Àwọn obìnrin 'Blue Origin' tó lọ sínu òfurufú padá sí orílẹ̀ ayé

Àkọlé fídíò,
    • Author, Maddie Molloy
    • Role, BBC Climate & Science reporter
    • Author, Victoria Gill
    • Role, Science correspondent, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja olorin Katy Perry ati obinrin marun-un mii ti pada si ori ilẹ aye lẹyin tí wọn gbera pẹlu rọkẹẹti Jeff Bezos ti wọn gbe lọ sinu ofurufu.

Olorin ọhun ni iyawo afẹsọna Bezos tẹle pẹlu atọkun CBS Gayle King, ẹni to ni orin Louis Armstrong "What a Wonderful World" ni Kate Perry n kọ lasiko irinajo naa.

Lẹyin ti wọn pada si ori ile aye, Perry ni oun ni tun ni ajọsepọ nla pẹlu ile aye ati pẹlu ifẹ si.

Irinajo naa lo jẹ bí isẹju mọkanla, ti awọn obinrin mẹfa si lọ kilomita 100km(62m) ni oke ile aye, ti wọn si kọja ala ile aye ati ofurufu, eyi ti fun wọn ni isẹju diẹ lati fun juoju lounjẹ.

Aworan

Bakan naa, awọn obinrin to wa ninu ọkọ ofurufu naa ni a ti ri omimọ Nasa tẹlẹ, Aisha Bowe, ajafẹtọ ọmọniyan, Amanda Nguyen, ati olugbesinima sita, Kerianne Flynn.

Ọkọ ofurufu New Shepard gbera lati West Texas ni ago 08:30 (14:30 BST).

Ọpọ ero lo n yẹ awọn obinrin naa si nigba ti wọn balẹ pada si ile aye.

Jeff Bezos lo si ilẹkun ọkọ ofurufu naa lati ki Lauren Sanchez, ẹni akọkọ to kọkọ jade sita.

"Inu mi dun fun awọn ẹgbẹ yii, " o sọ pẹlu omije loju. "Ń ko le sọrọ.

"Mo wo ita ferese, mo ri osupa."

"Ile aye dakẹ, ko ki n ṣe nnkan ti mo lero ni mo ri."

Ẹni to tẹle ni Katy Perry, ẹni to fi ẹnu balẹ, to si gbe patako soke- orukọ ọmọ rẹ ni Daisy.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Dave Limp/Blue Origin

Gayle King naa fi orukun rẹ lelẹ bí o ṣe ń jade lati inu ọkọ naa.

"Mo kan fẹ ni akoko die pẹlu ilẹ, lati ti fi mọ riri rẹ." O sọ.

Kerianne Flynn lo jade kẹyin, to si n pariwo mo lọ sinu ofurufu.

Irinajo obìnrin lọ ofurufu to waye gbẹyin lo waye ni ọgọta ọdun ṣeyin nigba ti obinrin Sovie, Cosmonaut Valentina Tereshkova ni obinrin akọkọ ti yoo rin irinajo lọ sinu ofurufu.

Lati igba naa, ko ti si irinajo obinrin nikan lọ sinu ofurufu.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Blue Origin

Wo bi ọkọ ofurufu Blue Origin ṣe gbera

Àkọlé fídíò,