Ṣé Donald Trump yóò lọ sí ẹ̀wọ̀n ni tàbí yóò díje dupò ààrẹ? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Pẹlu idajọ ẹbi ti ile ẹjọ gbe ka iwaju aarẹ tẹlẹ lorilẹede Amẹrika, Donald Trump, ọpọlọpọ koṣẹlẹri ni ọr rẹ gbe sita.
Akọkọ, oun ni aarẹ orilẹede Amẹrika akọkọ, yala to ṣi wa lori oye ni o, tabi eyi to ti fi ipo silẹ, ti yoo jẹbi iwa ọdaran niwaju ile ẹjọ. Oun si tun ni akọkọ oludije ẹgbẹ oṣelu to lamilaaka ni yoo jẹbi ẹsun ile ẹjọ.
Bi o tilẹ jẹ wi pe, Trump ti sọ pe oun yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ naa, ti o si n duro de iru ijiya ti ile ẹjọ yoo fun un fun ẹsun naa lọjọ kọkanla oṣu keje, eyi le ja si lilọ si ẹwọn tabi sisan owo itanran to lagbara pupọ. Pẹlu bẹẹ, a jẹ wi pe, ko tii ya ju lati tan fitila wo ohun ti eyi le fa ba ọrọ oṣelu.
Yoo le diẹ lati sọ ni pato ibi ti ọr rẹ yoo kangun si nitori pe iru eyi ko ṣẹlẹ ri ninu itan.
“Lọpọ igba inu iwe itan ni a maa n wo lati mọ ibi ti o ṣeeṣe ki ọr ja si” gẹgẹ bi Jeffery Engel, oludari ibudo itan nipa awọn aarẹ, eyi to wa ni fasiti Southern Methodist. “Amọṣa ko tii si akọsilẹ iṣẹlẹ kan to fara pẹ eyi ninu itan.”

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Ilé alájà méjí dàwó l‘Eko, àwọn òṣìṣẹ pàjáwìrì dóòlà èèyàn mẹ́wàá
- Wo àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Donald Trump, ààrẹ Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀ tó jẹ̀bi ẹ̀sùn mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n níléẹjọ́
- 'Èmi ò ní báwọn kọ orin ìyìn Nàìjíríà àtijọ́ tí Tinubu fòntẹ̀ lù,' mínísítà tẹ́lẹ̀ rí yarí
- Wo ewu tó wà nínú fífipá fún ọmọdé lóúnjẹ, pẹ̀lú bí o ṣe lè pa ọmọ
Trump ni wọn yan gẹgẹbi oludije ẹgbẹ oṣelu Republican nibi eto idibo sipo aarẹ eyi ti yoo waye loṣu kejila ọdun yii lorilẹede Amẹrika. Nibi ipade apapọ ẹgbẹ oṣelu Republican ti yoo waye lọjọ diẹ lẹyin ti ileẹjọ ba kede ijiya Trump nin yoo gbe aṣia ẹgbẹ oṣelu naa le e lọwọ.
Awọn iwadi ibo to ti waye fihan pe ni ifẹgbẹkẹgbẹ ni Trump ati aarẹ Biden wa ninu igbelewọn bi araalu ṣe n fẹ wọn si, koda lawọn ipinlẹ kọọkan to lẹnu julọ ninu eto idibo naa, Trump lo n lewaju. Amọṣa, awọn iwadii wọnyii tun jẹ ko di mimọ pe bi ile ẹjọ ba ti lọ ka ijiya to tọ sii tan, o ṣeeṣe ki o ja irawọ rẹ ninu idibo naa.
Ọpọ awọn eeyan lo si ti sọ pe bi ọbẹ ile ẹjọ ba ba aarẹ tẹlẹ naa ni iru fun ẹsun iwa ọdaran, awọn ko ni dibo fun un.

Bi iye awọn to n fẹ Trump ba ja diẹ silẹ, o ṣeeṣe ko to lati jaa lulẹ ninu idije naa. Bi awọn oludibo to yẹ ko dibo fun un tẹlẹ ba duro sile lawọn ipinlẹ to ṣe pataki bi Wisconsin tabi Pennsylvania, nitori abajade ẹsun yii, o lee ni ipa to pọ lara ibi ti ibo naa yoo jasi.

Fun ọdun mẹjọ ni awọn onimọ atawọn alatako ti n fọnrere iṣubu Trump lagbo oṣelu, amọ ṣe ọrọ wọn yoo ri bẹẹ tabi ko ni ri bẹẹ? Oniruuru wahala ati iroyin aṣemaṣe lo yọ taya lẹsẹ ọkọ ipolongo ibo rẹ lọdun 2016 leyi to yẹ ko bi oloṣelu yoiowu ṣubu.
Ẹgbẹ oṣelu Trump duro ṣinṣin pẹlu rẹ lasiko to la igbesẹ meji lati yọ ọ nipo aarẹ ati wahala ati rugudu to gbẹyin iṣejọba rẹ ni saa rẹ akọkọ, lasiko to jẹ wi pe awọn eeyan kan kọlu ile aṣofin apapọ orilẹede naa.
Gbogbo awọn iṣẹlẹ yii ko di Trump lọna ati ṣe agbedide irinajo oṣelu rẹ eleyi to ti sọ ọ di oludije ti ko ṣe e fi ọwọ rọ sẹyin ninu ere ije si ipo aarẹ orilẹede naa bayii.
Awọn oludibo ni agbara wa lọwọ wọn bayii lati sọ bi idajọ ile ẹjọ to wa lọrun Trump bayii yoo ṣe ni ipa to ninu kadara irin oṣelu rẹ nigba ti wọn ba n dibo loṣu kọkanla. Bi aarẹ Amẹrika tẹlẹ naa ba fidirẹmi, idajọ ileẹjọ yii yoo jẹ ohun kan pataki ti awọn onwoye yoo tọka si gẹgẹbi ohun to ṣokunfa rẹ.
Bi o ba si di pe o bori idibo naa, o ṣeeṣe ko jẹ abawọn kan ninu irinajo oṣelu rẹ.















