherland.
2. Àsìá wa yóò fihànOur flag shall be a symbol
Pé òdodo jọbaThat truth and justice reign,
Nígbà àlàáfíà, nígbà ogun In peace or battle honour’d,
Èyí ló jẹ́ èrè wa And this we count as gain,
Ta ó fi fún àwọn ọmọ waTo hand on to our children
Àsìá àìlábàwọ́n. A banner without stain
3. Ọlọ́run ẹ̀dá gbogbo O God of all creation,
Gba ẹ̀bẹ̀ wa wọ̀nyí Grant this our one request,
Jẹ́ ká ní orílẹ̀èdè Help us to build a nation
Níbi ìrẹ́jẹ kò sí Where no man is oppressed,
K'àlàáfíà àti ọ̀pọ̀ And so with peace and plenty
Jẹ ìbùkún Nàìjíríà. Nigeria may be blessed.
Igbesẹ keji: Kọ bi iro orin rẹ ṣe lọ
Akọkọ ni ki o kọ bi iro orin rẹ ṣe lọO le gbọ awọn ikasilẹ ohun orin naa ni pẹlẹputu. Fi ọkan rẹ si bi iṣẹnupe ati ohun orin naa ṣe lọ bi o ti n fi ọkan ba bi wọn ṣe kọọ ninu ikasilẹ ohun ti o n gbọ.
Igbesẹ kẹta: Bẹrẹ si ni kọ orin naa diẹdiẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bẹrẹ si ni kọ orin naa diẹdiẹ. Nigba ti o ba n ṣe eyi, rii daju pe o fọkan si ọna iṣọwọpe awọn ọrọ kọọkan ninu ohun orin naa.
Igbesẹ kẹrin: Ṣe aṣaro lori itumọ to so rọ mọ orin naa.
Ṣe aṣaro lori itumọ to so rọ mọ orin naa.
Fun apẹrẹ, ẹsẹ to gbẹyin ninu orin naa tẹnpẹlẹ mọ pataki alaafia, igbayegbadun ati ilana aparo kan o ga jukan lọ lorilẹede Naijiria.
Mimọ awọn itumọ to sodo sinu orin naa yoo tubọ mu ki o rinlẹ daadaa lọkan rẹ.
















