"Irọ́ ni o! Ọkọ Osinachi kò sá kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kuje lásíkò ìkọlù tó wáyé níbẹ̀"

PETER NWACHUKWU

Oríṣun àwòrán, PETER NWACHUKWU

Ileeṣẹ ijọba apapọ to n bojuto ọgba ẹwọn ni Naijiria, Nigeria Correction Service, NCS, ti sọ pe irọ ni iroyin to n lọ nigboro pe afurasi lori iku obinriin olorin ẹmi to di oloogbe, Peter Nwachukwu, ti salọ kuro lọgba ẹwọn to wa.

Alukoro ileesẹ naa niluu Abuja lo fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC.

O ni “Ko si ootọ kankan ninu iroyin to ni ọkọ Osinachi Nwanchukwu ti ṣalọ kuro lọgba ẹwọn Kuje.”

Chukwuedo Humphrey lo ṣi aṣọ loju eegun ọrọ yii lẹyin ti iroyin ti kọkọ gbode pe afurasi naa ti ṣalọ lọgba ẹwọn.

Humphrey sọ pe “Bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, inu ọgba ẹwọn naa ni mo wa, mo si ri ọkunrin naa laipẹ yii.”

“Irọ ni gbogbo iroyin ti wọn n gbe kiri yẹn pe o ti salọ o.”

O fi kun pe o yẹ ki awọn ileeṣẹ iroyin maa ṣe iwadii wọn finifini ki wọn to maa gbe iroyin sita, ki wọn ma ba ṣi awọn araalu lọna pẹlu iroyin ofege.

Ojojumọ ni ọwọ wa n tẹ awọn ẹlẹwọn to salọ

O ni ojojumọ ni ọwọ awọn n tẹ awọn ẹlewọn to salọ lẹyin ikọlu to waye si ọgba ẹwọn naa ṣaaju.

Humphrey tun sọ siwaju si pe lootọ ni ọwọ ajọ to n gbogun ti egboogi oloro, NDLEA, tẹ ọkan lara awọn to salọ lọgba ẹwọn naa niluu Abuja lọjọ Aje.

NDLEA sọ ṣaaju pe ibudokọ kan lọwọ awọn ti tẹ ẹlẹwọn naa lọjọ Aje.

Ẹwẹ, ọjọ Ẹti ni NCS kede pe awọn n wa ẹlẹwọn méjídínláàdọ́rùn ún to jẹ ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi Boko Haram to salọ kuro ninu ọgba ẹwọn naa lẹyin ikọlu to waye nibẹ.