Wo ẹ̀bùn márùn-ún tó ṣe pàtàkí tí o lè fún ọmọ rẹ lásìkò àyájọ́ ọjọ́ àwọn ọmọdé

Oríṣun àwòrán, Others
Ajọ iṣọkan agbaye to n ri sọrọ awọn ọmọde lagbaye, UNICEF lo yan gbogbo ọjọ kẹtadinlọgbọn ninu oṣu lọdọọdun gẹgẹ bi ayajọ ọjọ awọn ọmọde lagbaye.
Erongba wọn si ni lati maa fi ifẹ han si awọn ọmọde, paapaa lati maa fi ṣe ohun ti wọn ba n fẹ fun wọn nipa mi mu inu wọn dun.
Bakan naa ni ọjọ naa tun wa fun lati maa fi polongo awọn ohun to n ṣẹlẹ si wọn, lati le ṣe iranwọ nitori igbagbọ wi pe awọn ni ọjọ iwaju orileede.
Akori ayẹyẹ ayajọ ti ọdun yii ni wọn pe ni “Fun ọmọ kọọkan, gbogbo ẹtọ”, iyẹn ti itunmọ rẹ lede oyinbo jẹ ‘For every child, every right.’
Pupọ awọn obi ati alagbato ni ko fẹẹ ye nipa bi wọn ṣe le mu inu awọn ọmọ wọn, paapaa lasiko ayajọ ọjọ lati bu ọla ati iyi fun wọn bi tonii.
Lara awọn ohun ti ẹ le ṣe lati fi mu inu awọn ọmọ yin dun ni
Jẹ ki wọn gbọ orin ti wọn nifẹ si julọ.
Awọn obi ati alagbatọ le pinnu lati jẹ ki awọn ọmọ wọn gbọ orin ti wọn nifẹ si julọ, paapaa awọn eyi to le mu ki wọn kẹkọọ, ko si fun wọn ni iwa ọmọluabi.
Eyii le jẹ orin ti awọn obi wọn ṣakosilẹ rẹ, ti wọn si n jẹ ko jẹ eyi to ma maa mu ẹrin pa ẹrẹkẹ wọn ni gbogbo igba.
Kika iwe papọ
Awọn obi le jẹ ki awọn ọmọ wọn maa ka iwe papọ, paapaa awọn iwe itan ṣoki-ṣoki.
Ẹ le gba wọn laaye lati yan iru iwe itan ti wọn ba n fẹ. Ki obi tun ṣalaye awọn itan inu iwe yii fun wọn tun le ṣe pataki, ko le ba a ye wọn daradara
Awọn itan ti wọn ṣe bi orin lati gbọ tun le fun awọn ọmọde ni anfaani lati maa fi ṣe ranti ni gbogbo igba ti wọn ba n ranti.
Fun wọn laaye lati yan iru ounjẹ ti wọn fẹ
Ọna kan ṣoṣo to tun dara julọ ni lati jẹ ki ọmọ yan irufẹẹ ounjẹ to ba nifẹ si. Awọn ọmọde nilo awọn ounjẹ aṣara-loore lo le mu ki ago ara wọn wa ni eto ati ilana ilera pipe.
Awọn ounjẹ kan naa si wa to maa n mu ara ati ọpọlọ ọmọde ji pepe ni gbogbo igba, gbiyanju lati jẹ ki wọn yan funra wọn.
Jẹ ki wọn wo sinima to dara
Wiwo sinima tun wa lara awọn ọna to dara lati maa fi gbadun ayajọ ọjọ awọn ọmọde. Awọn sinima eremọde ti a mọ si Cartoon ni agbara pupọ lati jẹ ki awọn ọmọde maa rẹrin, ki wọn si fọkanbalẹ pe ile ni awọn wa.
Awọn sinima to tun maa n kọ wọn lẹkọọ naa tun ṣe pataki fun wọn lati jẹ ki wọn wo.
Awọn obi le fi ilana kalẹ lati maa wo sinima pẹlu awọn ọmọ, ki wọn le fi ilana irufẹ sinima ti wọn gbọdọ maa wo lelẹ.
Gbe wọn jade
Lilọ si awọn ibi igbafẹ bii ile itaja igbalode, ọgba awọn ẹranko naa tun le jẹ ọna pataki lati fi ṣayẹyẹ fun awọn ọmọde.
Koda, lilo awọn asiko to dara lawọn ile ounjẹ igbalode naa tun dara pupọ, o si maa n jẹ ki wọn ri ara wọn gẹgẹ bi ẹni to wuyi lawujọ.
Nipa gbigbe wọn jade, awọn obi yoo tun lo anfaani rẹ lati ma ṣe jẹ ki awọn ọmọ wọn maa da ronu.
Afẹfẹ ati eemi awọn agbegbe yii tun ma n mu ara wọn ji pepe, ki wọn si jafafa.















