Ṣé pípadà s'órin orílẹ̀èdè àtijọ́ tẹ̀lé ìgbésẹ̀ òfin tó tọ́?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní ọjọ́rú, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Karùn-ún ọdún 2024 ni ààrẹ Bola Ahmed Tinubu buwọ́lu òfin yíyí orin orílẹ̀ èdè padà kúrò ní ‘Arise o compatriot’ sí ‘Nigeria, we hail thee’.
Láàárín ọ̀sẹ̀ kan ni àbá láti fi ṣe àyípadà náà fi dòfin bí ilé aṣòfin àgbà ṣe buwọ́lu àná láàárín ọjọ́ márùn-ún.
Ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹtàlélógún ni wọ́n kọ́kọ́ ka àbá náà fún ìgbà àkọ́kọ́ àti ìkejì ní ilé aṣòfin àgbà tí ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, Godswill Akpabio sì kéde lọ́jọ́rú, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n pé ààrẹ Tinubu ti buwọ́lu àbá náà dòfin.
Láti ìgbà tí àbá náà ti dòfin ni àwọn ọmọ Nàìjíríà kan ti n kọminú lórí bí àbá náà ṣe yá kíákíá tí wọ́n sì tètè búwọlù ú dòfin.
Lára àwọn awuyewuye tó ń wáyé lẹ́yìn ìbuwọ́lù náà ni ìbéèrè pé ṣe àbá náà gba ìlànà tó tọ́ kí wọ́n tó tọwọ́bọ̀ ọ́ dòfin.
Amòfin àgbà kan ní Nàìjíríà, tó tún jẹ́ lámèyítọ́, Jiti Ogunye ṣàlàyé pé ó lè ya àwọn ará ìlú lẹ́nu pé kíákíá ni ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin buwọ́lu àbá náà.
Ogunye ní ohun tí ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà mọ àwọn aṣòfin náà mọ́ ni pé wọ́n máa ń fi ṣíṣe òfin falẹ̀ tó jẹ́ pé àbá míì máa lo tó ọdún mẹ́wàá kí wọ́n tó buwọ́lù ú.
Àmọ́ agbẹjọ́rò náà ní ìwé òfin Nàìjíríà kò sọ iye ọjọ́ tàbí gbèdéke àsìkò tó yẹ kí àbá lò nílé aṣòfin kí wọ́n tó sọ ọ́ dòfin.
Ó ṣàlàyé pé ètò ìsúná owó nìkan ni ìwé òfin Nàìjíríà dá ìgbà àti àkókó tó máa fi wáyé fún àmọ́ tí kò sọ wí pé ìgbà kan fún àwọn mìíràn.
Ó ní ohun tí ìwé òfin náà là kalẹ̀ ni àwọn ìgbésẹ̀ ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé tó yẹ kí àbá kan gbà kí wọ́n tó buwọ́lù ú dòfin.
Kí ní àwọn ìgbésẹ̀ tí òfin là kalẹ̀ kí àbá tó dòfin
Ogunye ṣàlàyé pé tí òfin kan bá ti tẹ̀lé àwọn ìgbésẹ̀ àti ìlànà tí ìwé òfin Nàìjíríà là kalẹ̀ ni èèyàn le fi ọwọ́ sọ̀yà wí pé òfin náà kẹ́sẹ járí tàbí pé òfin dádáa ni.
Gbígbé àbá lọ sí ilé aṣòfin fún àgbéyẹ̀wò ni ohun àkọ́kọ́ ohun tí aṣòfin yóò kọ́kọ́ ṣe, tí wọ́n yóò sì ṣe àyẹ̀wò rẹ̀ bóyá ó yẹ ní kíká fún ilé.
Nígbà tí gbogbo ilé bá ti fẹnukò pé kí aṣòfin náà tẹ́ pẹpẹ àbá rẹ̀ ni wọ́n máa ka àbá náà fún ìgbà àkọ́kọ́ sí etí gbogbo àwọn aṣòfin tí oníkálùkù yóò bsì sọ àríwísí rẹ̀ lórí àbá náà.
Lẹ́yìn náà ni wọ́n máa tún fẹnukò pé kí àbá náà tẹ̀síwájú fún kíkà fún ìgbà kejì láti mọ́ bóyá ohun tó wà nínú àbá náà yẹ ní ṣíṣe àti láti sọ àbọ́ bẹ́ẹ̀ dòfin.
Lẹ́yìn èyí ni wọ́n máa pe èèyàn láti wá dá sí àbá náà láti mọ èrò àwọn ará ìlú lórí àbá náà kí wọ́n tó gbe kalẹ̀ dòfin àmọ́ ìgbésẹ̀ yìí kò pọn dandan àti pé kìí ṣe gbogbo òfin ló nílò àríwísí àwọn ará ìlú.
Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ka àbá yìí fún ìgbà kejì ló kan ìgbésẹ̀ mìíràn àmọ́ tí kò pọn dandan kí wọ́n ṣe è
Kíka àbá náà fún ìgbà kẹta tó jẹ́ ìgbà tó kẹ́yìn ló kàn lẹ́yìn èyí kí àbá bẹ́ẹ̀ tó di ìbuwọ́lù dòfin látọwọ́ àwọn aṣòfin náà, tí wọ́n sì máa gbe lọ fún ààrẹ láti buwọ́lù ú.
Ogunye wòye pé gbogbo àwọn ìlànà àti ìgbésẹ̀ yìí ni àbá láti yí orin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà padà sí ti àtijọ́ gbà kó tó di pé ààrẹ buwọ́lù ú dòfin bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yá kíákíá.
'Àwọn ológun ló pa “Arise o compatriot” ní dandan fún àwọn èèyàn'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹ́yìn tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gba òmìnira lọ́dún 1960 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní lo “Nigeria we hail thee” àmọ́ tí wọ́n ṣe àyípadà rẹ̀ sí “Arise o compatriot” lẹ́yìn tí Olusegun Obasanjo gba ìjọba lọ́dún 1978.
Ogunye ṣàlàyé pé èro òun ni pé ààrẹ Tinubu àtàwọn aṣòfin gbé ìgbésẹ̀ yìí láti fi sọ fún àwọn ológun pé àwọn kò faramọ́ nǹkan tí wọ́n ṣe sí Nàìjíríà nígbà náà.
Ó ṣe ìràntí pé àwọn ológun máa ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ girama nígbà náà láti mú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní dandan láti máa kọ orin tí ìjọba ní kí àwọn èèyàn má kọ mọ́ yìí.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì nígbà náà ni kìí kọ orin “Arise o compatriot” láti fi ṣe ìfẹ̀hónúhàn sí àwọn ologun pé àwọn kò fẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
Ó ní èyí ni òun rò wí pé Tinubu ṣe láti fi sọ fún àwọn ológun pé iṣẹ́ ọwọ́ wọn kò tẹ́ àwọn ará ìlú lọ́rùn.
“Ohun tí èmi rò ni pé àwọn tó yí orin padà yìí fọgbọ́n pa òwe fún àwọn ológun àti Obasanjo pé àwọn kọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”
“Ṣùgbọ́n ohun tí ológun ṣe ní orílẹ̀ èdè yìí pọ̀, orin ló kéré jù nínú àwọn nǹkan tó yẹ kí wọ́n máa jà fún nítorí nǹkan tí wọ́n ṣe tó ń fẹ́ àyípadà pọ̀ púpọ̀.”
Kí ni èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí yíyí orin Nàìjíríà padà
Láti ìgbà tí ìjíròrò pípadà sí orin orílẹ̀ èdè àtijọ́ ti bẹ̀rẹ̀ ni àwọn àwọn èèyàn ti ń sọ àríwísí wọn lórí rẹ̀.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ wí pé ìjọba Nàìjíríà ń fi ẹ̀tẹ̀ sílẹ̀ máa pa làpálàpá ni ìgbésẹ̀ yìí.
Àwọn ọmọ Nàìjíríà ní ohun tó yẹ kí ìjọba mójútó ni ọ̀wọ́ngógó pàápàá lórí oúnjẹ tó ń bá àwọn èèyàn fínra.
Wọ́n ní ó dàbí pé ìjọba kò mọ èyí tó kàn àti pé ṣe bí wọ́n ṣe yí orin Nàìjíríà máa mú ìgbèrú bá owó náírà tó ti di akúrẹtẹ̀ ní ọjà àgbáyé.

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Oríṣun àwòrán, Screenshot















