Yorùbá ní ìlànà fún àyẹ̀wò mímọ ọmọ ọkọ yàtọ̀ sí ọmọ àlè lówó tí kò ga ju ara lọ - Ifayemi Elebuibon

Oríṣun àwòrán, ARABAOSOGBO1
Ọkan lara awọn aṣiwaju agbaṣa Yoruba ga, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn ti kọminu lori bi ọrọ ọmọ ale ṣe n pọ sii, pẹlu amọran pe ẹnikẹni to ba fẹ mọ boya ọmọ ale lọmọ oun tabi ọmọ ọkọ lee dan ilana iṣẹṣe ilẹ Yoruba wo.
Oloye Ẹlẹbuibọn to ba awọn akọroyin sọrọ ni ile rẹ nilu Oṣogbo dahun ibeere lori boya ẹya Yoruba ni ilana tirẹ lati da ọmọ ọkọ mọ yatọ si ọmọ ale, pẹlu bi owo ayẹwo oyinbo ti wọn n pe ni DNA ṣe gọbọi ju fun ọpọ lati san lọpọ igba.
Oloye Ẹlẹbuibọn to tun jẹ Araba awo ilu Oṣogbo ṣalaye pe kikọ ti awọn eeyan kọ aṣa ati iṣẹṣe awọn babanla wọn silẹ lo faa bi iwa agbere ninu igbeyawo ṣe n pọ sii. O niẹya Yoruba ni awọn ilana to to ti o si tọ lati mọ boya ọmọ ale lọmọ kan tabi ọmọ ọkọ, eyi ti ẹnikẹni to ba ṣe irufẹ iwadii bẹẹ le lo.
Oloye Ẹlẹbuibọn ni, Yoruba ni awọn ọna iṣẹmbaye ti ogun rẹ ṣe e mu gbari. Wọn si yatọ lati idile kan si omiran.
Araba ilu Oṣogbo naa ṣalaye siwaju sii pe ninu aṣa ilẹ Yoruba, lasiko ibimọ, o ṣeeṣe lati mọ ẹni to lọmọ.
Ni ile tiwa nigba iwaṣẹ, iyawo tuntun yoo fi ogun bura lati jẹ olootọ si ọkọ rẹ.”
Agba agbaṣaka naa ni oniruuru ọna lo wa nilẹ Yoruba lati mọ ẹni to ni ọmọ, awọn ọna wọnyii, gẹgẹbi o ṣe sọ si rọrun owo wọn ko si ga ju ara lọ.











