Kínni North Korea àti South Korea dì sínú bọ́ọ̀lù ńlá fi ránṣẹ́ sí ara wọn?

Aworan fere nla to kun fun idọti

Oríṣun àwòrán, Yonhap News Agency / Reuters

    • Author, By Hyojung Kim
    • Role, BBC News Korean

North Korea ti fi ogunlọgọ fere ti wọn ko idọti sinu ransẹ si orilẹede South Korea, eyi to n ṣe iranti ogun to waye laarin orilẹede mejeeji, eyi to ti wa fun ọgọta ọdun.

O le ni igba fere ti wọn so ọra mọ nidi, to jẹ pe idọti lo kunu pupọ, ni wọn ṣawari ni lorilẹede South Korea lọjọ Isẹgun, eyi lo ti jẹ ki awọn alaṣẹ ṣekilọ fun awọn araalu pe ki wọn duro sinu ile wọn.

Orilẹede North Korea ṣekilọ ni ọjọ diẹ sẹyin pe awọn yoo fi awọn fere idọti yii ransẹ lati fi gba ẹsan ohun ti ileeṣẹ South Korea fi ransẹ si wọn.

Aworan ologun South Korea to n ko idọti

Oríṣun àwòrán, Yonhap News Agency / EPA

Iwe ogun to jẹ biliọnu 2.8

Awọn iwe ogun yii, ti wọn n pe ni “pira ” ni Korea- ni awọn orilẹede mejeeji fi sinu fere ransẹ si ara wọn lasiko ogun ọdun 1950.

Igbesẹ yii lo bẹrẹ nigba ti ogun kọkọ bẹrẹ , ti ileeṣẹ ologun ajọ agbaye UN si n ju awọn iwe ogun yii si orule Ariwa.

Lati le gba ẹsan, North Korea naa fi awọn iwe ogun naa ransẹ pada si ajọ agbaye.

Nigba to ma fi di ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keje ọdun 1953, apapọ ye iwe ogun ti wọn ti fi ransẹ ti jẹ bilọnu 2.8. 2.5 bilọnu awọn iwe ogun yii to jẹ pe orilẹede South Korea ati Ajọ agbaye ti fi ransẹ , ti North Korea ati Soviet Union si fi ọọdurun milọnu ransẹ.

Iwe odun to n rọ awọn ologun pe ki wọn juwọ le

Oríṣun àwòrán, DMZ Museum

Awọn fere lo le ka gbogbo ayika Korea Peninsule ni ọpọlọpọ igba.

Pupọ awọn iwe ogun yii ni o jẹ alawọ pupọ lati fi pe akiyesi awọn araalu.

Awọn iroyin to wa ninu iwe ogun naa lo n rọ wọpn ju wọle ogun. Awọn iwe ogun mi lo wa pẹlu iwe ẹri to pe abo wa, to si n ṣe ileri fun eeyan to di wọn mu.

Iwe ogun ni eder gẹẹsi

Oríṣun àwòrán, DMZ Museum

“Gbigbe ara ẹni ga

Lẹyin adehun ọdun 1953, ti fopin si ogun naa laarin orilẹede mejeeji, pinpin iwe ogun ko dawọ duro sibẹsibẹ.

Wọn kun fun awọn ọrọ abuku to n bu ẹnu atẹlu awọn olori mejeeji ati iṣejọba wọn.

Iwe ogun

Oríṣun àwòrán, DMZ Museum

Ni ọdun 1960 ati 70s, Iwe lati North Korea n sọrọ lori idagbasoke Pyongyang ati bibuọla fun awọn aṣeyọri Alaga Kim Il-sung.

Ni ọdun 1970, iwe North Korea ṣe ileri fun awọn ọmọ ologun to wa si orilẹede ni ọpọlọpọ anfani, to fi jẹ fifun awọn ẹtọ wọn ati ominira, pi pese iṣẹ , pipese ilẹ, owo ati nawọn ẹbun mii.

Iwe to ni aworan obinrin

Oríṣun àwòrán, DMZ Museum

Lasiko yii lọdun 1970, eto ọrọ aje North Korea ni o da bi pe o da ju ti South Korea lọ, to si sokunfa idi ti awọn fi n kọ si North Korea lẹyin ti wọn ka ohun to wa ninu iwe naa.

Nigba to ma fidi ọdun 1980, ko jẹ tuntun mọ pe ki akẹkọọ South Korea mu iwe ti North Korea fi ransẹ. Mimu awọn nnkan yii wa si ile ẹkọ tabi ileeṣẹ ọlọpaa le jẹ ko jẹ ọpọlọpọ anfani pe iwe, bairo ati awọn nnkan mi to wulo funm ile ẹkọ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, DMZ Museum

Awọn ileeṣẹ ijọba fun fi aworan lede lati fi kede sita pe ẹbun wa fun ẹni to ba mu awọn eeyan to n gbẹ iyin gbẹbọjẹ tabi n gba iwe yii.

Bi eto ọrọ aje orilẹede mejeeji ṣe yipada , Orilẹede South Korea bẹrẹ sini lo anfani yii lati se nnkan fun arawọn.

Lasiko idije Olympis ọdun 1988, awọn ọrọ bii “Se o ko fẹ jẹun ko yo?’ ni wọn lo ;ati yanku awọn ọrọ yii.

Aworan

Oríṣun àwòrán, DMZ Museum

Idaduro

Lẹyin adehun ọdun 1991 ati 2000, orilẹede North ati South Korea gba lati fi opin si pinpin iwe kaakiri.

Ni ọdun 2007, Ileeṣẹ ọlọpaa fofin de ajọ to n mojuto gbigba iwe ti North Korea ba fi ransẹ.

Pẹlu bii ikede pe pinpin iwe ti dopin, sibẹsibẹ ko da bi pe o wa sopin.

Nigba ti awọn orilẹede mejeeji tun pade lasiko iṣejọba Aarẹ Lee Myung-bak, ija tun pada si awọn aarin wọn.

Iwe bẹrẹ si ni ma fo kiri bi ti tẹlẹ ni orilẹede Korea mejeeji

Yatọ si pinpin iwe

Lati ọdun 2000, ileeṣẹ kan orilẹede South Korea lewaju ninu fifi iwe to TAKO North Korea ransẹ. Bakan naa ni wọn fi awọn nnkan igbalode bi kọọpu, idomie, owo dọla ati awọn nnkan mi.

Pinpin awọn iwe to tako North Korea yii gboro wọ ọdun 2010 lẹyin ti ọkọ oju omi ileeṣẹ olgun ri sinu omi.

Lẹtin ifilọlẹ ohun ija ti North Korea ṣe ninu oṣi kinni ọdun 2016, iṣejọba Park Geun-hye ni South Korea bẹrẹ si ni lo ohun igbe ohun safẹfẹ lati ba awọn araalu sọrọ.

Awọn to n jade sita lati ẹrọ igbeohunsafẹfẹ yii l;o jẹ iroyin nipa titẹ ẹtọ ọmọ ọmọniyan mọlẹ ni North Korea, ti wọn si fi orin ọkan lara olorin to gbajumọ si ara ohun ti wọn gbe jade.

North Korea fesi pada, ti wọn si bẹrẹ sini ma pin iwe kiri nipa South Korea. Pupọ awọn iwe yii lo bu ẹnu atẹlu ilana Washington ti North Krea ati eto oṣelu ni South Korea.

Iwe to n bu Ẹnu atẹlu Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Julie Yoon / BBC

Ni ọjọ kọdinlọgbọn oṣu kẹrin ọdun 2018, Aarẹ South Korea, Moon Jae-in ati olorin North Korea Kim Jong-un kede ajọṣepọ ti wọn pe ni Panmunjom Declaration.

Awọn olori mejjeji gba lati da wọn nnkan tii duro to jẹ mọ lilo ẹrọ igbeohunṣafẹfẹ ati pin pin iwe kiri bẹrẹ lati ojọ kinni oṣu karun un.

Sibẹsibẹ, pinpin iwe lati ọwọ ẹgbẹ kan si n tẹsiwaju.

Lasiko naa, Kim Yo-jong, aburo Kim Jong-un ṣekilọ fun pe ti ijọba South Korea ko ba awọn eeyan yioi sọrọ lati dẹkun yii, ija laarin orilẹede mejeeji yoo tẹsiwaju.