Kí ni ìwọ̀n omi tó yẹ tàbí pọ̀ jù fún èèyàn lójúmọ́?

Ọmọde to n mu omi ni aṣalẹ Thar, ni Rajasthan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Omi ṣe pataki fun agọ ara nitori omi ni a bu wẹ, omi ni a bu mu, ko si ẹni to n ba omi se ọta.

Ọpọ awọn onimọ lagbaye lo n gba awọn eeyan nimọran pe ki wọn maa mu omi, o kere tan, lita omi meji lojumọ fun awọn obinrin, ki awọn ọkunrin si maa mu lita omi meji abọ.

Ẹwẹ, awọn onimọ sayẹnsi tun sọ pe iye iwọn omi to yẹ ki eeyan maa mu da lori ọpọ nnkan.

Ewu nla lo wa ti eeyan ko ba mu omi to to, bẹẹ lo tun lewu ki eeyan mu omi amuju.

Ida ọgọta ninu ọgọrun agọ ara wa ni omi ko, omi wa ninu iṣan ara wa, ninu ẹjẹ ati ninu awọn ẹya mii ninu ara ẹda.

Nidia Rodriguez-Sanchez, to jẹ onimọ nipa omi ni fasiti Stirlin, to wa ni Scotland sọ pe oniruru eroja aṣaraloore lo wa ninu omi.

O sọ pe oriṣiriṣi awọn eroja inu ounjẹ lawọn eeyan n wa kiri amọ wọn gbagbe pe bi ounjẹ ṣe ṣe pataki naa, ni omi ṣe pataki ninu ara ẹda.

Awọn ẹya ara ti omi wa
Àkọlé àwòrán, Awọn ẹya ara ti omi wa

Iṣẹ ti omi n ṣe ninu ara

Iṣẹ ti omi n ṣe lagọ ara ẹda ko kere rara.

Gẹgẹ bii awọn onimọ nile ẹkọ Havard Medical School ṣe sọ, awọn nnkan wọnyii ni omi n ṣe lagọ ara:

  • Gbigbe awọn eroja ati oxygen sinu awọn iṣan ara
  • Fifọ ile itọ mọ lọwọ awọn kokoro aifojuri
  • O n ran ounjẹ lọwọ lati lọ daada ninu ara
  • Kii jẹ ki inu kun akunju
  • Kii jẹ ki ẹjẹ ru ju ninu ara
  • O n ran awọn orike ara lọwọ
  • Idaabodo ẹya inu atawọn iṣan
  • Kii jẹ ki ara gbona ju
  • O n ṣakoso eroja 'sodium' ninu ara
Iṣẹ omi ninu ara
Àkọlé àwòrán, Iṣẹ omi ninu ara

Ki ni yoo ṣẹlẹ ti o ko ba mu iwọn omi to yẹ

Gbogbo igba ni ara wa maa n padanu omi ti a ba ti n laagun, ti a ba ti n tọ ati ti a ba ti n mi.

Lati maa gbe daadaa a ni lati maa rọpo awọn omi ti agọ ara wa n padanu yii loorekoore.

Ti omi inu ara ko ba to, o lewu, o si le fa awon aisan kan fun ara eeyan.

Apẹrẹ ara ti ko ni omi to to

  • Itọ to n pọn ati eyii to n run
  • Ki eeyan ma ri itọ tọ
  • Oju to n ṣe bai bai
  • Ara rirẹ
  • Ẹnu, ete ati ahọn to gbẹ
  • Oju to n wu

Lawọn igba mii ti eeyan ko ba mu omi to to, aya ẹni bẹẹ le maa lu gbigbigbi tabi ki ọkan lara ẹya inu ẹni bẹẹ kọṣẹ gẹgẹ bii atẹjade WHO.

Aworan ipa ti omi to pọ ju ati omi ti ko to maa n ko ninu ara
Àkọlé àwòrán, Aworan ipa ti omi to pọ ju ati omi ti ko to maa n ko ninu ara

Ṣe ewu wa ninu mimu omi to pọ ju?

Bẹẹ - Ewu nla lo wa nibẹ.

Ti eeyan ba mu omi lamuju laarin asiko diẹ sira wọn, o le yọri si 'hyponatraemia' eyii ti wọn n pe ni omi amuyo.

Lara awọn apẹrẹ Hyponatremia ni:

  • Kii eebi maa le eeyan ati ki eeyan maa bi
  • Ori fifọ
  • Ki eeyan ma mọ ohun to n ṣe
  • Irẹwẹsi ara
  • Aini isinmi ninu agọ ara
  • Irẹwẹsi iṣan ara
  • Ki eeyan maa daku
  • Nigba mii eeyan le daku patapata fun ọpọ ọjọ

Lọdun 2018, Johanna Perry n gbaradi fun ere ije ilu London pẹlu ọmọ rẹ, wọn si bẹrẹ si n mu ọpọ omi inu ike.

O sọ fun BBC pe "Ohun kan ti mo ranti gbẹyin ni akọle ere ije naa."

Lẹyin ọjọ kẹta ni obinrin naa to ji dide ni ẹka iṣẹlẹ pajawiri nile iwosan.

O ni "Mo mu omi to pọ ju to bẹẹ t imo fi fọ eroja aṣaraloore kuro ninu ara mi.

Ohun to ṣẹlẹ si obinrin naa n ṣapẹrẹ ohun to le ṣẹlẹ si eeyan ti omi ba pọ lapọju ninu agọ ara.

Omi maa n wọ inu iṣan to n gbe ẹjẹ rin, lẹyin naa ni kidinrin maa n fọ omi naa mọ lati sọ ọ di itọ.

Amọ iwọn lita omi kan pere ni kindinrin wa le fọ laarin wakati kan ṣoṣo.

Iwọn omi melo ni a nilo gan?

Ọmọde to n jẹ watermelon

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọ ohun ti a n jẹ bii eso 'watermelon' lo ni ọpọ omi lara

Lati wa ni ilera pipe, awọ onimọ ni ki a maa mu ife omi mẹjọ lojumọ kan.

Ajọ to n ri si eto ilera nilẹ Europe ni ki obinrin maa mu lita omi meji loojọ, ki awọn ọkunrin si maa mu lita meji ati abọ lojumọ.

Eyii pẹlu omi lati ara awọn nnkan mii ti a n jẹ bii eso.

Pupọ ninu ohun ti a n jẹ lo ni ọpọ omi lara, fun apẹrẹ, eso watermelon ti ida 94% rẹ jẹ kiki omi.

Amọ ṣa, iye iwọn omi to yẹ fun eeyan da lori ọpọ nnkan mii bii bi wọn ṣe sanran to, irufẹ iṣẹ tabi ere idaraya ti wọn n ṣe, ọjọ ori wọn, iṣẹda wọn bii ọkunrin tabi obinrin ati agbegbe ti wọn wa.