Ọmọ àti òbí mi ní láti k'ọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú àwọn ẹran láti lè sá fún àwọn ajínigbé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
“Nigba ti wọn ya wọ abule wa, mo gbọro ibọn, ti mo si sare gun ọkada mi, fi iyawo, ọmọ ati awọn obi mi silẹ,” ọkan lara olugbe agbegbe Kuchi ṣalaye fun BBC.
O fẹ kọkọ doola ẹmi ara rẹ! O wa ọna de si ilu Minna, olu ilu fun ipinlẹ Niger sugbọn o n sarẹ ọkan nipa awọn mọlẹbi rẹ.(A ko ni le darukọ rẹ nitori o lewu).
“Awọn ajinigbe yii ji iyawo mi ati ẹgbọn rẹ gbe.
Sugbọn iyawo mi pada saa mọ wọn lọwọ. Iyawo mi sọ fun mi pe awọn ajinigbe yii fẹ fi ọkọ oju omi ko awọn eeyan sọda odo Shiroro, ti o si ni anfani lati saa," o ṣalaye.
Ẹwẹ, ẹgbọn iyawo rẹ si wa pẹlu awọn ajinigbe, ti awọn ajinigbe yii si ti kan si awọn mọlẹbi pe ki wọn mu owo wa.
O ṣalaye siwaju pe “awọn ọmọ mi ati obi mi ni lati saa pamọ si ile ewurẹ, ti wọn si ṣa pamọ pẹlu awọn ewurẹ.
Nigba ti Ọlọrun yoo ba wọn ṣe, wọn ko ri wọn
Lẹyin ti awọn ajinigbe naa kuro ni agbegbe naa, awọn obi mi ati awọn ọmọ saa wọ igbo, ti sa wọ ilu mi to wa ni itosi.
Iyawo rẹ pe lori ago lẹyin ti iṣẹlẹ naa waye lati sọ fun ọkọ rẹ pe ori ko o yọ, o si ti wa ni ilu keji to sumọ. “Mo ti ba iyawo mi sọrọ sugbọn a ko si nibi kana.
Lalẹ Ọjọ Ẹti ni awọn agbebọn kan wọ agbegbe Kuchi, ti wọn si gbe ọpọlọpọ eeyan lọ.
Awọn alasẹ ni awọn agbebọn naa ni wọn wọle wa pẹlu awọn ohun ija oloro, ti wọn si furasi wọn pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ ikọ agbesunmomi, Boko Haram nitori wọn gbe asia lọwọ lasiko ikọlu naa.
Sugbọn a ko ti le fi idi yii mulẹ.
Alaga ijọba ibilẹ Munya ni awọn agbebọn naa lo to wakati meji ni agbegbe naa, ti wọn si n dana, jale kaakiri.
“A ko ri awọn ẹsọ alabo. Ilu Kuchi ati agbegbe rẹ ni o wa lọwọ agbegbọn yii,” Aminu Abdul Hamid Na-jume ṣalaye.
O sọ fun BBC pe awọn agbegbọn naa n lọ lati ojule si ojule, ti awọn si ji awọn eeyan gbe lẹyin ti wọn ṣekupa eeyan mẹwaa.
Ọdé marun un ni wọn ṣekupa lasiko ti wọn iya ija, ti eeyan mẹta mii si farapa.
Pupọ awọn ti wọn gbe lọ ni obinrin, ọmọde ati awọn agbalagba . Najume ni ninu ibẹru bojo ni awọn eeyan ni awọn ilu to sumọ wa bayii bi awọn olugbe Kuchi ṣe n daro awọn eeyan wọn to ku, ti wọn si n reti iroyin nipa awọn ti wọn ji gbe.
Olugbe mi sọ ep awọn agbebọn pada wa si ilu naa lọjọ keji lati tun wa ji awọn eeyan gbe, paapa olori ilu ati iyawo rẹ meji. Eyi lo jẹ ki awọn eeyan yooku to wa ni agbegbe ba ẹsẹ wọn sọrọ.
Ijọba orilẹede Naijiria ko si sọrọ sita lori iṣẹlẹ naa. Ki ṣe igba akọkọ ree ti ikọlu awọn agbebọn yoo waye nipinlẹ Niger. Ọpọlọpọ awọn araalu ni wọn ṣekupa tabi ji gbe lọ.
Loṣu to lọ, ọmọ ikọ ologun mẹwaa ni wọn ṣekupa.















