Àwọn obìnrin tí wọn bí lóbìnrin nìkan ni òfin rí gẹ́gẹ́ bíi obìnrin - Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní UK

Awọn obinrin n dunnu lori idajọ ile ẹjọ to ga julọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Maria Zaccaro
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ile ẹjọ to ga julọ ni UK ti dajọ wi pe awọn eeyan ti wọn bi lobinrin nikan ni ofin ilẹ naa ri gẹgẹ bii obinrin.

Awọn adajọ to gbe idajọ yii kale ko ṣai fi idi rẹ mulẹ pe awọn ti wọn bi lọkunrin ti wọn n ṣe bi obinrin atawọn obinrin to n ṣe bi ọkunrin si lẹtọọ si abo labẹ ofin kawọn eeyan le ma ba maa dẹyẹ si wọn, ṣugbọn akọ ati abo ni ofin mọ gẹgẹ bi ẹya eeyan meji to wa.

Ẹgbẹ kan to n ri si ọrọ awọn obinrin ni Scotland lo gbe ijọba orilẹede naa lọ sile ẹjọ wi pe ko paṣẹ pe awọn ti wọn bi lobinrin nikan lo yẹ ki ofin maa ri gẹgẹ bii obinrin.

Ẹgbẹ naa ti gba idalare bayii nile ẹjọ to ga julo ni UK pẹlu idajọ tawọn adajọ ile ẹjọ naa gbe kalẹ.

Akọ to n ṣe bi abo ni ẹni ti wọn bi lọkunrin ṣugbọn to n ṣe bii obinrin, bakan naa, abo to n ṣe bi akọ ni eeyan ti wọn bi lobinrin amọ to n ṣe bi ọkunrin.

Niṣe lawọn obinrin n dawọọ idunnu niwaju ile ẹjọ to ga julọ lẹyin idajọ naa, nigba tawọn kosakọ-kosabo n kọminu pe idajọ ọhun le ṣakoba fun awọn labẹ ofin.

Bawo lọrọ naa ṣe de ile ẹjọ to ga julọ?

Idajọ yii ti pari aawọ to ti pẹ laarin ijọba orilẹede Scotland ati ẹgbẹ to n ri sọro awọn obinrin lorilẹede naa.

Ọrọ yii bẹrẹ lọdun 2018 lẹyin ti ile aṣofin Scotland buwọlu ofin ti yoo mu ibadọgba wa laarin awọn ẹya.

Nigba naa ni ẹgbẹ awọn obinrin tako igbesẹ awọn minisita lati fi awọn kosakọ-kosabo naa sara awọn ti yoo jẹ anfaani ọhun labẹ ofin.

Ijọba sọ nigba naa pe awọn kosakọ-kosabo to ba ni iwe ẹri GRC lẹtọọ si awọn anfaani kan naa tawọn obinrin ati ọkunrin lẹtọọ si.

Lẹyin ti igbẹjọ ti waye lọpọ igba nile ẹjọ lorilẹede Scotland, ni ẹjọ naa de ile ẹjọ to ga julọ ni UK eyi to wa niluu London fun idajọ to kẹyin.

Ohun ti wọn beere lọwọ ile ẹjọ to ga julọ ni pe ko tumọ ofin ibadọgba ẹya ọdun 2010 eyi to kan England, Scotland ati Wales.

Ofin yii daabo bo ẹtọ awọn eeyan nipasẹ ẹya wọn.

Ki lo wa ninu idajọ ile ẹjọ to ga julọ?

Ileẹjọ to ga julọ gbe idajọ wọn kalẹ eyi ti adajọ Lord Hodge ka wi pe itumọ obinrin ati ẹya ninu ofin ibadọgba ọdun 2010 ni pe ẹni ti wọn ba ti bi lobinrin nikan ni ofin ri gẹgẹ bii obinrin.

Idajọ naa sọ pe itumọ mii fun ofin naa ko lẹsẹ nlẹ rara.

Ile ẹjọ ṣalaye wi pe itumọ ti ijọba Scotland fun ofin ibadọgba naa yoo ṣe afikun ẹya to wa pẹlu ẹya meji mii.

Awọn adajọ ile ẹjọ to ga julọ sọ pe idajọ awọn ko ni ki ijọba maa yan awọn kosabọ-kosabo sipo.

Idajọ naa sọ pe ofin ibadọgba si n daabo bawọn eeyan to jẹ kosakọ-kosabo naa pẹlu.

Adajo Hodge ṣalaye ninu idajọ to ka wi pe awọn kosakọ-kosabo si lẹtọọ si aabo labẹ ofin papaa julọ tawọn eeyan ba n dẹyẹ si wọn.

Ohun tawọn eeyan n sọ nipa idajọ ile ẹjọ to ga julọ

Aworan arabinrin JK Rowling to n ṣatilẹyin fun awọn obinrin ni Scotland

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ko si ẹni to le sọ pato iru ipa ti idajọ yii yoo ni kaakiri Uk bayii, ṣugbọn ohun ti o tumọ si ni pe awọn obinrin ti wọn ba bi lobinrin nikan ni yoo maa lanfaani si nnkan to jẹ tawọn obinrin.

Ẹwẹ, Sacha Deshmukh to jẹ ọga agba ajọ Amnesty International UK ti kepe ijọba UK atawọn alaṣẹ lati sọ bi ofin yoo ṣe daabo bawọn kosakọ-kosabo tawọn eeyan kan le fẹẹ maa lo idajọ yii tẹ ẹtọ wọn mọlẹ.

Ẹgbẹ kan ti orukọ rẹ n jẹ TransActual UK naa ti fi aidunnu rẹ han lori idajọ ile ẹjọ to ga julọ.

Ẹgbẹ naa sọ pe tawọn eeyan ti wọn ba bi lọkunrin amọ to n ṣe bii obinrin ko ba lẹtọọ si nnkan tawọn obinrin ba lẹtọọ si, o tumọ si pe wọn o ni le kopa ninu nnkan to n lọ lawujọ niyẹn.

Onkọwe Harry Potter, JK Rowling to ṣatilẹyin fawọn obinrin Scotland sọ pe idajọ yii yoo daabo ba gbogbo obinrin ati ọmọdebinrin kaakiri ilẹ UK.

Adari ẹgbẹ oṣelu Conservative Party, Kemi Badenoch, naa sọ pe aṣeyọri nla ni idajọ ile ẹjọ naa jẹ.

Badenoch ni ''obinrin ni obinrin n jẹ, ọkunrin lọkunrin n jẹ. Ko si ẹni to le tun ara rẹ da.''

Ọmọwe Annie Donaldson to maa n ṣe iwadii iwa ipa sawọn obinrin naa sọ pe idajọ ile ẹjọ to ga julọ ti ṣalaye ẹni ti ofin ri gẹgẹ obinrin gan an.

Ki lo n ṣẹlẹ lawọn orilẹede mii?

Loṣu Kinni to kọja ni Aarẹ Donald Trump orilẹede Amẹrika buwọlu ofin to sọ pe ẹya meji ti i ṣe obinrin ati ọkunrin nikan ofin mọ lorilẹede naa.

Ofin naa sọ pe ọkunrin ko le sọ ara rẹ di obinrin, obinrin naa ko si le di ọkunrin l'Amẹrika.

Awọn bii orilẹede mọkanlelogun to fi mọ Argentina ati Nepal gba ki eeyan sọ iru ẹya to jẹ fun ra rẹ titi di oṣu Kọkanla ọdun 2024.

Amọ, ọpọ orilẹede ni wọn ko ti ri awọn kosakọ-kosabo gẹgẹ ẹya.

Loṣu kẹjọ to kọja, obinrin kosakọ-kosabo kan lati Australia jare nile ẹjọ lori iwa idẹyẹsi lori itakun ayelujara kan to wa fawọn obinrin nikan, lẹyin to sọ pe ọkunrin loun.

Eyi waye nitori Australia jẹ ọkan lara orilẹede 189 pẹlu Brazil, India ati South Africa ti wọn ti buwọlu ofin to tako idẹyẹsi sawọn obinrin.

Ọdun 1979 ni ajọ UN ṣe agbekalẹ ofin yii eyi to n daabo bo ẹtọ awọn obinrin .

Nitori naa, idajọ to waye ni Australia ṣe pataki fawọn orilẹede ti wọn ti buwọlu ofin to tako idẹyẹsi sawọn obinrin.