Gbogbo ẹni tó ń jí lọ ibi iṣẹ́, àgbẹ̀, ọlọ́jà, òògùn owó ni gbogbo wọn ń ṣe - Ifayemi Elebuibon

Àkọlé fídíò, Ifayemi Elebuibon: Kí wọ́n máa gé orí èèyàn fi ṣe òògùn owó tàbí gbé igbá léèyàn lórí, àwa

Araba awo ti ilu Osogbo, Ifayemi Elebuibon ti ni lootọ ni Akudaaya wa.

O sọ eyi lati fesi si gbogbo awọn ti ko gbagbọ ninu iṣẹlẹ yii.

Elebuibon sọ nigba ti BBC Yoruba ṣebẹwo si ile rẹ pe bi eeyan ba ku lai to ọjọ, o ni nkan ibilẹ ti Yoruba maa n ṣe ti ẹni naa yoo ji dide lọjọ kẹta.

"Baba taa jọ wa ninu ọkọ ni ki n wo obinrin to joko nita yii, o ni pe o ti ku, ara ilu awọn ni, mo ba ni bawo la o wa ṣe mọ, baba ni ki n maa woo, pe to ba ti ri oun maa ri nkan ti yoo ṣe".

O ni bẹẹ ni ọpọlọpọ eeyan ti wọn ti ku bẹyẹn to jẹ pe ilu mii ni wọn o maa gbe o si ni tori rẹ ni eeyan ṣe pọ lagbaye ti wọn a maa wọ tuu tuu..

"Ogun owo ti ko si ni pe ki eeyan kan ji ko wa ni ni kọrọ yara oun kan, ki oun kan maa mu owo nibẹ ni ko jẹ abuubu tan, irọ ni o jẹ".

Araba awo ti ilu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon gbalejo ikọ iroyin BBC Yoruba nibi to ti tan imọlẹ si ootọ nipa awuyewuye awọn eeyan nipa ogun owo paapaa eyi ti wọn npariwo pe awọn onijibiti ori ayelujara (Yahoo) n ṣe.

Aworan iboji

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Igba Aje

O ni oriṣiriṣi ọrọ to n lọ lode nisiiyi bii pe wọn gbe igba le eeyan kan lori, wọn ge ẹya ara fi ṣe oogun owo ati bẹẹ bẹẹ lọ, o ni awọn ko gbọ iru rẹ nigba iwasẹ.

"Laelae ni awọn baba wa ti n ṣe awure, awure nla wa, awure oṣo wa, awure ti waa maa pa ẹran ewurẹ, aguntan loṣooṣu wa, amọ ti ki wọn maa ge ori eeyan wa fi ṣe oogun owo yii, emi o mọ".

Baba Elebuibon

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Bakan naa nigba ti o mẹnu ba ọrọ akudaaya, Baba Ifayemi Elebuibon ni aṣa Yoruba gbagbọ ninu "Ajidide".

O fi kun un pe ni ọjọ kẹẹta, o ni nkan ti wọn maa n ṣe fun ẹni to ku lati ji dide.