Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ kéde ìyanṣẹ́lódì aláìlọ́jọ́ lẹ́yìn tí ìpàdé wọn pẹ̀lú ìjọba lórí owó oṣù tuntun tún forí ṣánpọ́n

Oríṣun àwòrán, NLC Headquarters/X
Apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria NLC ati TUC ti kede iyansẹlodi bẹrẹ lati ọjọ Aje, ọjọ kẹta oṣu kẹfa ọdun 2024.
Iroyin to tẹ wa lọwọ ni igbeṣẹ naa waye lẹyin ipade to waye laarin ẹgbẹ oṣisẹ ati ijọba apapọ lori ọrọ owo oṣu tuntun.
Aarẹ ẹgbẹ oṣisẹ TUC, Festus Osifo lo kede igbesẹ naa lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ pẹlu awọn olori ẹgbẹ oṣisẹ NLC niluu Abuja lọjọ Ẹti.
Gẹgẹ bi ohun ti awọn olori ẹgbẹ oṣisẹ sọ, wọn gbe igbesẹ naa nitori iye ọjọ ti wọn fun ijọba apapọ lati wa ojutuu si ọrọ owo oṣu to kereju ti dopin.
Ẹgbẹ oṣisẹ tun binu jade ninu ipade pẹlu ijọba apapọ lọjọ Ẹti, ti wọn si kọ N60,000 ti ijọba gbe kalẹ lati san.
Akọkọ ni ẹgbẹrun mejidinlaadọta naira ti wọn kọkọ dabaa, ẹlẹẹkeji ni ẹgbẹrun mẹrinlelaadọta naira ti wọn mẹnuba lọjọ Iṣẹgun, nigba ti ẹgbẹrun mẹtadinlọgọta naira jẹ igba kẹta, ko to tun wa kan ẹgbẹrun lọna ọgọta naira ti wọn kọ lati tẹwọgba.
Gẹgẹ bii iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe ṣalaye, iye owo ti ijọba apapọ gbe siwaju ẹgbẹ osisẹ ni ko dun mọ wọn ninu, ti wọn tun jẹ ko ye ijọba apapọ pe wọn ko ni ipinnu lati yi erongba wọn pada.
Ẹgbẹ osisẹ ni owo ti awọn fẹ maa gba gẹgẹ bii oṣu to kere ju ni N494,000 lẹyin ti wọn din ẹgbẹrun mẹta ninu N497,000 ti wọn lawọn fẹ gba tẹlẹ lọsẹ to kọja.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















