Ilé alájà méjí dàwó l‘Eko, àwọn òṣìṣẹ pàjáwìrì dóòlà èèyàn mẹ́wàá

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Eeyan mẹwaa ni wọn ti doola ẹmi wọn lẹyin ti ile alaja meji kan dawo ni agbegbe Isale Eko npinlẹ Eko lỌjọbọ ọgbọnjọ oṣu Karun-un ọdun 2024 yii.
Ile ọhun ni wọn ni isẹlẹ ina to waye ninu ọja Dosumu ti ṣe akoba nla fun lasiko ti iṣẹlẹ ina naa waye.
Agbẹnusọ ajọ to risi iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijria, NEMA, ẹka ti ipinlẹ Eko, Ibrahim Farinloyem ẹni to fi iroyin naa mulẹ, ṣalaye pe awọn ile mẹrinla mii ni iṣẹlẹ ina to waye ni ọja Dosumu naa ṣe akoba fun.
Bakan naa, akọwe ajọ to n risi iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ LASEMA, Olufemi Damilola Oke Osanyintolu ni awọn to farapa ti wa ni ile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju.
“Awọn eeyan mẹwaa, agbalagba mẹsan an ati ọdọmọbinrin ọmọ mẹtadinlogun ni wọn farapa nibi iṣẹlẹ naa,” o ṣalaye.
“Lẹyin ti wọn ti gba itọju diẹ nibi ti isẹlẹ naa ti waye, wọn ti wa ni ile iwosan abẹle Iga Iduganran ti wọn ti n gba itọju.
“Afọku ile naa ti wọn yoo fọ tan, ti a yoo si ṣayẹwo awọn ile to wa niwaju ile to dawo.”
Bẹẹ ba gbagbe, ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu yii ni mọṣalasi kan dawo ni agbegbe Papo Ajao, ti eeyan mẹta si ba iṣẹlẹ naa lọ.
Ninu ọrọ ti LASEMA gbe sita, “pẹlu igbiyanju wa, awọn to ti jade laye lori ijamba mọṣalaṣi to da wo naa ti di mẹta bayii, ti awọn to si farapa yana yana tun ti di meje.
“Ile to da wo naa ni a ti fi n pa ilẹ rẹ lati ko awọn ẹru buruku kuro.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















