Ta ni arákùnrin Peter Segun Awojide, olùdíje sipò gómìnà Ipinlẹ Osun?

Àwòrán Awojide áti igbakeji gomina rẹ

Oríṣun àwòrán, sceenshot

Arakunrin Awojide Peter Segun jẹ ọkan gboogi ninu ọrọ oṣelu ni ipinlẹ Osun, ti o si tun jẹ ọkan lara awọn olujide sipo gomina ni Ipinlẹ Osun labẹ asia ẹgbẹ oselu African Action Congress.

Awojide jẹ ọmọ bibi Imesi-Ile lapa ariwa ipinlẹ Osun ni ìjọba ibilẹ Obokun

Ó bẹrẹ ile ẹkọ alakọọbẹrẹ ni Iwere ilé High School ni Ipinlẹ naa ti o si jade ile ẹkọ grammar ni ọdun 1997

Awojide tẹsiwaju ninu eto ẹkọ ni ile iwe gbogbonise Osun State College of Technology ni Esa Oke ni Ipinlẹ Osun

Arákùnrin Awojide Peter Segun ni o ni ireti lati mu igba otun ba eto ijoba ni Ipinlẹ Osun gẹgẹ bi gomina ipinle naa.

Awojide ni o se afihan ohun merin ti o ṣe fun ipinlẹ Osun ti o ba di gomina.

O ni akọkọ ni eto ẹkọ ọfẹ fun awọn olugbe ipinlẹ, eto abo to yanranti lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn ara ipinlẹ naa, idagbasoke ọrọ aje ni origun merin ipinlẹ naa ati eto Ilera igbalode fun awọn olugbe ipinlẹ Osun.