Ṣé Nàìjíríà ti já sójú ọ̀nà lẹ́yìn ọdún kan Tinubu nípò?

Oniṣowo burẹdi
    • Author, Mansur Abubakar
    • Role, BBC News, Kano

Lootọ awọn ọmọ Naijiria fẹran ere bọọlu pupọ̀, ṣugbọn ọrọ to n jade lẹnu wọn bayii ju ọrọ bọọlu lọ.

Lẹyin ọdun kan Bọla Tinubu ni ipo aarẹ Naijiria, Abubakar Sheka to n ta burẹdi lopopona ni ilu Kano ni ohun to n mumu lọkan awọn onibara oun ni bi wọn yoo ṣe ri nnkan ra.

“Nigba ti inu ba kun ni eeyan n sọ ọrọ bọọlu, ṣugbọn ni asiko yii ni atijẹ ati atimu di inira nla fun eleyi to ti wa mu ki koko ọrọ to wa lẹnu ọpọ maa da lori ọrọ aje.”

Sheka ẹni ọdun mẹrindinlogoji ṣalaye fun BBC pe iwọnba perete lawọn eeyan to ṣi n lagbara ati ra irẹsi bayii nitori iye ti wọn n ta burẹdi gan an ti gbowoleri lati oṣu karun un ọdun to kọja, eyi ti ko ṣẹyin bi owo iyẹfun ti ṣe gbẹnu soke to si ti mu ki ọpọ idile rin jinna si burẹdi ni jijẹ.

Bi nnkan ṣe n gbowoleri, ti agbara owo Naira pẹlu si n fojojumọ dẹnukọlẹ ti di ohun ti gbogbo sọmọ Naijiria n fojojumọ ba finra lati oṣu meji sẹyin bayii.

Lootọ wahala eto ọrọ aje to n ba Naijiria finra naa lo n ba ọpọ orilẹede agbaye naa finra, sibẹ pupọ ohun to jẹ ti Naijiria lo waye nipa afọwọfa awọn igbesẹ ijọba ti ijọba Tinubu gbe nigba to de ori oye lọdun kan sẹyin.

Ida mẹtadinlogoji ibo logbe Tinubu wọle sipo aarẹ Naijiria ninu ibo to fa ọpọlọpọ ipinya. O r awọn ọmọ Naijiria nigba naa lati di ọkan pada.

Bakan naa lo koju wahala iṣuna, ijinigbe ati ijẹkujẹ.

Aarẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, Reuters

Laarin pọpọsinsin eto ibura wọle rẹ lo ti kede eto pataki kan ti ijọba rẹ ṣe.

“Owo iranwọ ori epo rọbi ti di afisẹyin ti eegun n fiṣọ,” ni ọrọ ti Tinubu sọ si eti igbọ awọn ọmọ Naijiria lai ṣalaye ni ṣisẹntẹle bi eto naa yoo ṣe lọ, tabi awọn ọna arẹmọlẹkun ti ijọba fẹ gbe kalẹ.

Owo gọbọi ni eto iranwọ owo ori epo rọbi yii n gbọn lọ lapo ijọba, eleyi si ni Tinubu ni oun fẹ na si nnkan miran.

Eekan onimọ nipa ọr to n lọ, Hashim Abubakar ni, Aarẹ Tinubu bẹrẹ ọrọ akọsọ rẹ gẹgẹbi aarẹ ni agogo mẹwaa, nigba ti a o fi ri agogo mọkanla, awọn eeyan ti bẹrẹ si nii to si ile epo kaakiri.

“Ọrọ rẹ yii lo mu ki owo epo di ọwọngogo lẹsẹkẹsẹ.”

Bakan naa ni ijọba Tinubu ti fopin si ki ijọba maa fi gbedeke le iye ti wọn n ta Naira ni ja karakata owo ilẹ okeere eleyi to mu ki agbara owo naira o tubọ dẹnukọlẹ sii. Eleyi ti mu ki gbogbo nnkan gbowolori ni Naijiria.

Eyi si ti tubọ ti ọpọ si oko oṣi ati iṣẹ.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC n ṣw iwọde ọwọngogo nnkan ni NAijiria

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ijọba pin owo ti iye rẹ to $54 fun awọn idile kan laarin oṣu mẹta lati ran awọn idile to ku diẹkaato fun, amọ eyi ko ran ohunkohun rara.

Ọgbẹni Victor Aluyi to jẹ ọga agba nileeṣẹ iṣuna Sankore ṣalaye pe, atunto gbogbo ti ijọba to wa lode naa n ṣe da lori ọna ati mu ki awọn oludokoowo lati oke okun o tubọ ni igbagbọ ninu ọrọ aje Naijiria lati le wa dokoowo si inu rẹ.

Lọ si BBC.com/yoruba fun awọn iroyin miran

Ẹ tun kan si wa ni facebook ni BBCNewsYoruba ati @bbcnewsyoruba lori Instagram