Akẹ́kọ̀ọ́ fásitì OAU gan mọ́ iná lásìkò tó ń gbá bọ́ọ̀lù

Abawọle fasiti Obafemi Awolowo nilu Ile Ife

Oríṣun àwòrán, Obafemi Awolowo University

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹka ile Ẹkọ Fasiti Obafemi Awolowo to wa ni iluu Moro nipinlẹ Ọsun ni wọn ti padanu akẹkọọkunrin naa.

‎Iwadi BBC Yoruba fihan pe ni irọlẹ ọjọ abamẹta, ọjọ Kejila osu Kẹrinọdun 2025 ni ọdọmọkunrin naa n gba bọọlu pẹlu akẹẹgbẹ rẹ nilegbe awọn akẹkọ naa.

‎Eyi lo mu ki akẹkọọ naa fori ko waya ina mọnamọna, to si gba ẹmi rẹ, ki awọn akẹgbẹ rẹ to sun mọ.

Bọọlu ti wọn n gba fo sinu agbala ile kan to sun mọ tosi, akẹkọọ naa si fo sinu agbala ile naa lati lọ mu bọọlu ọhun lo ba gan mọ ina

Nigba ti BBC Yoruba kan si Abiodun Olarewaju, ẹni to jẹ agbẹnusọ fun ile Ẹkọ Fasiti Obafemi Awolowo nilu Ile Ife, o fidi isẹlẹ naa mulẹ fun wa.

‎O ni o jẹ ohun ibanujẹ fun awọn lati padanu ọdọmokunrin naa.

"Akẹkọọ naa lo jẹ ọkan lara akẹkọọ wa to n gbaradi lati se idanwo asewọle si fasiti naa to wa ni iluu Moro.

Ẹka eto ẹkọ naa ni wọn ti n mura lati wa si Ile Ẹkọ Fasiti giga to wa ni iluu Ile-Ife lẹyin ti o ba pari ni CDL, eleyi to n se lọwọ lọwọ."

‎Ogbeni Abiodun wi pe, Iroyin fi to awọn leti pe, awọn akẹkọọ naa n gba bọọlu ni irọlẹ ọjọ buruku naa ni.

Nigbati bọọlu ti wọn n gba naa fo sinu agbala ile kan to sun mọ tosi ibi ti awọn akẹkọọ naa n ti gba bọọlu.

‎ Eyi lo mu ki Ọmọkunrin yi si fo sinu agbala ile naa lati lọ mu bọọlu, nitori oun lo gba bọọlu naa si inu agbala ile naa.

Ni eyi ti wọn si ti sofin wi pe ẹnikẹni to ba gba bọọlu sinu agbala Ile naa, ni yo lọ mu.

‎Pẹlu ofin ti wọn ti se, Ọmọkunrin naa wọ inu agbala ile naa lọ lati lọ mu bọọlu naa.

‎Nigba ti awọn akẹgbẹ rẹ ko ri ko pada de, ni wọn lọ wo o, ti wọn si ri wi pe o n japoro iku lọwọ.

Wọn sare sún mọ, bẹẹ ni ọkan ninu wọn si mu igi lati fi yọ waya ina mọnamona naa kuro lara rẹ.

‎Lẹyin eyi ni wọn sare gbe lọ si ile iwosan CDL ninu ọgba ile ẹkọ naa.

"‎Ile iwosan ni wọn ti sọ pe akẹkọọ naa ti ku, ki wọn to gbe de ile iwosan ọhun"

‎Ile iwosan naa ni wọn ti sọ fun wọn pe akẹkọọ naa ti ku ki wọn to gbe de ile iwosan ọhun.

Wọn ba tun gbe akẹkọọ naa lọ si ile iwosan miran to wa ni agbegbe wọn, sugbọn ẹpa ko boro mọ rara.

‎Ọgbeni Abiodun tun fi kun wi pe, ohun ti awọn gbọ ni wi pe, igba akọkọ ti Ọmọkunrin naa yoo gba bọọlu pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ niyii.

‎Ẹni to jẹ adari CDL, Ọjọgbọn Femi Koya ti pe awọn obi ọmọdékùnrin naa lati salaye Isẹlẹ buruku yi fun wọn.