Lórí ọ̀rọ̀ Emir Sanusi àti Ado Bayero: ‘Àwọn jàǹdùkú kan ń gbèrò àti kọlu àwọn agbègbè kan ní ìlú Kano’

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Kano, Mohammed Hussein Gumel ti sọ pe awọn ti gba olobo nla kan pe awọn janduku kan lo wa nidi wahala to n ṣẹlẹ nipinlẹ naa lọwọlọwọ, ati pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati dẹkun wọn.
Gumel sọ pe awọn janduku yii ti ṣe ikọlu si ọpọ awọn agbegbe to ṣe pataki, to fi mọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa.
Ọga ọlọpaa naa jẹ ko di mimọ pe awọn ko nii la oju silẹ lati jẹ ki wahala naa tẹsiwaju, ati pe ohunkohun tabi igbesẹ ti awọn ba gbe, ofin ati aṣẹ ile ẹjọ lawọn n tẹle.
Ninu ọrọ rẹ, o ṣalaye pe
“Mo fẹẹ fi to o yin leti pe ati pe pari eto ati ilana lati jẹ ki eto aabo gbookan sii, ka si rii daju gbogbo agbegbe ti awọn janduku fẹẹ ṣe ikọlu si la daabo bo, ka si tun maa foju wo awọn bubaa wọn.
“Ohunkohun to ba nii ṣe pẹlu ọrọ aafin, a rii gẹgẹ bii ofin ati apa kan ninu aṣẹ ile-ẹjọ.
“Gẹgẹ ileeṣẹ to n boju to ọrọ ofin ati aṣẹ ofin, bi ile-ẹjọ ba paṣẹ, koda to ba dara tabi ko dara, a ma maa tẹle aṣẹ naa ni gbogbo igba ni titi digba ti ile-ẹjọ yoo fi pinnu.”
Bakan naa ni ileeṣẹ ologun orileede yii sọ pe awọn ko lọwọ si gbogbo nnkan to n lọ nipa wahala aafin nipinlẹ Kano, ati pe awọn ko ni nnkan ṣe nipa lilo aṣẹ ile-ẹjọ.
Ninu atẹjade ti alakoso eto igbẹnusọ ileeṣẹ ologun, Ọgagun Onyema Nwachukwu fi lede, o sọ pe o lawọn ti gbe igbesẹ lati gbogun ti gbogbo awọn to n gbero lati da wahala silẹ.
Ileeṣẹ ologun lo n tako ẹsun ti ẹgbẹ awọn agbẹjọro lorileede Naijiria, ẹka tipinlẹ Kano fi kan wọn pe wọn mọ nipa wahala to n ṣẹlẹ niluu Kano.
Iroyin fi ye wa pe ogoji oloye lo kopa nibi ipade ti Emir ilu Kano, Muhammad Sanusi keji pe lọjọp Aiku, ti a si tun gbọ pe ninu awọn oloye Emir ana naa wa nibẹ pẹlu.
Ju gbogbbo rẹ lọ, awọn alẹnulọrọ ninu eto igbeyawo Karaye, eyi ti wọn bajẹ ti sọ pe awọn tako igbesẹ ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa gbe.
Wọn ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa gbe igbesẹ ti wọn gbe lai ba awọn araalu sọrọ.















