Àwọn oníléètura ní Kwara fẹ̀hónú hàn lórí àfikún owó iná mọ̀nàmọ́ná, wọ́n ní ó ti fẹ́ jẹ okòòwò àwọn run

Awọn ọmọ ẹgbẹ olotẹẹli ni ipinlẹ Kwara, ti ke gbajare si ijọba apapọ lati mu adinku ba owo ina monamona ki ileesẹ wọn ma baa parun.
E yi lo waye nibi iwọde ti wọn se lọ ọfisi ajọ to n dari ina ọba, NERC lọjọ Isẹgun, ọjọ kejidinlọgbọn osu karun-un ọdun ti a wa yii.
Ẹni ti o gba wọn ni akowe ajọ NERC ti o ni ki a forukọ bo ohun lasiri.
Nibi ifẹhonuhan ọhun lati ri awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn gbe pilakaadi ti wọn kọ oniruuru ọrọ si lati fẹdun ọkan wọn han.
Nigba ti o n ba BBC News Yoruba sọrọ, alaga ẹgbẹ naa, Alhaji Dauda Akande sọ pe pataki ifẹhonuhan alaafia awọn ni lati jẹki ijọba mọ ipalara ati inira ti ọwọn gogo ina monamona mu de ba awọn.
Ninu ọrọ rẹ, "pẹlu alekun ti ajọ IBEDC ṣe, alabara band A ni ọpọlọpọ wa jẹ, owo ti a n san si ti di 225 Naira fun uniti kan lati 74 Naira fun uniti kan ti o jẹ tẹlẹ.
"Igba to ya ni ajọ naa gbe e walẹ si 205 Naira fun uniti kan, sugbọn gbogbo rẹ ko boju mu to, awọn Ileesẹ wa ko si lee moribọ labẹ rẹ pẹlu bi ọrọ aje orilẹ-ede ṣe ri ni akoko yii.
"Ti ajọ IBEDC ko ba tete wa nkan ṣe lati mu adinku ba ina ọba, ọpọlọpọ oko owo ni yoo parun, ainisẹlọwọ yoo si gbode kan lorilẹ-ede Naijiria.
"Eleyi yoo si tun fa ipalara siwaju sii fun ọrọ aje wa
Alagan naa wa rọ ajọ NERC ki wọn da si ọrọ naa ni kopẹ kopẹ lati doola awọn isẹ ati oko owo.
O ni ki wọn tete fi iwe ifẹhonuhan awọn sọwọ si olu Ileesẹ wọn ni ilu Abuja fun igbesẹ ti o yẹ.
Ẹwẹ, okan lara ọmọ ẹgbẹ naa, ọgbẹni Funsho Ibrahim fi kún-un pe, tẹlẹ, otẹẹli ohun n san milionu mẹfa losu sugbọn alekun ti fa ki awọn maa san milionu marunlelogun losu.
"Nibo na fẹ ki a ti rii, elo gan-an ni a n pa wọle? Yatọ si owo ori ijọba apapọ ati ti ipinlẹ, pẹlu owo awọn osisẹ. Eleyi ko bójú mu rara. Ko si ẹni to lee moribọ, ohun ti wọn n sọ nipe ki a kogba sile".
BBC News Yoruba kan si ọga agba ajọ NERC ni Ilorin, arakunrin Amos Ajanaku lori ẹrọ ibanisọrọ
O ni oun rin irin ajo lori isẹ ilu sugbon oun yo gbiyanju wi pe awọn fi iwe ifẹhonuhan wọn sọwọ si ibi to yẹ fun atunto to peye.















