Wo ìgbésẹ̀ tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ń gbé lórí fídíò tó ṣàfihàn àwọn ọlọ́pàá tó ń gbowó lọ́wọ́ ọmọ ilẹ̀ China

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Fidio kan to ṣafihan bawọn ọlọpaa MOPOL kan ṣe n gbowo lọwọ awọn ọmọ ilẹ okeere ti igbagbọ wa pe wọn jẹ ọmọ orilẹede China, ti fa awuyewuye lori ayelujara.
Ọpọ eeyan lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu ihuwasi awọn ọlọpaa MOPOL ọhun, ti wọn ni wọn n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ iwakusa ti orilẹede China kan, to wa ni Sagamu nipinlẹ Ogun.
Amọ, awọn eeyan kan ti sọ pe, ki i ṣe wi pe awọn ọlọpaa naa gba riba, bi ko ṣe pe ẹni to ni ileeṣẹ iwakusa ti wọn ti n ṣiṣẹ fun, lo fun wọn lẹbun owo naa.
"Awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa ti sọ pe ọkunrin to nile iṣẹ ọhun fawọn ọlọpaa yii lẹbun owo, lati mọ riri iṣẹ ribiribi ti wọn n ṣe ni"
A gbọ wi pe iṣẹlẹ naa da lori awọn ọlọpaa to n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ AKK- Frontier Risk Management Nigeria Ltd, ti wọn n ṣiṣẹ nibi ti wọn ti n wa kusa ni Sagamu.
Ẹnikan tiẹ ṣalaye pe ọkunrin to ni ileeṣẹ iwakusa to wa ni Sagamu lo tajo de, o si pinnu lati ri awọn ọlọpaa to n ṣọ ileeṣẹ rẹ, lẹyin tawọn kan sọ fun un wi pe awọn MOPOL naa n ṣiṣẹ daadaa.
Ohun ti a gbọ ni pe lasiko ti ọkunrin to ni ileeṣẹ ọhun n ṣepade lọwọ pẹlu awọn ọlọpaa naa atawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa lapapọ, ni ọkan lara awọn eeyan to tẹ le ọkunrin naa wa bẹrẹ si ni pin owo fun gbogbo awọn oṣiṣẹ, to fi mọ awọn ọlọpaa naa.
Ṣugbọn ko si ẹni to mọ ẹni to pin fidio yii lori itakun ayelujara ti gbogbo eeyan fi ri i.
Bo tilẹ jẹ pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa ti sọ pe ọkunrin to nile iṣẹ ọhun fawọn ọlọpaa yii lẹbun owo, lati mọ riri iṣẹ ribiribi ti wọn n ṣe ni.
Amọ awọn ajafẹtọọ ọmọniyan, to fi mọ oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu AAC, Omoyele Sowore, ti bu ẹnu ẹtẹ lu ihuwasi awọn ọlọpaa to gbowo lọwọ awọn ọmọ ilẹ China naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa fesi lori fidio to lu ori ayelujara pa, pe awọn ti da awọn ọlọpaa to gba owo naa mọ, wọn yoo si gba ijiya to tọ si wọn
Ẹwẹ, ileeṣẹ Naijiria ti kilọ fawọn ọlọpaa lati yago fun iwa to tabuku iṣẹ ọlọpaa lẹyin ti fidio to n ṣafihan bawọn ọlọpaa kan ṣe gbowo lọwọ ọmọ orilẹede China kan lu ori ayelujara pa.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, ACP Olumuyiwa Adejobi, fi sita, ileeṣẹ ṣe apejuwe iwa tawọn ọlọpaa naa hu gẹgẹ bi eyi to lodi sofin ati ihuwasi ọlọpaa.
ACP Adejobi ni ihuwasi awọn ọlọpaa naa tako alakalẹ ti ileeṣẹ ọlọpaa n tẹle e ni Naijiria.
O ni ileeṣẹ ko faye gba iru iwa bayii eyi to le jẹ ki araalu ma le jẹrii awọn ọlọpaa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti da awọn ọlọpaa naa mọ, wọn yoo si gba ijiya to tọ si wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa wa rọ awọn araalu ati ileeṣẹ to n lo ọlọpaa wi pe ki wọn yago fun iwa titabuku iṣẹ ọlọpaa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















