Wo ìpínlẹ̀ márùn-ún tí àwọn èèyàn ti kú jùlọ lẹ́yìn tí Tinubu gbàjọba

Oríṣun àwòrán, Getty Image
O ti pe ọdun kan bayii ti Aarẹ Bọla Tinubu ti gba iṣakoso orilẹ-ede Naijiria, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun-un ọdun 2023 lo de ori ipo naa.
Ni gbogbo ẹkun mẹfẹẹfa ti Naijiria pin si ni eto aabo ti mẹhẹ.
Ireti awọn eeyan tẹlẹ ni pe ijọba Tinubu yoo ri iṣoro aabo yii yanju pẹlu ipolongo ifọkanbalẹ to ṣe ati ileri.
Ṣugbọn lẹyin ọdun kan iṣakoso naa, o tun n buru si i ni.
Iṣoro ijinigbe-gbowo ko kuro, paapaa lapa Iwọ-Oorun Ariwa.
Awọn Boko Haram naa ko ṣiwọ idaamu, wọn n dunkooko mawọn eeyan wọn si n pa wọn ni Ariwa-Ila Oorun.
Bakan naa lọrọ si ri lapaa Guusu-Ila-Oorun naa, ipaniyan n waye .
Ọjọ keji ti ijọba tuntun gori aleefa ni awọn agbebọn pa eeyan mẹẹẹdọgbọn (25) ni Zamfara, niluu Maru.
Ṣugbọn ijọba n sọ pe awọn n gbiyanju agbara awọn lati yanju iṣoro yii.
Illeṣẹ kan, Beacon Consulting, ṣatupalẹ ipaniyan to ti waye lẹyin ọdun kan ijọba Aarẹ Bọla Tinubu ni Naijiria, awọn ipinlẹ marun-un teeyan ti ku ju ree lẹsẹẹsẹ.
Ìpínlẹ̀ Borno

Oríṣun àwòrán, Baba Gana Zulum @ Facebook
Ipinlẹ Borno jẹ ọkan lara awọn ilu to n koju ipaniyan julọ ni Naijiria, paapaa latigba ti Boko Haram ti gberasọ nibẹ ni 2009.
Pẹlu gbogbo igbiyanju awọn ijọba iṣaaju lati ṣẹgun ikọ apaayan naa, awọn ẹgbẹ naa n gbilẹ si i ni.
Awọn ẹgbẹ bii Jama'atu Ahlis Sunna Lidda'awati al Jihad ati ISWAP ko duro rara.
Eeyan ẹgbẹrun meji ati ọgọrin (2,070) ni akọsilẹ Beacon sọ pe awọn agbebọn pa ni Borno laarin ọdun 2023 si asiko ti Tinubu gbajọba.
Nnkan mi-in tun ni pe awọn ẹgbẹ apaayan naa tun n koju ara wọn, eyi to n mu ija waye ju ti tẹlẹ lọ, araalu lo si n n fi ẹmi wọn di i.
Ọgọrun-un eeyan (100) lo ku nigba ti Jama'atu Ahlis Sunnah koju ISWAP lọjọ kẹrinla oṣu kẹrin 2024.
Eyi waye nijọba ibilẹ Kukawa.
Ọgọrun-un eeyan mi-in tun ṣegbe lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ 2023. Jama'atu Ahlis Sunna Lidda'awati al Jihad lo deede sọ wahala kalẹ fawọn eeyan naa .
Lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹfa ọdun 2023, Boko Haram kọlu awọn abule kan nijọba ibilẹ Jere, eeyan mẹẹẹdogun ni wọn pa.
Ṣugbọn ṣaa, awọn ologun ilẹ wa ko fi awọn apaayan naa lọrun silẹ, ọgọrun-un kan ni wọn pa ninu awọn ikọ Jama'atu Ahlis Sunnah, nijọba ibilẹ Gwoza, iyẹn lọjọ kọkanla, oṣu kẹfa ọdun 2023.
Ijọba ibilẹ Marte ati Kukawa ni awọn agbebọn ti paayan ju ni Borno.
Eeyan 402 ati 347 ni wọn pa labule kọọkan.
Ìpínlẹ̀ Zamfara

Oríṣun àwòrán, Govenor Dauda Lawal@Facebook
Ko jẹ ijọloju pe Zamfara lo ṣikeji ninu awọn ipinlẹ ti oku ti sun julọ lẹyin ọdun kan ijọba Aarẹ Tinubu.
Idi to fi ri bẹẹ ni pe awọn eeyan ibẹ maa n koju awọn ajinigbe to maa n beere owo nla lẹyin ijinigbe ni.
Awọn agbebọn n wọ Zamfara bo ṣe wu wọn ni. Wọn n wọ abule pa awọn eeyan, bẹẹ ni wọn da wọn lọna ni marosẹ, ti wọn aa ji wọn gbe sa lọ.
Wọn aa maa wọnu ile lọọ ji eeyan gbe ni Zamfara, wọn yoo si ko wọn wọgbo lọ.
Gomina ipinlẹ naa, Dauda Lawal, fi ẹgbẹ akọya lelẹ, minisita eto aabo wa nibẹ pẹlu, ṣugbọn bakan naa lọmọ n ṣori pẹlu aabo to mẹhẹ.
Eeyan 761 lo ku bi akọsilẹ Beacon ṣe wi, iyẹn laarin ọgbọnjọ oṣu kẹfa ọdun 2023 si oṣu karun-un 2024 yii.
Ọmọbinrin to le ni ọgbọn (30) ni wọn ji gbe, wọn pa eeyan mẹẹẹdọgbọn ni Maru, mẹẹẹdọgbọn mi-in ni Maradun.
Lọjọ kọkanla, oṣu karun-un 2024 yii, eeyan mọkandinlaaadọta (49) ni wọn pa nijọba ibilẹ Anka. Awọn abule bii Yar Sabaya, Farar ati Duhuwa ni wọn ti pa wọn.
Awọn ti wọn ku ni Maru jẹ 329, ti Tsafe si jẹ 112 .
Ìpínlẹ̀ Plateau

Oríṣun àwòrán, Caleb Mutfwang @Facebook
Ija laarin awọn agbẹ ati awọn daran-daran lo maa n saba ṣẹlẹ ni Plateau.
Eyi ti pọ ki idibo ọdun 2023 too waye, lẹyin ibo, o tun gbilẹ si i.
Eeyan 560 ni wọn ti pa lati ọjọ akọkọ ti Tinubu gba ipo aarẹ si oṣu kẹta ọdun 2024 yii. Gẹgẹ bi Beacon ṣe sọ.
Ikọlu to waye ni Riyon ni wọn ti pa eeyan mọkanlelogun
lẹyin ijọba Tinubu
Wọn pa mejilelogun (22) lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹfa, nijọba ibilẹ Mangu.
Eeyan mẹẹẹdogun mi-in tun padanu ẹmi ni Mangu logunjọ, oṣu kẹfa, latari ija to ṣẹlẹ laarin agbegbe meji.
Ijọba ibilẹ Bokkos lo padanu eeyan ju ninu awọn ikọlu ọdun kan yii, eeyan 174 lo ku lọdọ wọn.
Ijọba ibilẹ Mangu lo ṣikeji, eeyan 149 ni awọn padanu.
Ìpínlẹ̀ Benue

Oríṣun àwòrán, Hyacinth Alia @Facebook
Eeyan ẹẹdẹgbẹta le mejilelogoji ( 542), ni wọn di oku ni Benue laarin ọdun kan ijọba Tinubu.
Ikọlu to waye ni Benue si farajọ ti Plaetau naa.
Awọn agbẹ pẹlu awọn daran-daran, ẹya meji sira wọn ni wọn n fa ikọlu to n sọ ẹmi nu wọnyi.
Iṣakoso Tinubu ṣẹṣẹ pe ọsẹ kan ni wọn pa eeyan mẹẹẹdọgbọn nijọba ibilẹ Katsina-Ala.
Eyi waye lọjọ kẹta oṣu kẹfa ọdun 2023.
Awọn agbebọn ni wọn ya wọ agbegbe naa ti wọn si pa awọn eeyan lọ bii rẹrẹ.
Bakan naa, lọjọ kẹjọ oṣu keje 2023, awọn agbebọn pa eeyan mẹrinlelogun (24) nijọba ibilẹ Ukum.
Laipẹ yii ni wọn tun pa eeyan mẹwaa nijọba ibilẹ Agatu, eyi waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu karun-un ọdun 2024 yii.
Ijọba ibilẹ to padanu ẹmi ju laarin asiko naa ni Ukum, nibi ti eeyan 136 ti ku.
Ijọba ibilẹ Agatu lo tẹle e, nibi ti wọn ti pa eeyan mejidinlọgọta (58).
Bakan naa lo si jẹ pe eeyan 58 naa ni wọn pa ni Gwer West.
Ìpínlẹ̀ Kaduna

Oríṣun àwòrán, Uba Sani @Facebook
Ipinlẹ Kaduna lo wa nipo karun-un ninu awọn ibi ti ẹmi ti bọ sọwọ ipaniyan julọ latigba ti Aarẹ Tinubu ti n darii Naijiria.
Ijinigbe-gbowo, wahala awọn daran-daran ati ija ẹlẹyamẹya lo n fa wahala nipinlẹ naa.
Awọn eeyan ti sa kuro nijọba ibilẹ Birnin Gwari, Giwa ati Kajuru nitori awọn ajinigbe.
Akọsilẹ ileeṣẹ Beacon sọ pe eeyan irinwo (400), ni wọn wọn pa laarin oṣu kẹfa ọdun 2023 ati oṣu karun-un 2024.
Ijọba ibilẹ Birnin Gwari ni wọn ti paayan ju, eeyan ọgọrun-un kan ati marun-un (105) ni wọn pa.
Kauru lo tẹle e, wọn pa mẹrindinlaadọta (46) nibẹ.
Lọjọ akọkọ ninu ọdun 2024 yii, wọn pa ogoji eeyan ni Birnin Gwari.
Awọn ajinigbe tun wọ abule Kuriga lọjọ keje, oṣu karun-un 2024, wọn ji awọn akẹkọọ pupọ gbe.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ naa pada gba itusilẹ, sibẹ, olukọ wọn kan ba ijinigbe naa lọ.
Loootọ, ijọba Tinubu ba iṣoro aisi aabo yii nilẹ ni, ṣugbọn ai-sọrọ nipa rẹ yii n kọ awọn eeyan lominu.
O ṣe pataki fun ijọba yii lati wa ọna abayọ si iṣoro to n sọ ẹmi alaiṣẹ nu yii.
Nnkan ko gbọdọ maa ri bayii lọ.














