Mo lè gbà kíyàwó mi yan àlè níta, kó ṣáà má ti kúrò nílé mi- Gaji onitiata

Aworan Sola Olaibi (Gaji

Oríṣun àwòrán, Sola Olaibi @Facebook

Ọpọ eeyan ni ọrọ ti gbajumọ ọkunrin onitiata nni, Sola Olaibi tawọn eeyan mọ si Gaji, sọ ṣi n ṣe ni kayeefi, bẹẹ lawọn mi-in si tun n gboriyin fun un.

Gaji to maa n kopa alawada ninu ere tiata Yoruba, sọ pe oun ko binu bi iyawo oun ba n yan ale nita.

O ni ko ṣaa ma ti kuro nile oun ni koko.

Gaji fi kun un pe ko si ọkunrin to pe, ko sobinrin to dara tan, o ni kaluku n gba ara wọn bẹẹ ni.

Ọkunrin naa sọ pe bi a ko ba le mọwa fun oniwa mọ, ki kaluku maa ba tiẹ lọ.

Lori eto ori ayelujara kan ti Biola Adebayo toun naa jẹ oṣere tiata maa n ṣe ni Gaji ti ṣalaye lori igbeyawo rẹ to daru.

‘Mi o sọ pe mi o ṣe mọ, iyawo mi lo ni o ti su oun to si fi mi silẹ lọ’

Aworan Sola Olaibi (Gaji)

Oríṣun àwòrán, Sola Olaibi @Facebook

‘’Ni gbogbo ile ti emi pẹlu iyawo mi, Iya Eniola gbe, awọn eeyan ki i gbagbọ pe tọkọ-tiyawo ni wa.

‘’Wọn maa n ro pe aburo mi ni.

‘’Emi ti mo wa l’Ekoo, ti iyawo mi wa l’Abeokuta. Ṣe ẹ ri i pe ifẹ fọju.

‘’Mo mọ itọju obinrin daadaa o. Bi mo ba tiẹ lọọ ṣiṣẹ lawọn ipinlẹ mi-in, mo maa ri i daju pe mo n pe e, mo le pe to ẹẹmẹtadinlọgọrun-un (97 times) lojumọ.

‘‘Iyawo mi lo kan deede yipada si mi, o ni o ti su oun o si fi mi silẹ, emi kọ ni mo ni mi o fẹ ẹ mọ.

‘’Koda ko tiẹ jẹ o n yan ale nita, ko ṣe nnkan kan fun mi. Ko ṣaa ma ti kọ mi silẹ’’

Bi Gaji ṣe sọrọ lori igbeyawo rẹ naa lo tun sọ pe isunmọni la a mọṣe ẹni.

Oṣere yii sọ pe ko sẹni to le mọ boya oun buru, tabi pe eeyan daadaa loun nigba toun ko ba huwa aidaa si wọn.

Lopin ifọrọwerọ naa, awọn eeyan to gboriyin fun oṣere yii pọ. Wọn lawọn nifẹ si bi ko ṣe fẹnu ba iyawo to kọ ọ silẹ jẹ.